Exodus 37 (BOYCB)
1 Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 2 Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 3 Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 4 Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. 5 Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e. 6 Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 7 Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 8 Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 9 Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́. 10 Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. 11 Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 12 Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 13 Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 14 Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. 15 Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 16 Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde. 17 Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà ní ojúlówó wúrà, ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, ìrudí rẹ àti agogo rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà. 18 Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 19 Àwo mẹ́ta ni a ṣe bí ìtànná almondi pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà. 20 Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 21 Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 22 Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà. 23 Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni. 24 Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara tálẹ́ǹtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà. 25 Igi kasia ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà. 26 Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká. 27 Ó ṣe òrùka wúrà méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní òdìkejì ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e. 28 Ó ṣe òpó igi ṣittimu, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà. 29 Ó sì túnṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí—iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.
In Other Versions
Exodus 37 in the ANGEFD
Exodus 37 in the ANTPNG2D
Exodus 37 in the AS21
Exodus 37 in the BAGH
Exodus 37 in the BBPNG
Exodus 37 in the BBT1E
Exodus 37 in the BDS
Exodus 37 in the BEV
Exodus 37 in the BHAD
Exodus 37 in the BIB
Exodus 37 in the BLPT
Exodus 37 in the BNT
Exodus 37 in the BNTABOOT
Exodus 37 in the BNTLV
Exodus 37 in the BOATCB
Exodus 37 in the BOATCB2
Exodus 37 in the BOBCV
Exodus 37 in the BOCNT
Exodus 37 in the BOECS
Exodus 37 in the BOGWICC
Exodus 37 in the BOHCB
Exodus 37 in the BOHCV
Exodus 37 in the BOHLNT
Exodus 37 in the BOHNTLTAL
Exodus 37 in the BOICB
Exodus 37 in the BOILNTAP
Exodus 37 in the BOITCV
Exodus 37 in the BOKCV
Exodus 37 in the BOKCV2
Exodus 37 in the BOKHWOG
Exodus 37 in the BOKSSV
Exodus 37 in the BOLCB
Exodus 37 in the BOLCB2
Exodus 37 in the BOMCV
Exodus 37 in the BONAV
Exodus 37 in the BONCB
Exodus 37 in the BONLT
Exodus 37 in the BONUT2
Exodus 37 in the BOPLNT
Exodus 37 in the BOSCB
Exodus 37 in the BOSNC
Exodus 37 in the BOTLNT
Exodus 37 in the BOVCB
Exodus 37 in the BPBB
Exodus 37 in the BPH
Exodus 37 in the BSB
Exodus 37 in the CCB
Exodus 37 in the CUV
Exodus 37 in the CUVS
Exodus 37 in the DBT
Exodus 37 in the DGDNT
Exodus 37 in the DHNT
Exodus 37 in the DNT
Exodus 37 in the ELBE
Exodus 37 in the EMTV
Exodus 37 in the ESV
Exodus 37 in the FBV
Exodus 37 in the FEB
Exodus 37 in the GGMNT
Exodus 37 in the GNT
Exodus 37 in the HARY
Exodus 37 in the HNT
Exodus 37 in the IRVA
Exodus 37 in the IRVB
Exodus 37 in the IRVG
Exodus 37 in the IRVH
Exodus 37 in the IRVK
Exodus 37 in the IRVM
Exodus 37 in the IRVM2
Exodus 37 in the IRVO
Exodus 37 in the IRVP
Exodus 37 in the IRVT
Exodus 37 in the IRVT2
Exodus 37 in the IRVU
Exodus 37 in the ISVN
Exodus 37 in the JSNT
Exodus 37 in the KAPI
Exodus 37 in the KBT1ETNIK
Exodus 37 in the KBV
Exodus 37 in the KJV
Exodus 37 in the KNFD
Exodus 37 in the LBA
Exodus 37 in the LBLA
Exodus 37 in the LNT
Exodus 37 in the LSV
Exodus 37 in the MAAL
Exodus 37 in the MBV
Exodus 37 in the MBV2
Exodus 37 in the MHNT
Exodus 37 in the MKNFD
Exodus 37 in the MNG
Exodus 37 in the MNT
Exodus 37 in the MNT2
Exodus 37 in the MRS1T
Exodus 37 in the NAA
Exodus 37 in the NASB
Exodus 37 in the NBLA
Exodus 37 in the NBS
Exodus 37 in the NBVTP
Exodus 37 in the NET2
Exodus 37 in the NIV11
Exodus 37 in the NNT
Exodus 37 in the NNT2
Exodus 37 in the NNT3
Exodus 37 in the PDDPT
Exodus 37 in the PFNT
Exodus 37 in the RMNT
Exodus 37 in the SBIAS
Exodus 37 in the SBIBS
Exodus 37 in the SBIBS2
Exodus 37 in the SBICS
Exodus 37 in the SBIDS
Exodus 37 in the SBIGS
Exodus 37 in the SBIHS
Exodus 37 in the SBIIS
Exodus 37 in the SBIIS2
Exodus 37 in the SBIIS3
Exodus 37 in the SBIKS
Exodus 37 in the SBIKS2
Exodus 37 in the SBIMS
Exodus 37 in the SBIOS
Exodus 37 in the SBIPS
Exodus 37 in the SBISS
Exodus 37 in the SBITS
Exodus 37 in the SBITS2
Exodus 37 in the SBITS3
Exodus 37 in the SBITS4
Exodus 37 in the SBIUS
Exodus 37 in the SBIVS
Exodus 37 in the SBT
Exodus 37 in the SBT1E
Exodus 37 in the SCHL
Exodus 37 in the SNT
Exodus 37 in the SUSU
Exodus 37 in the SUSU2
Exodus 37 in the SYNO
Exodus 37 in the TBIAOTANT
Exodus 37 in the TBT1E
Exodus 37 in the TBT1E2
Exodus 37 in the TFTIP
Exodus 37 in the TFTU
Exodus 37 in the TGNTATF3T
Exodus 37 in the THAI
Exodus 37 in the TNFD
Exodus 37 in the TNT
Exodus 37 in the TNTIK
Exodus 37 in the TNTIL
Exodus 37 in the TNTIN
Exodus 37 in the TNTIP
Exodus 37 in the TNTIZ
Exodus 37 in the TOMA
Exodus 37 in the TTENT
Exodus 37 in the UBG
Exodus 37 in the UGV
Exodus 37 in the UGV2
Exodus 37 in the UGV3
Exodus 37 in the VBL
Exodus 37 in the VDCC
Exodus 37 in the YALU
Exodus 37 in the YAPE
Exodus 37 in the YBVTP
Exodus 37 in the ZBP