Deuteronomy 21 (BOYCB)

1 Tí a bá rí ọkùnrin tí a pa, ní ìdùbúlẹ̀ ní pápá nínú ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ń fún ọ láti jogún, tí a kò sì mọ ẹni tí ó pa á, 2 àwọn àgbàgbà yín yóò jáde lọ láti wọn jíjìnnà ibi òkú sí ìlú tí ó wà nítòsí. 3 Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí òkú yóò mú ẹgbọrọ abo màlúù tí kò ì ṣiṣẹ́ rí àti tí kò sì fà nínú àjàgà rí, 4 kí àwọn àgbàgbà ìlú náà kí wọn mú ẹgbọrọ abo màlúù náà sọ̀kalẹ̀ wá sí àfonífojì tí ó ní omi ṣíṣàn kan, tí a kò ro, tí a kò sì gbìn, kí wọn kí ó sì ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ màlúù náà níbẹ̀ ní àfonífojì náà. 5 Àwọn àlùfáà, ọmọ Lefi yóò wá síwájú, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti bùkún ní orúkọ OLÚWA àti láti parí gbogbo ẹjọ́ àríyànjiyàn àti ọ̀rọ̀ ìlú. 6 Nígbà náà ni gbogbo àwọn àgbàgbà ìlú tí ó wà nítòsí yóò wẹ ọwọ́ wọn lórí ẹgbọrọ abo màlúù tí a ti kan ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7 wọn yóò sì sọ pé, “Ọwọ́ wa kò ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, tàbí kí ojú wa rí i ní títa sílẹ̀.” 8 Dáríjì, OLÚWA, àwọn ènìyàn rẹ ni Israẹli, tí ìwọ ti dá sílẹ̀, àti kí ìwọ má ṣe gba ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn rẹ ní Israẹli. Ṣùgbọ́n kí a dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì. 9 Nígbà náà ni ìwọ wẹ̀ kúrò láàrín rẹ ẹ̀bi títa ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó tọ́ níwájú OLÚWA. 10 Nígbà tí o bá lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá rẹ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ tí o sì mú àwọn ìgbèkùn, 11 tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbèkùn, tí o sì ní ìfẹ́ sí i, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ. 12 Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, 13 kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ. 14 Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í. 15 Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn. 16 Nígbà tí ó bá ń pín ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò gbọdọ̀ fi ẹ̀tọ́ àkọ́bí fún ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn. 17 Ó ní láti fi ipò ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn fun un gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí i rẹ̀ nípa fífún un ní ìlọ́po ìpín gbogbo ohun tí ó ní. Ọmọ yẹn ni àmì àkọ́kọ́ agbára baba rẹ̀. Ẹ̀tọ́ àkọ́bí jẹ́ tirẹ̀. 18 Bí ọkùnrin kan bá ní aláìgbọ́ràn tàbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ tí kò gbọ́rọ̀ sí baba àti ìyá rẹ̀ tí kò sì ní í gbà tí wọ́n bá ń bá a wí, 19 baba àti ìyá rẹ̀ yóò gbá a mú, wọn yóò mu wá fún àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú u rẹ̀. 20 Wọn yóò sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ọmọ wa yìí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ̀tẹ̀. Kò ní gbọ́rọ̀ sí wa lẹ́nu. Ọ̀jẹun àti ọ̀mùtípara ni.” 21 Nígbà náà ni gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò sọ ọ́ ní òkúta pa. Ìwọ yóò sì mú ìwà ibi kúrò láàrín yín, gbogbo Israẹli yóò gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n. 22 Bí ọkùnrin kan tí ó jẹ̀bi ẹ̀sùn bá ní láti kú tí ó sì kú, tí a sì gbé òkú rẹ̀ kọ́ sára igi, 23 o kò gbọdọ̀ fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ sára igi ní gbogbo òru. Gbìyànjú láti sin ín ní ọjọ́ náà gan an, nítorí ẹni tí a bá gbé kọ́ sórí igi wà lábẹ́ ègún Ọlọ́run. Ìwọ kò gbọdọ̀ ba ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún jẹ́.

In Other Versions

Deuteronomy 21 in the ANGEFD

Deuteronomy 21 in the ANTPNG2D

Deuteronomy 21 in the AS21

Deuteronomy 21 in the BAGH

Deuteronomy 21 in the BBPNG

Deuteronomy 21 in the BBT1E

Deuteronomy 21 in the BDS

Deuteronomy 21 in the BEV

Deuteronomy 21 in the BHAD

Deuteronomy 21 in the BIB

Deuteronomy 21 in the BLPT

Deuteronomy 21 in the BNT

Deuteronomy 21 in the BNTABOOT

Deuteronomy 21 in the BNTLV

Deuteronomy 21 in the BOATCB

Deuteronomy 21 in the BOATCB2

Deuteronomy 21 in the BOBCV

Deuteronomy 21 in the BOCNT

Deuteronomy 21 in the BOECS

Deuteronomy 21 in the BOGWICC

Deuteronomy 21 in the BOHCB

Deuteronomy 21 in the BOHCV

Deuteronomy 21 in the BOHLNT

Deuteronomy 21 in the BOHNTLTAL

Deuteronomy 21 in the BOICB

Deuteronomy 21 in the BOILNTAP

Deuteronomy 21 in the BOITCV

Deuteronomy 21 in the BOKCV

Deuteronomy 21 in the BOKCV2

Deuteronomy 21 in the BOKHWOG

Deuteronomy 21 in the BOKSSV

Deuteronomy 21 in the BOLCB

Deuteronomy 21 in the BOLCB2

Deuteronomy 21 in the BOMCV

Deuteronomy 21 in the BONAV

Deuteronomy 21 in the BONCB

Deuteronomy 21 in the BONLT

Deuteronomy 21 in the BONUT2

Deuteronomy 21 in the BOPLNT

Deuteronomy 21 in the BOSCB

Deuteronomy 21 in the BOSNC

Deuteronomy 21 in the BOTLNT

Deuteronomy 21 in the BOVCB

Deuteronomy 21 in the BPBB

Deuteronomy 21 in the BPH

Deuteronomy 21 in the BSB

Deuteronomy 21 in the CCB

Deuteronomy 21 in the CUV

Deuteronomy 21 in the CUVS

Deuteronomy 21 in the DBT

Deuteronomy 21 in the DGDNT

Deuteronomy 21 in the DHNT

Deuteronomy 21 in the DNT

Deuteronomy 21 in the ELBE

Deuteronomy 21 in the EMTV

Deuteronomy 21 in the ESV

Deuteronomy 21 in the FBV

Deuteronomy 21 in the FEB

Deuteronomy 21 in the GGMNT

Deuteronomy 21 in the GNT

Deuteronomy 21 in the HARY

Deuteronomy 21 in the HNT

Deuteronomy 21 in the IRVA

Deuteronomy 21 in the IRVB

Deuteronomy 21 in the IRVG

Deuteronomy 21 in the IRVH

Deuteronomy 21 in the IRVK

Deuteronomy 21 in the IRVM

Deuteronomy 21 in the IRVM2

Deuteronomy 21 in the IRVO

Deuteronomy 21 in the IRVP

Deuteronomy 21 in the IRVT

Deuteronomy 21 in the IRVT2

Deuteronomy 21 in the IRVU

Deuteronomy 21 in the ISVN

Deuteronomy 21 in the JSNT

Deuteronomy 21 in the KAPI

Deuteronomy 21 in the KBT1ETNIK

Deuteronomy 21 in the KBV

Deuteronomy 21 in the KJV

Deuteronomy 21 in the KNFD

Deuteronomy 21 in the LBA

Deuteronomy 21 in the LBLA

Deuteronomy 21 in the LNT

Deuteronomy 21 in the LSV

Deuteronomy 21 in the MAAL

Deuteronomy 21 in the MBV

Deuteronomy 21 in the MBV2

Deuteronomy 21 in the MHNT

Deuteronomy 21 in the MKNFD

Deuteronomy 21 in the MNG

Deuteronomy 21 in the MNT

Deuteronomy 21 in the MNT2

Deuteronomy 21 in the MRS1T

Deuteronomy 21 in the NAA

Deuteronomy 21 in the NASB

Deuteronomy 21 in the NBLA

Deuteronomy 21 in the NBS

Deuteronomy 21 in the NBVTP

Deuteronomy 21 in the NET2

Deuteronomy 21 in the NIV11

Deuteronomy 21 in the NNT

Deuteronomy 21 in the NNT2

Deuteronomy 21 in the NNT3

Deuteronomy 21 in the PDDPT

Deuteronomy 21 in the PFNT

Deuteronomy 21 in the RMNT

Deuteronomy 21 in the SBIAS

Deuteronomy 21 in the SBIBS

Deuteronomy 21 in the SBIBS2

Deuteronomy 21 in the SBICS

Deuteronomy 21 in the SBIDS

Deuteronomy 21 in the SBIGS

Deuteronomy 21 in the SBIHS

Deuteronomy 21 in the SBIIS

Deuteronomy 21 in the SBIIS2

Deuteronomy 21 in the SBIIS3

Deuteronomy 21 in the SBIKS

Deuteronomy 21 in the SBIKS2

Deuteronomy 21 in the SBIMS

Deuteronomy 21 in the SBIOS

Deuteronomy 21 in the SBIPS

Deuteronomy 21 in the SBISS

Deuteronomy 21 in the SBITS

Deuteronomy 21 in the SBITS2

Deuteronomy 21 in the SBITS3

Deuteronomy 21 in the SBITS4

Deuteronomy 21 in the SBIUS

Deuteronomy 21 in the SBIVS

Deuteronomy 21 in the SBT

Deuteronomy 21 in the SBT1E

Deuteronomy 21 in the SCHL

Deuteronomy 21 in the SNT

Deuteronomy 21 in the SUSU

Deuteronomy 21 in the SUSU2

Deuteronomy 21 in the SYNO

Deuteronomy 21 in the TBIAOTANT

Deuteronomy 21 in the TBT1E

Deuteronomy 21 in the TBT1E2

Deuteronomy 21 in the TFTIP

Deuteronomy 21 in the TFTU

Deuteronomy 21 in the TGNTATF3T

Deuteronomy 21 in the THAI

Deuteronomy 21 in the TNFD

Deuteronomy 21 in the TNT

Deuteronomy 21 in the TNTIK

Deuteronomy 21 in the TNTIL

Deuteronomy 21 in the TNTIN

Deuteronomy 21 in the TNTIP

Deuteronomy 21 in the TNTIZ

Deuteronomy 21 in the TOMA

Deuteronomy 21 in the TTENT

Deuteronomy 21 in the UBG

Deuteronomy 21 in the UGV

Deuteronomy 21 in the UGV2

Deuteronomy 21 in the UGV3

Deuteronomy 21 in the VBL

Deuteronomy 21 in the VDCC

Deuteronomy 21 in the YALU

Deuteronomy 21 in the YAPE

Deuteronomy 21 in the YBVTP

Deuteronomy 21 in the ZBP