Deuteronomy 6 (BOYCB)
1 Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí OLÚWA Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsi i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jordani. 2 Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀. 3 Gbọ́ ìwọ Israẹli, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́rọ̀, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ní ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ. 4 Gbọ́ ìwọ Israẹli, OLÚWA Ọlọ́run wa, OLÚWA kan ni. 5 Fẹ́ràn OLÚWA Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ. 6 Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ máa wà lóókan àyà yín. 7 Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde. 8 Ẹ so wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín. 9 Kí ìwọ kí ó kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ̀, àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde rẹ. 10 Nígbà tí OLÚWA Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín, fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńlá ńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ, 11 àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n. Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, 12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé OLÚWA, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú. 13 Bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká; 15 torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà. 16 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dán OLÚWA Ọlọ́run yín wò bí ẹ̀yin ti dán wò ní Massa. 17 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin OLÚWA Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín. 18 Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú OLÚWA, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 19 Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀tá yín jáde níwájú u yín bí OLÚWA ti ṣèlérí. 20 Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí OLÚWA Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?” 21 Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n OLÚWA fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti. 22 Lójú wa ni OLÚWA tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀. 23 Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra fún àwọn baba ńlá wa. 24 OLÚWA pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ràn sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, láti bẹ̀rù OLÚWA Ọlọ́run wa, kí ó ba à lè máa dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a ṣe wà títí di òní. 25 Bí a bá ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú OLÚWA Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”
In Other Versions
Deuteronomy 6 in the ANGEFD
Deuteronomy 6 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 6 in the AS21
Deuteronomy 6 in the BAGH
Deuteronomy 6 in the BBPNG
Deuteronomy 6 in the BBT1E
Deuteronomy 6 in the BDS
Deuteronomy 6 in the BEV
Deuteronomy 6 in the BHAD
Deuteronomy 6 in the BIB
Deuteronomy 6 in the BLPT
Deuteronomy 6 in the BNT
Deuteronomy 6 in the BNTABOOT
Deuteronomy 6 in the BNTLV
Deuteronomy 6 in the BOATCB
Deuteronomy 6 in the BOATCB2
Deuteronomy 6 in the BOBCV
Deuteronomy 6 in the BOCNT
Deuteronomy 6 in the BOECS
Deuteronomy 6 in the BOGWICC
Deuteronomy 6 in the BOHCB
Deuteronomy 6 in the BOHCV
Deuteronomy 6 in the BOHLNT
Deuteronomy 6 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 6 in the BOICB
Deuteronomy 6 in the BOILNTAP
Deuteronomy 6 in the BOITCV
Deuteronomy 6 in the BOKCV
Deuteronomy 6 in the BOKCV2
Deuteronomy 6 in the BOKHWOG
Deuteronomy 6 in the BOKSSV
Deuteronomy 6 in the BOLCB
Deuteronomy 6 in the BOLCB2
Deuteronomy 6 in the BOMCV
Deuteronomy 6 in the BONAV
Deuteronomy 6 in the BONCB
Deuteronomy 6 in the BONLT
Deuteronomy 6 in the BONUT2
Deuteronomy 6 in the BOPLNT
Deuteronomy 6 in the BOSCB
Deuteronomy 6 in the BOSNC
Deuteronomy 6 in the BOTLNT
Deuteronomy 6 in the BOVCB
Deuteronomy 6 in the BPBB
Deuteronomy 6 in the BPH
Deuteronomy 6 in the BSB
Deuteronomy 6 in the CCB
Deuteronomy 6 in the CUV
Deuteronomy 6 in the CUVS
Deuteronomy 6 in the DBT
Deuteronomy 6 in the DGDNT
Deuteronomy 6 in the DHNT
Deuteronomy 6 in the DNT
Deuteronomy 6 in the ELBE
Deuteronomy 6 in the EMTV
Deuteronomy 6 in the ESV
Deuteronomy 6 in the FBV
Deuteronomy 6 in the FEB
Deuteronomy 6 in the GGMNT
Deuteronomy 6 in the GNT
Deuteronomy 6 in the HARY
Deuteronomy 6 in the HNT
Deuteronomy 6 in the IRVA
Deuteronomy 6 in the IRVB
Deuteronomy 6 in the IRVG
Deuteronomy 6 in the IRVH
Deuteronomy 6 in the IRVK
Deuteronomy 6 in the IRVM
Deuteronomy 6 in the IRVM2
Deuteronomy 6 in the IRVO
Deuteronomy 6 in the IRVP
Deuteronomy 6 in the IRVT
Deuteronomy 6 in the IRVT2
Deuteronomy 6 in the IRVU
Deuteronomy 6 in the ISVN
Deuteronomy 6 in the JSNT
Deuteronomy 6 in the KAPI
Deuteronomy 6 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 6 in the KBV
Deuteronomy 6 in the KJV
Deuteronomy 6 in the KNFD
Deuteronomy 6 in the LBA
Deuteronomy 6 in the LBLA
Deuteronomy 6 in the LNT
Deuteronomy 6 in the LSV
Deuteronomy 6 in the MAAL
Deuteronomy 6 in the MBV
Deuteronomy 6 in the MBV2
Deuteronomy 6 in the MHNT
Deuteronomy 6 in the MKNFD
Deuteronomy 6 in the MNG
Deuteronomy 6 in the MNT
Deuteronomy 6 in the MNT2
Deuteronomy 6 in the MRS1T
Deuteronomy 6 in the NAA
Deuteronomy 6 in the NASB
Deuteronomy 6 in the NBLA
Deuteronomy 6 in the NBS
Deuteronomy 6 in the NBVTP
Deuteronomy 6 in the NET2
Deuteronomy 6 in the NIV11
Deuteronomy 6 in the NNT
Deuteronomy 6 in the NNT2
Deuteronomy 6 in the NNT3
Deuteronomy 6 in the PDDPT
Deuteronomy 6 in the PFNT
Deuteronomy 6 in the RMNT
Deuteronomy 6 in the SBIAS
Deuteronomy 6 in the SBIBS
Deuteronomy 6 in the SBIBS2
Deuteronomy 6 in the SBICS
Deuteronomy 6 in the SBIDS
Deuteronomy 6 in the SBIGS
Deuteronomy 6 in the SBIHS
Deuteronomy 6 in the SBIIS
Deuteronomy 6 in the SBIIS2
Deuteronomy 6 in the SBIIS3
Deuteronomy 6 in the SBIKS
Deuteronomy 6 in the SBIKS2
Deuteronomy 6 in the SBIMS
Deuteronomy 6 in the SBIOS
Deuteronomy 6 in the SBIPS
Deuteronomy 6 in the SBISS
Deuteronomy 6 in the SBITS
Deuteronomy 6 in the SBITS2
Deuteronomy 6 in the SBITS3
Deuteronomy 6 in the SBITS4
Deuteronomy 6 in the SBIUS
Deuteronomy 6 in the SBIVS
Deuteronomy 6 in the SBT
Deuteronomy 6 in the SBT1E
Deuteronomy 6 in the SCHL
Deuteronomy 6 in the SNT
Deuteronomy 6 in the SUSU
Deuteronomy 6 in the SUSU2
Deuteronomy 6 in the SYNO
Deuteronomy 6 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 6 in the TBT1E
Deuteronomy 6 in the TBT1E2
Deuteronomy 6 in the TFTIP
Deuteronomy 6 in the TFTU
Deuteronomy 6 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 6 in the THAI
Deuteronomy 6 in the TNFD
Deuteronomy 6 in the TNT
Deuteronomy 6 in the TNTIK
Deuteronomy 6 in the TNTIL
Deuteronomy 6 in the TNTIN
Deuteronomy 6 in the TNTIP
Deuteronomy 6 in the TNTIZ
Deuteronomy 6 in the TOMA
Deuteronomy 6 in the TTENT
Deuteronomy 6 in the UBG
Deuteronomy 6 in the UGV
Deuteronomy 6 in the UGV2
Deuteronomy 6 in the UGV3
Deuteronomy 6 in the VBL
Deuteronomy 6 in the VDCC
Deuteronomy 6 in the YALU
Deuteronomy 6 in the YAPE
Deuteronomy 6 in the YBVTP
Deuteronomy 6 in the ZBP