Deuteronomy 15 (BOYCB)
1 Ní òpin ọdún méje méje, ẹ̀yin gbọdọ̀ máa yọ̀ǹda àwọn gbèsè. 2 Báyìí ni kí ẹ máa ṣe é. Gbogbo ẹni tí wọ́n jẹ ní gbèsè gbọdọ̀ fojú fo gbèsè tí ó ti yá ará Israẹli ènìyàn rẹ̀. Kò gbọdọ̀ béèrè ohun náà, lọ́dọ̀ ará Israẹli ènìyàn rẹ̀ tàbí lọ́dọ̀ arákùnrin rẹ̀: nítorí pé a ti kéde àkókò OLÚWA láti fojú fo gbèsè. 3 Ẹ lè béèrè ìsanpadà lọ́dọ̀ àjèjì. Ṣùgbọ́n ẹ fa igi lé gbèsè yówù kó jẹ́ tí arákùnrin yín jẹ yín. 4 Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò tọ́ sí nínú yín, nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nínú ilẹ̀ náà tí ó ń mú un yín lọ láti gbà bí ìní yín. 5 Kìkì bí ẹ bá gbọ́rọ̀ sí àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run yín tí ẹ sì kíyèsára láti máa rìn nínú gbogbo àṣẹ wọ̀nyí, tí èmi ń pa fún un yín lónìí. 6 Nítorí pé OLÚWA Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín bí ó ti ṣèlérí, ẹ̀yin yóò sì máa yá ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ẹ kì yóò sì tọrọ. Ẹ ó ṣàkóso ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò sí orílẹ̀-èdè tí yóò lè jẹ ọba lé e yín lórí. 7 Bí tálákà kan bá wà láàrín àwọn arákùnrin yín ní èyíkéyìí àwọn ìlú, ilẹ̀ náà tí OLÚWA yín yóò fún un yín. Ẹ má ṣe ṣe àìláàánú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe háwọ́ sí arákùnrin yín tí ó jẹ́ tálákà. 8 Ṣùgbọ́n ẹ lawọ́ kí ẹ sì fi tọkàntọkàn yá wọn ní ohun tí wọ́n nílò. 9 Ẹ ṣọ́ra kí èrò búburú kan má ṣe sí nínú àyà rẹ wí pé, “Ọdún keje tí í ṣe ọdún ìyọ̀ǹda gbèsè ti súnmọ́,” nípa bẹ́ẹ̀, ojú rẹ a sì burú sí arákùnrin rẹ tálákà, tí ìwọ kò sì fun ní nǹkan, o kò sì fun ní nǹkan kan. Òun a si kígbe pe Olúwa nítorí rẹ, a si di ẹ̀ṣẹ̀ fún ọ. 10 Fún un tọkàntọkàn, láìsí ìkùnsínú, nítorí èyí, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, àti gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. 11 A kò lè fẹ́ tálákà kù ní ilẹ̀ náà ní ìgbà gbogbo, mo pàṣẹ fún un yín láti lawọ́ sí àwọn arákùnrin yín, sí àwọn tálákà àti sí àwọn aláìní, ní ilẹ̀ ẹ yín. 12 Bí Heberu ara yín kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin bá ta ara rẹ̀ fún ọ, tí ó sì sìn ọ́ fún ọdún mẹ́fà. Ní ọdún keje, jẹ́ kí ó di òmìnira. 13 Nígbà tí ó bá dá a sílẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ó lọ lọ́wọ́ òfo. 14 Fi tọkàntọkàn fún un láti inú agbo ewúrẹ́ rẹ, ilẹ̀ ìpakà rẹ, àti ibi ìfúntí rẹ. Fún un gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti bùkún fún ọ tó. 15 Ẹ rántí pé ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú ní Ejibiti, OLÚWA Ọlọ́run yín sì rà yín padà, ìdí nìyí tí mo fi pa àṣẹ yìí fún un yín lónìí. 16 Ṣùgbọ́n bí ìránṣẹ́ rẹ bá sọ fún ọ pé, “Èmi kò fẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,” nítorí pé ó fẹ́ràn ìwọ àti ìdílé rẹ, tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn, 17 kí ìwọ kí ó mú ìlu kan lu etí rẹ̀ mọ́ ara ìlẹ̀kùn, yóò sì di ẹrú rẹ láéláé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe sí ìránṣẹ́ ẹrúbìnrin rẹ. 18 Má ṣe kà á sí ohun ìnira láti dá ẹrú rẹ sílẹ̀, nítorí ìsìnrú rẹ̀ fún ọ, ní ọdún mẹ́fà náà tó ìlọ́po méjì iṣẹ́ alágbàṣe, OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò bùkún fún ọ nínú gbogbo ìdáwọ́lé rẹ. 19 Gbogbo àkọ́bí tí o jẹ́ akọ nínú agbo màlúù rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún OLÚWA, àti nínú agbo ewúrẹ́ bákan náà. Ẹ má ṣe fi àkọ́bí màlúù yín ṣiṣẹ́ rárá. Má ṣe rẹ́ irun àkọ́bí àgùntàn rẹ pẹ̀lú. 20 Ní ọdọọdún ni kí ìwọ àti ìdílé rẹ máa jẹ ẹ́ níwájú OLÚWA Ọlọ́run yín níbi tí Òun yóò yàn. 21 Bí ẹran ọ̀sìn kan bá ní àbùkù: bóyá ó yarọ, tàbí fọ́jú, tàbí tí ó ní èyíkéyìí àbùkù tó burú. Ẹ kò gbọdọ̀ fi rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run yín. 22 Ẹ jẹ ẹ́ ní ìlú u yín. Àti ẹni tí a kà sí mímọ́ àti aláìmọ́ ni ó lè jẹ ẹ́ bí ìgbà tí a ń jẹ èsúró tàbí àgbọ̀nrín. 23 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, ẹ dà á síta bí omi.
In Other Versions
Deuteronomy 15 in the ANGEFD
Deuteronomy 15 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 15 in the AS21
Deuteronomy 15 in the BAGH
Deuteronomy 15 in the BBPNG
Deuteronomy 15 in the BBT1E
Deuteronomy 15 in the BDS
Deuteronomy 15 in the BEV
Deuteronomy 15 in the BHAD
Deuteronomy 15 in the BIB
Deuteronomy 15 in the BLPT
Deuteronomy 15 in the BNT
Deuteronomy 15 in the BNTABOOT
Deuteronomy 15 in the BNTLV
Deuteronomy 15 in the BOATCB
Deuteronomy 15 in the BOATCB2
Deuteronomy 15 in the BOBCV
Deuteronomy 15 in the BOCNT
Deuteronomy 15 in the BOECS
Deuteronomy 15 in the BOGWICC
Deuteronomy 15 in the BOHCB
Deuteronomy 15 in the BOHCV
Deuteronomy 15 in the BOHLNT
Deuteronomy 15 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 15 in the BOICB
Deuteronomy 15 in the BOILNTAP
Deuteronomy 15 in the BOITCV
Deuteronomy 15 in the BOKCV
Deuteronomy 15 in the BOKCV2
Deuteronomy 15 in the BOKHWOG
Deuteronomy 15 in the BOKSSV
Deuteronomy 15 in the BOLCB
Deuteronomy 15 in the BOLCB2
Deuteronomy 15 in the BOMCV
Deuteronomy 15 in the BONAV
Deuteronomy 15 in the BONCB
Deuteronomy 15 in the BONLT
Deuteronomy 15 in the BONUT2
Deuteronomy 15 in the BOPLNT
Deuteronomy 15 in the BOSCB
Deuteronomy 15 in the BOSNC
Deuteronomy 15 in the BOTLNT
Deuteronomy 15 in the BOVCB
Deuteronomy 15 in the BPBB
Deuteronomy 15 in the BPH
Deuteronomy 15 in the BSB
Deuteronomy 15 in the CCB
Deuteronomy 15 in the CUV
Deuteronomy 15 in the CUVS
Deuteronomy 15 in the DBT
Deuteronomy 15 in the DGDNT
Deuteronomy 15 in the DHNT
Deuteronomy 15 in the DNT
Deuteronomy 15 in the ELBE
Deuteronomy 15 in the EMTV
Deuteronomy 15 in the ESV
Deuteronomy 15 in the FBV
Deuteronomy 15 in the FEB
Deuteronomy 15 in the GGMNT
Deuteronomy 15 in the GNT
Deuteronomy 15 in the HARY
Deuteronomy 15 in the HNT
Deuteronomy 15 in the IRVA
Deuteronomy 15 in the IRVB
Deuteronomy 15 in the IRVG
Deuteronomy 15 in the IRVH
Deuteronomy 15 in the IRVK
Deuteronomy 15 in the IRVM
Deuteronomy 15 in the IRVM2
Deuteronomy 15 in the IRVO
Deuteronomy 15 in the IRVP
Deuteronomy 15 in the IRVT
Deuteronomy 15 in the IRVT2
Deuteronomy 15 in the IRVU
Deuteronomy 15 in the ISVN
Deuteronomy 15 in the JSNT
Deuteronomy 15 in the KAPI
Deuteronomy 15 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 15 in the KBV
Deuteronomy 15 in the KJV
Deuteronomy 15 in the KNFD
Deuteronomy 15 in the LBA
Deuteronomy 15 in the LBLA
Deuteronomy 15 in the LNT
Deuteronomy 15 in the LSV
Deuteronomy 15 in the MAAL
Deuteronomy 15 in the MBV
Deuteronomy 15 in the MBV2
Deuteronomy 15 in the MHNT
Deuteronomy 15 in the MKNFD
Deuteronomy 15 in the MNG
Deuteronomy 15 in the MNT
Deuteronomy 15 in the MNT2
Deuteronomy 15 in the MRS1T
Deuteronomy 15 in the NAA
Deuteronomy 15 in the NASB
Deuteronomy 15 in the NBLA
Deuteronomy 15 in the NBS
Deuteronomy 15 in the NBVTP
Deuteronomy 15 in the NET2
Deuteronomy 15 in the NIV11
Deuteronomy 15 in the NNT
Deuteronomy 15 in the NNT2
Deuteronomy 15 in the NNT3
Deuteronomy 15 in the PDDPT
Deuteronomy 15 in the PFNT
Deuteronomy 15 in the RMNT
Deuteronomy 15 in the SBIAS
Deuteronomy 15 in the SBIBS
Deuteronomy 15 in the SBIBS2
Deuteronomy 15 in the SBICS
Deuteronomy 15 in the SBIDS
Deuteronomy 15 in the SBIGS
Deuteronomy 15 in the SBIHS
Deuteronomy 15 in the SBIIS
Deuteronomy 15 in the SBIIS2
Deuteronomy 15 in the SBIIS3
Deuteronomy 15 in the SBIKS
Deuteronomy 15 in the SBIKS2
Deuteronomy 15 in the SBIMS
Deuteronomy 15 in the SBIOS
Deuteronomy 15 in the SBIPS
Deuteronomy 15 in the SBISS
Deuteronomy 15 in the SBITS
Deuteronomy 15 in the SBITS2
Deuteronomy 15 in the SBITS3
Deuteronomy 15 in the SBITS4
Deuteronomy 15 in the SBIUS
Deuteronomy 15 in the SBIVS
Deuteronomy 15 in the SBT
Deuteronomy 15 in the SBT1E
Deuteronomy 15 in the SCHL
Deuteronomy 15 in the SNT
Deuteronomy 15 in the SUSU
Deuteronomy 15 in the SUSU2
Deuteronomy 15 in the SYNO
Deuteronomy 15 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 15 in the TBT1E
Deuteronomy 15 in the TBT1E2
Deuteronomy 15 in the TFTIP
Deuteronomy 15 in the TFTU
Deuteronomy 15 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 15 in the THAI
Deuteronomy 15 in the TNFD
Deuteronomy 15 in the TNT
Deuteronomy 15 in the TNTIK
Deuteronomy 15 in the TNTIL
Deuteronomy 15 in the TNTIN
Deuteronomy 15 in the TNTIP
Deuteronomy 15 in the TNTIZ
Deuteronomy 15 in the TOMA
Deuteronomy 15 in the TTENT
Deuteronomy 15 in the UBG
Deuteronomy 15 in the UGV
Deuteronomy 15 in the UGV2
Deuteronomy 15 in the UGV3
Deuteronomy 15 in the VBL
Deuteronomy 15 in the VDCC
Deuteronomy 15 in the YALU
Deuteronomy 15 in the YAPE
Deuteronomy 15 in the YBVTP
Deuteronomy 15 in the ZBP