Exodus 19 (BOYCB)
1 Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai. 2 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá. 3 Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. OLÚWA sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: 4 ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. 5 Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú àmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. 6 Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” 7 Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti OLÚWA pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. 8 Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti OLÚWA wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ OLÚWA lọ. 9 OLÚWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún OLÚWA. 10 OLÚWA sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. 11 Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni OLÚWA yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. 12 Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á. 13 A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.” 14 Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 15 Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.” 16 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì. 17 Mose sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè. 18 Èéfín sì bo òkè Sinai nítorí OLÚWA sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. 19 Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn. 20 OLÚWA sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o sì pe Mose wá sí orí òkè náà. Mose sì gun orí òkè. 21 OLÚWA sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo OLÚWA, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé. 22 Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú OLÚWA gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. OLÚWA yóò kọlù wọ́n.” 23 Mose wí fún OLÚWA pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ” 24 OLÚWA sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ OLÚWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.” 25 Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí OLÚWA wí fún wọn.
In Other Versions
Exodus 19 in the ANGEFD
Exodus 19 in the ANTPNG2D
Exodus 19 in the AS21
Exodus 19 in the BAGH
Exodus 19 in the BBPNG
Exodus 19 in the BBT1E
Exodus 19 in the BDS
Exodus 19 in the BEV
Exodus 19 in the BHAD
Exodus 19 in the BIB
Exodus 19 in the BLPT
Exodus 19 in the BNT
Exodus 19 in the BNTABOOT
Exodus 19 in the BNTLV
Exodus 19 in the BOATCB
Exodus 19 in the BOATCB2
Exodus 19 in the BOBCV
Exodus 19 in the BOCNT
Exodus 19 in the BOECS
Exodus 19 in the BOGWICC
Exodus 19 in the BOHCB
Exodus 19 in the BOHCV
Exodus 19 in the BOHLNT
Exodus 19 in the BOHNTLTAL
Exodus 19 in the BOICB
Exodus 19 in the BOILNTAP
Exodus 19 in the BOITCV
Exodus 19 in the BOKCV
Exodus 19 in the BOKCV2
Exodus 19 in the BOKHWOG
Exodus 19 in the BOKSSV
Exodus 19 in the BOLCB
Exodus 19 in the BOLCB2
Exodus 19 in the BOMCV
Exodus 19 in the BONAV
Exodus 19 in the BONCB
Exodus 19 in the BONLT
Exodus 19 in the BONUT2
Exodus 19 in the BOPLNT
Exodus 19 in the BOSCB
Exodus 19 in the BOSNC
Exodus 19 in the BOTLNT
Exodus 19 in the BOVCB
Exodus 19 in the BPBB
Exodus 19 in the BPH
Exodus 19 in the BSB
Exodus 19 in the CCB
Exodus 19 in the CUV
Exodus 19 in the CUVS
Exodus 19 in the DBT
Exodus 19 in the DGDNT
Exodus 19 in the DHNT
Exodus 19 in the DNT
Exodus 19 in the ELBE
Exodus 19 in the EMTV
Exodus 19 in the ESV
Exodus 19 in the FBV
Exodus 19 in the FEB
Exodus 19 in the GGMNT
Exodus 19 in the GNT
Exodus 19 in the HARY
Exodus 19 in the HNT
Exodus 19 in the IRVA
Exodus 19 in the IRVB
Exodus 19 in the IRVG
Exodus 19 in the IRVH
Exodus 19 in the IRVK
Exodus 19 in the IRVM
Exodus 19 in the IRVM2
Exodus 19 in the IRVO
Exodus 19 in the IRVP
Exodus 19 in the IRVT
Exodus 19 in the IRVT2
Exodus 19 in the IRVU
Exodus 19 in the ISVN
Exodus 19 in the JSNT
Exodus 19 in the KAPI
Exodus 19 in the KBT1ETNIK
Exodus 19 in the KBV
Exodus 19 in the KJV
Exodus 19 in the KNFD
Exodus 19 in the LBA
Exodus 19 in the LBLA
Exodus 19 in the LNT
Exodus 19 in the LSV
Exodus 19 in the MAAL
Exodus 19 in the MBV
Exodus 19 in the MBV2
Exodus 19 in the MHNT
Exodus 19 in the MKNFD
Exodus 19 in the MNG
Exodus 19 in the MNT
Exodus 19 in the MNT2
Exodus 19 in the MRS1T
Exodus 19 in the NAA
Exodus 19 in the NASB
Exodus 19 in the NBLA
Exodus 19 in the NBS
Exodus 19 in the NBVTP
Exodus 19 in the NET2
Exodus 19 in the NIV11
Exodus 19 in the NNT
Exodus 19 in the NNT2
Exodus 19 in the NNT3
Exodus 19 in the PDDPT
Exodus 19 in the PFNT
Exodus 19 in the RMNT
Exodus 19 in the SBIAS
Exodus 19 in the SBIBS
Exodus 19 in the SBIBS2
Exodus 19 in the SBICS
Exodus 19 in the SBIDS
Exodus 19 in the SBIGS
Exodus 19 in the SBIHS
Exodus 19 in the SBIIS
Exodus 19 in the SBIIS2
Exodus 19 in the SBIIS3
Exodus 19 in the SBIKS
Exodus 19 in the SBIKS2
Exodus 19 in the SBIMS
Exodus 19 in the SBIOS
Exodus 19 in the SBIPS
Exodus 19 in the SBISS
Exodus 19 in the SBITS
Exodus 19 in the SBITS2
Exodus 19 in the SBITS3
Exodus 19 in the SBITS4
Exodus 19 in the SBIUS
Exodus 19 in the SBIVS
Exodus 19 in the SBT
Exodus 19 in the SBT1E
Exodus 19 in the SCHL
Exodus 19 in the SNT
Exodus 19 in the SUSU
Exodus 19 in the SUSU2
Exodus 19 in the SYNO
Exodus 19 in the TBIAOTANT
Exodus 19 in the TBT1E
Exodus 19 in the TBT1E2
Exodus 19 in the TFTIP
Exodus 19 in the TFTU
Exodus 19 in the TGNTATF3T
Exodus 19 in the THAI
Exodus 19 in the TNFD
Exodus 19 in the TNT
Exodus 19 in the TNTIK
Exodus 19 in the TNTIL
Exodus 19 in the TNTIN
Exodus 19 in the TNTIP
Exodus 19 in the TNTIZ
Exodus 19 in the TOMA
Exodus 19 in the TTENT
Exodus 19 in the UBG
Exodus 19 in the UGV
Exodus 19 in the UGV2
Exodus 19 in the UGV3
Exodus 19 in the VBL
Exodus 19 in the VDCC
Exodus 19 in the YALU
Exodus 19 in the YAPE
Exodus 19 in the YBVTP
Exodus 19 in the ZBP