Acts 9 (BOYCB)
1 Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí èémí ìhalẹ̀ mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ, 2 ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu. 3 Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká. 4 Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” 5 Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?”Olúwa sì wí fún pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. 6 Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.” 7 Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan. 8 Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku. 9 Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu. 10 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!”Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.” 11 Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà. 12 Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.” 13 Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu. 14 Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.” 15 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli. 16 Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.” 17 Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.” 18 Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀. 19 Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀. 20 Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.” 22 Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà. 23 Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á. 24 Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n. 26 Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni. 27 Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu. 28 Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa. 29 Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a. 30 Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu. 31 Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i. 32 Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33 Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34 Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35 Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa. 36 Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe. 37 Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè. 38 Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.” 39 Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà, gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn. 40 Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó. 41 Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè. 42 Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́. 43 Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.