Deuteronomy 14 (BOYCB)
1 Ọmọ OLÚWA Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́: nítorí náà, ẹ má ṣe ya ara yín ní abẹ. Ẹ má ṣe gé irun iwájú orí yín nítorí òkú. 2 Nítorí pé ènìyàn mímọ́ ní ẹ jẹ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín, nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run ti yàn yín láti jẹ́ ìṣúra iyebíye rẹ̀. 3 Ẹ má ṣe jẹ ohun ìríra kankan. 4 Àwọn wọ̀nyí ni ẹranko tí ẹ lè máa jẹ: màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́, 5 àgbọ̀nrín, èsúró, etu, àgóró, ẹfọ̀n, ìgalà àti àgùntàn igbó. 6 Ẹ lè jẹ gbogbo ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í ṣe méjì tí ó sì tún jẹ àpọ̀jẹ. 7 Síbẹ̀síbẹ̀ nínú gbogbo ẹran tí ń jẹ àpọ̀jẹ tí ó sì tún ya pátákò ẹsẹ̀ tí ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ni: ìbákasẹ, ehoro, àti ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n wọn kò la pátákò ẹsẹ̀, a kà wọ́n sí àìmọ́ fún yín. 8 Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ àìmọ́; bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ya pátákò ẹsẹ̀, kì í jẹ àpọ̀jẹ, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú rẹ̀. 9 Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyìí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́. 10 Ṣùgbọ́n èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. 11 Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́. 12 Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà, 13 onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà, 14 onírúurú ẹyẹ ìwò, 15 ògòǹgò, òwìwí, pẹ́pẹ́yẹdò àti onírúurú àwòdì, 16 onírúurú òwìwí, 17 òwìwí ọ̀dàn, àkàlà, ìgò, 18 àkọ̀, òòdẹ̀, onírúurú ẹyẹ odò mìíràn, atọ́ka àti àdán. 19 Àti gbogbo kòkòrò tí ń fò tí wọ́n ń kọ́wọ̀ọ́ rìn jẹ́ aláìmọ́ fun un yín, ẹ má ṣe jẹ wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ẹ lè jẹ èyíkéyìí ẹ̀dá abìyẹ́ tí ó bá mọ́. 21 Ẹ má ṣe jẹ ohun tí ó ti kú sílẹ̀. Ẹ lè fún àwọn àjèjì tí ń gbé ní èyíkéyìí nínú ìlú yín. Òun lè jẹ ẹ́ tàbí kí ẹ tà á fún àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n ènìyàn mímọ́ fún OLÚWA Ọlọ́run yín ni ẹ̀yin jẹ́.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ewúrẹ́ nínú wàrà ìyá rẹ̀. 22 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdákan nínú mẹ́wàá nínú ìre oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apá kan. 23 Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bu ọlá fún OLÚWA Ọlọ́run yín nígbà gbogbo. 24 Bí ibẹ̀ bá jì tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí OLÚWA yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù). 25 Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sí owó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí OLÚWA yóò yàn. 26 Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú OLÚWA níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀. 27 Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Lefi tí ó ń gbé nì ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í ṣe tiwọn. 28 Ní òpin ọdún mẹ́ta mẹ́ta, ẹ̀yin yóò mú gbogbo ìdámẹ́wàá ìre oko àwọn ọdún náà, kí ẹ kó wọn jọ ní ìlú yín. 29 Kí àwọn Lefi (tí kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn) àti àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba, àti àwọn opó tí ń gbé ìlú yín lè wá, kí wọn sì jẹ kí wọn sì yó, kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ le è bùkún fún ọ, nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
In Other Versions
Deuteronomy 14 in the ANGEFD
Deuteronomy 14 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 14 in the AS21
Deuteronomy 14 in the BAGH
Deuteronomy 14 in the BBPNG
Deuteronomy 14 in the BBT1E
Deuteronomy 14 in the BDS
Deuteronomy 14 in the BEV
Deuteronomy 14 in the BHAD
Deuteronomy 14 in the BIB
Deuteronomy 14 in the BLPT
Deuteronomy 14 in the BNT
Deuteronomy 14 in the BNTABOOT
Deuteronomy 14 in the BNTLV
Deuteronomy 14 in the BOATCB
Deuteronomy 14 in the BOATCB2
Deuteronomy 14 in the BOBCV
Deuteronomy 14 in the BOCNT
Deuteronomy 14 in the BOECS
Deuteronomy 14 in the BOGWICC
Deuteronomy 14 in the BOHCB
Deuteronomy 14 in the BOHCV
Deuteronomy 14 in the BOHLNT
Deuteronomy 14 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 14 in the BOICB
Deuteronomy 14 in the BOILNTAP
Deuteronomy 14 in the BOITCV
Deuteronomy 14 in the BOKCV
Deuteronomy 14 in the BOKCV2
Deuteronomy 14 in the BOKHWOG
Deuteronomy 14 in the BOKSSV
Deuteronomy 14 in the BOLCB
Deuteronomy 14 in the BOLCB2
Deuteronomy 14 in the BOMCV
Deuteronomy 14 in the BONAV
Deuteronomy 14 in the BONCB
Deuteronomy 14 in the BONLT
Deuteronomy 14 in the BONUT2
Deuteronomy 14 in the BOPLNT
Deuteronomy 14 in the BOSCB
Deuteronomy 14 in the BOSNC
Deuteronomy 14 in the BOTLNT
Deuteronomy 14 in the BOVCB
Deuteronomy 14 in the BPBB
Deuteronomy 14 in the BPH
Deuteronomy 14 in the BSB
Deuteronomy 14 in the CCB
Deuteronomy 14 in the CUV
Deuteronomy 14 in the CUVS
Deuteronomy 14 in the DBT
Deuteronomy 14 in the DGDNT
Deuteronomy 14 in the DHNT
Deuteronomy 14 in the DNT
Deuteronomy 14 in the ELBE
Deuteronomy 14 in the EMTV
Deuteronomy 14 in the ESV
Deuteronomy 14 in the FBV
Deuteronomy 14 in the FEB
Deuteronomy 14 in the GGMNT
Deuteronomy 14 in the GNT
Deuteronomy 14 in the HARY
Deuteronomy 14 in the HNT
Deuteronomy 14 in the IRVA
Deuteronomy 14 in the IRVB
Deuteronomy 14 in the IRVG
Deuteronomy 14 in the IRVH
Deuteronomy 14 in the IRVK
Deuteronomy 14 in the IRVM
Deuteronomy 14 in the IRVM2
Deuteronomy 14 in the IRVO
Deuteronomy 14 in the IRVP
Deuteronomy 14 in the IRVT
Deuteronomy 14 in the IRVT2
Deuteronomy 14 in the IRVU
Deuteronomy 14 in the ISVN
Deuteronomy 14 in the JSNT
Deuteronomy 14 in the KAPI
Deuteronomy 14 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 14 in the KBV
Deuteronomy 14 in the KJV
Deuteronomy 14 in the KNFD
Deuteronomy 14 in the LBA
Deuteronomy 14 in the LBLA
Deuteronomy 14 in the LNT
Deuteronomy 14 in the LSV
Deuteronomy 14 in the MAAL
Deuteronomy 14 in the MBV
Deuteronomy 14 in the MBV2
Deuteronomy 14 in the MHNT
Deuteronomy 14 in the MKNFD
Deuteronomy 14 in the MNG
Deuteronomy 14 in the MNT
Deuteronomy 14 in the MNT2
Deuteronomy 14 in the MRS1T
Deuteronomy 14 in the NAA
Deuteronomy 14 in the NASB
Deuteronomy 14 in the NBLA
Deuteronomy 14 in the NBS
Deuteronomy 14 in the NBVTP
Deuteronomy 14 in the NET2
Deuteronomy 14 in the NIV11
Deuteronomy 14 in the NNT
Deuteronomy 14 in the NNT2
Deuteronomy 14 in the NNT3
Deuteronomy 14 in the PDDPT
Deuteronomy 14 in the PFNT
Deuteronomy 14 in the RMNT
Deuteronomy 14 in the SBIAS
Deuteronomy 14 in the SBIBS
Deuteronomy 14 in the SBIBS2
Deuteronomy 14 in the SBICS
Deuteronomy 14 in the SBIDS
Deuteronomy 14 in the SBIGS
Deuteronomy 14 in the SBIHS
Deuteronomy 14 in the SBIIS
Deuteronomy 14 in the SBIIS2
Deuteronomy 14 in the SBIIS3
Deuteronomy 14 in the SBIKS
Deuteronomy 14 in the SBIKS2
Deuteronomy 14 in the SBIMS
Deuteronomy 14 in the SBIOS
Deuteronomy 14 in the SBIPS
Deuteronomy 14 in the SBISS
Deuteronomy 14 in the SBITS
Deuteronomy 14 in the SBITS2
Deuteronomy 14 in the SBITS3
Deuteronomy 14 in the SBITS4
Deuteronomy 14 in the SBIUS
Deuteronomy 14 in the SBIVS
Deuteronomy 14 in the SBT
Deuteronomy 14 in the SBT1E
Deuteronomy 14 in the SCHL
Deuteronomy 14 in the SNT
Deuteronomy 14 in the SUSU
Deuteronomy 14 in the SUSU2
Deuteronomy 14 in the SYNO
Deuteronomy 14 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 14 in the TBT1E
Deuteronomy 14 in the TBT1E2
Deuteronomy 14 in the TFTIP
Deuteronomy 14 in the TFTU
Deuteronomy 14 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 14 in the THAI
Deuteronomy 14 in the TNFD
Deuteronomy 14 in the TNT
Deuteronomy 14 in the TNTIK
Deuteronomy 14 in the TNTIL
Deuteronomy 14 in the TNTIN
Deuteronomy 14 in the TNTIP
Deuteronomy 14 in the TNTIZ
Deuteronomy 14 in the TOMA
Deuteronomy 14 in the TTENT
Deuteronomy 14 in the UBG
Deuteronomy 14 in the UGV
Deuteronomy 14 in the UGV2
Deuteronomy 14 in the UGV3
Deuteronomy 14 in the VBL
Deuteronomy 14 in the VDCC
Deuteronomy 14 in the YALU
Deuteronomy 14 in the YAPE
Deuteronomy 14 in the YBVTP
Deuteronomy 14 in the ZBP