Ecclesiastes 2 (BOYCB)
1 Mo rò nínú ọkàn mi, “Wá nísinsin yìí, èmi yóò sì dán ọ wò pẹ̀lú ìgbádùn láti ṣe àwárí ohun tí ó dára.” Ṣùgbọ́n eléyìí náà jásí asán. 2 “Mo wí fún ẹ̀rín pé òmùgọ̀ ni. Àti fún ìre-ayọ̀ pé kí ni ó ń ṣe?” 3 Mo tiraka láti dun ara mi nínú pẹ̀lú ọtí wáìnì, àti láti fi ọwọ́ lé òmùgọ̀—ọkàn mi sì ń tọ́ mi pẹ̀lú ọgbọ́n. Mo fẹ́ wo ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe fún ènìyàn ní abẹ́ ọ̀run ní ìwọ̀nba ọjọ́ ayé rẹ̀. 4 Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá ńlá. Mo kọ́ ilé púpọ̀ fún ara mi, mo sì gbin ọgbà àjàrà púpọ̀. 5 Mo ṣe ọgbà àti àgbàlá, mo sì gbin onírúurú igi eléso sí inú wọn. 6 Mo gbẹ́ adágún láti máa bu omi rin àwọn igi tí ó ń hù jáde nínú ọgbà. 7 Mo ra àwọn ẹrú ọkùnrin àti àwọn ẹrú obìnrin, mo sì tún ní àwọn ẹrú mìíràn tí a bí sí ilé mi. Mo sì tún ní ẹran ọ̀sìn ju ẹnikẹ́ni ní Jerusalẹmu lọ. 8 Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi àti àwọn ohun ìṣúra ti ọba àti ìgbèríko. Mo ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin, àti dídùn inú ọmọ ènìyàn, aya àti obìnrin púpọ̀. 9 Mo di ẹni ńlá ju ẹnikẹ́ni tí ó wà ní Jerusalẹmu ṣáájú mi. Nínú gbogbo èyí, ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀. 10 Èmi kò jẹ́ kí ojú mi ṣe aláìrí ohun tí ó bá ń fẹ́.N kò sì jẹ́ kí ọkàn mi ó ṣe aláìní ìgbádùn.Ọkàn mi yọ̀ nínú gbogbo iṣẹ́ mi,èyí sì ni èrè fún gbogbo wàhálà mi. 11 Síbẹ̀, nígbà tí mo wo gbogbo ohun tí ọwọ́ mi ti ṣeàti ohun tí mo ti ṣe wàhálà láti ní:gbogbo rẹ̀, asán ni. Ó dàbí ẹnigbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́, kò sí èrè kan ní abẹ́ oòrùn;ọgbọ́n àti òmùgọ̀, asán ni. 12 Nígbà náà ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí ọgbọ́n,àti ìsínwín àti àìgbọ́nkí ni ọba tí ó jẹ lẹ́yìn tí ọba kan kú le è ṣeju èyí tí ọba ìṣáájú ti ṣe lọ. 13 Mo sì ri wí pé ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ti dára ju òkùnkùn lọ. 14 Ojú ọlọ́gbọ́n ń bẹ lágbárí rẹ̀,nígbà tí aṣiwèrè ń rìn nínú òkùnkùn,ṣùgbọ́n mo wá padà mọ̀wí pé ìpín kan náà ni ó ń dúró de ìsọ̀rí àwọn ènìyàn méjèèjì. 15 Nígbà náà ni mo rò nínú ọkàn wí pé,“Irú ìpín tí òmùgọ̀ ní yóò bá èmi náà pẹ̀lúkí wá ni ohun tí mo jẹ ní èrè nípa ọgbọ́n?”Mo sọ nínú ọkàn mi wí pé,“Asán ni eléyìí pẹ̀lú.” 16 Nítorí pé ọlọ́gbọ́n ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí i òmùgọ̀, a kì yóò rántí rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́;gbogbo wọn ni yóò di ohun ìgbàgbé ní ọjọ́ tó ń bọ̀.Ikú tí ó pa aṣiwèrè náà ni yóò pa ọlọ́gbọ́n ènìyàn. 17 Nítorí náà, mo kórìíra ìwàláàyè, nítorí pé iṣẹ́ tí wọn ń ṣe ní abẹ́ oòrùn ti mú ìdààmú bá mi. Gbogbo rẹ̀ asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni. 18 Mo kórìíra gbogbo ohun tí mo ti ṣiṣẹ́ fún ní abẹ́ oòrùn, nítorí pé mo ní láti fi wọ́n sílẹ̀ fún ẹni tí ó wà lẹ́yìn mi ni. 19 Ta ni ó wá mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni yóò jẹ́ tàbí aṣiwèrè? Síbẹ̀ yóò ní láti ṣe àkóso lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo tí ṣe yìí pẹ̀lú. 20 Nítorí náà, ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí ní kábámọ̀ lórí gbogbo àìsimi iṣẹ́ ṣíṣe mi ní abẹ́ oòrùn. 21 Nítorí pé ènìyàn le è ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní abẹ́ oòrùn, tí ó sì ti kọ́ ṣe iṣẹ́ fúnra rẹ̀. Asán ni eléyìí pẹ̀lú àti àdánù ńlá. 22 Kí ni ohun tí ènìyàn rí gbà fún gbogbo wàhálà àti ìpọ́njú tí ó fi ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn? 23 Gbogbo ọjọ́ rẹ, iṣẹ́ rẹ kún fún ìrora, àti ìbànújẹ́, kódà ọkàn rẹ̀ kì í ní ìsinmi ní alẹ́. Asán ni eléyìí pẹ̀lú. 24 Ènìyàn kò le è ṣe ohunkóhun tí ó dára jù pé kí ó jẹ kí ó sì mu, kí ó sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ rẹ̀. Mo rí wí pé eléyìí pẹ̀lú wá láti ọwọ́ Ọlọ́run. 25 Nítorí wí pé láìsí òun, ta ni ó le jẹ tàbí kí ó mọ adùn? 26 Fún ẹni tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ni Ọlọ́run yóò fún ní ọgbọ́n, ìmọ̀ àti ìdùnnú, ṣùgbọ́n fún ẹni dẹ́ṣẹ̀, Ó fún un ní iṣẹ́ láti ṣà àti láti kó ohun ìní pamọ́ kí ó sì fi fún ẹni tí ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Eléyìí pẹ̀lú, asán ni, ó dàbí ẹni gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
In Other Versions
Ecclesiastes 2 in the ANGEFD
Ecclesiastes 2 in the ANTPNG2D
Ecclesiastes 2 in the AS21
Ecclesiastes 2 in the BAGH
Ecclesiastes 2 in the BBPNG
Ecclesiastes 2 in the BBT1E
Ecclesiastes 2 in the BDS
Ecclesiastes 2 in the BEV
Ecclesiastes 2 in the BHAD
Ecclesiastes 2 in the BIB
Ecclesiastes 2 in the BLPT
Ecclesiastes 2 in the BNT
Ecclesiastes 2 in the BNTABOOT
Ecclesiastes 2 in the BNTLV
Ecclesiastes 2 in the BOATCB
Ecclesiastes 2 in the BOATCB2
Ecclesiastes 2 in the BOBCV
Ecclesiastes 2 in the BOCNT
Ecclesiastes 2 in the BOECS
Ecclesiastes 2 in the BOGWICC
Ecclesiastes 2 in the BOHCB
Ecclesiastes 2 in the BOHCV
Ecclesiastes 2 in the BOHLNT
Ecclesiastes 2 in the BOHNTLTAL
Ecclesiastes 2 in the BOICB
Ecclesiastes 2 in the BOILNTAP
Ecclesiastes 2 in the BOITCV
Ecclesiastes 2 in the BOKCV
Ecclesiastes 2 in the BOKCV2
Ecclesiastes 2 in the BOKHWOG
Ecclesiastes 2 in the BOKSSV
Ecclesiastes 2 in the BOLCB
Ecclesiastes 2 in the BOLCB2
Ecclesiastes 2 in the BOMCV
Ecclesiastes 2 in the BONAV
Ecclesiastes 2 in the BONCB
Ecclesiastes 2 in the BONLT
Ecclesiastes 2 in the BONUT2
Ecclesiastes 2 in the BOPLNT
Ecclesiastes 2 in the BOSCB
Ecclesiastes 2 in the BOSNC
Ecclesiastes 2 in the BOTLNT
Ecclesiastes 2 in the BOVCB
Ecclesiastes 2 in the BPBB
Ecclesiastes 2 in the BPH
Ecclesiastes 2 in the BSB
Ecclesiastes 2 in the CCB
Ecclesiastes 2 in the CUV
Ecclesiastes 2 in the CUVS
Ecclesiastes 2 in the DBT
Ecclesiastes 2 in the DGDNT
Ecclesiastes 2 in the DHNT
Ecclesiastes 2 in the DNT
Ecclesiastes 2 in the ELBE
Ecclesiastes 2 in the EMTV
Ecclesiastes 2 in the ESV
Ecclesiastes 2 in the FBV
Ecclesiastes 2 in the FEB
Ecclesiastes 2 in the GGMNT
Ecclesiastes 2 in the GNT
Ecclesiastes 2 in the HARY
Ecclesiastes 2 in the HNT
Ecclesiastes 2 in the IRVA
Ecclesiastes 2 in the IRVB
Ecclesiastes 2 in the IRVG
Ecclesiastes 2 in the IRVH
Ecclesiastes 2 in the IRVK
Ecclesiastes 2 in the IRVM
Ecclesiastes 2 in the IRVM2
Ecclesiastes 2 in the IRVO
Ecclesiastes 2 in the IRVP
Ecclesiastes 2 in the IRVT
Ecclesiastes 2 in the IRVT2
Ecclesiastes 2 in the IRVU
Ecclesiastes 2 in the ISVN
Ecclesiastes 2 in the JSNT
Ecclesiastes 2 in the KAPI
Ecclesiastes 2 in the KBT1ETNIK
Ecclesiastes 2 in the KBV
Ecclesiastes 2 in the KJV
Ecclesiastes 2 in the KNFD
Ecclesiastes 2 in the LBA
Ecclesiastes 2 in the LBLA
Ecclesiastes 2 in the LNT
Ecclesiastes 2 in the LSV
Ecclesiastes 2 in the MAAL
Ecclesiastes 2 in the MBV
Ecclesiastes 2 in the MBV2
Ecclesiastes 2 in the MHNT
Ecclesiastes 2 in the MKNFD
Ecclesiastes 2 in the MNG
Ecclesiastes 2 in the MNT
Ecclesiastes 2 in the MNT2
Ecclesiastes 2 in the MRS1T
Ecclesiastes 2 in the NAA
Ecclesiastes 2 in the NASB
Ecclesiastes 2 in the NBLA
Ecclesiastes 2 in the NBS
Ecclesiastes 2 in the NBVTP
Ecclesiastes 2 in the NET2
Ecclesiastes 2 in the NIV11
Ecclesiastes 2 in the NNT
Ecclesiastes 2 in the NNT2
Ecclesiastes 2 in the NNT3
Ecclesiastes 2 in the PDDPT
Ecclesiastes 2 in the PFNT
Ecclesiastes 2 in the RMNT
Ecclesiastes 2 in the SBIAS
Ecclesiastes 2 in the SBIBS
Ecclesiastes 2 in the SBIBS2
Ecclesiastes 2 in the SBICS
Ecclesiastes 2 in the SBIDS
Ecclesiastes 2 in the SBIGS
Ecclesiastes 2 in the SBIHS
Ecclesiastes 2 in the SBIIS
Ecclesiastes 2 in the SBIIS2
Ecclesiastes 2 in the SBIIS3
Ecclesiastes 2 in the SBIKS
Ecclesiastes 2 in the SBIKS2
Ecclesiastes 2 in the SBIMS
Ecclesiastes 2 in the SBIOS
Ecclesiastes 2 in the SBIPS
Ecclesiastes 2 in the SBISS
Ecclesiastes 2 in the SBITS
Ecclesiastes 2 in the SBITS2
Ecclesiastes 2 in the SBITS3
Ecclesiastes 2 in the SBITS4
Ecclesiastes 2 in the SBIUS
Ecclesiastes 2 in the SBIVS
Ecclesiastes 2 in the SBT
Ecclesiastes 2 in the SBT1E
Ecclesiastes 2 in the SCHL
Ecclesiastes 2 in the SNT
Ecclesiastes 2 in the SUSU
Ecclesiastes 2 in the SUSU2
Ecclesiastes 2 in the SYNO
Ecclesiastes 2 in the TBIAOTANT
Ecclesiastes 2 in the TBT1E
Ecclesiastes 2 in the TBT1E2
Ecclesiastes 2 in the TFTIP
Ecclesiastes 2 in the TFTU
Ecclesiastes 2 in the TGNTATF3T
Ecclesiastes 2 in the THAI
Ecclesiastes 2 in the TNFD
Ecclesiastes 2 in the TNT
Ecclesiastes 2 in the TNTIK
Ecclesiastes 2 in the TNTIL
Ecclesiastes 2 in the TNTIN
Ecclesiastes 2 in the TNTIP
Ecclesiastes 2 in the TNTIZ
Ecclesiastes 2 in the TOMA
Ecclesiastes 2 in the TTENT
Ecclesiastes 2 in the UBG
Ecclesiastes 2 in the UGV
Ecclesiastes 2 in the UGV2
Ecclesiastes 2 in the UGV3
Ecclesiastes 2 in the VBL
Ecclesiastes 2 in the VDCC
Ecclesiastes 2 in the YALU
Ecclesiastes 2 in the YAPE
Ecclesiastes 2 in the YBVTP
Ecclesiastes 2 in the ZBP