Ezekiel 17 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ ní wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli. 3 Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí, idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi kedari tó ga jùlọ, 4 ó gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, ó mú un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò. 5 “ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò. 6 Ó dàgbà, ó sì di àjàrà tó kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú sí i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó di àjàrà, ó sì mu ẹ̀ka àti ewé jáde. 7 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó le fún un ni omi. 8 Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sì so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’ 9 “Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí nìyí, yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu. 10 Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ” 11 Nígbà náà, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mi wá pé: 12 “Sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé yìí, ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Sọ fún wọn: ‘Ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba àti àwọn ìjòyè ọmọ-aládé ibẹ̀ lọ sí Babeli lọ́dọ̀ rẹ̀. 13 Lẹ́yìn èyí, ó bá ọ̀kan nínú ọmọ ọba dá májẹ̀mú, ó mú un ìbúra, ó tún kó àwọn alágbára ilẹ̀ náà lọ. 14 Kí ìjọba ilẹ̀ náà le rẹ ilẹ̀, kí ó má lè gbé ara rẹ̀ sókè, kí ó lè dúró nípa pípa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. 15 Ṣùgbọ́n ọba ṣọ̀tẹ̀ sí i nípa ríran àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ sí Ejibiti, kí wọn bá à lè fún un ni ẹṣin àti àwọn ọmọ-ogun púpọ̀. Yóò ha ṣe àṣeyọrí? Ṣe ẹni tó ṣe irú nǹkan yìí yóò sì bọ́ níbẹ̀? Yóò ha dalẹ̀ tán kí ó sì bọ́ níbẹ̀ bí? 16 “ ‘Bí mo ti wà láààyè ni OLÚWA Olódùmarè wí, òun yóò kú ní Babeli, ní ilẹ̀ ọba tó fi sórí oyè, ìbúra ẹni tí ó kẹ́gàn àti májẹ̀mú ẹni tí ó dà. 17 Farao pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun àti àjọ ńlá rẹ̀ kò ní lè ṣe ìrànwọ́ fún un lójú ogun. Nígbà tí wọ́n bá pa bùdó ogun tì í, tí wọ́n sì mọ odi láti pa ọ̀pọ̀ ènìyàn. 18 Nítorí pé ó kẹ́gàn ìbúra nípa dída májẹ̀mú, àti pé ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìlérí, kì yóò bọ níbẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn nǹkan tí ó ṣe yìí. 19 “ ‘Nítorí náà OLÚWA Olódùmarè wí pé, bí mo ti wà láààyè, Èmi yóò mú ẹ̀san ẹ̀jẹ́ mi tó kẹ́gàn àti májẹ̀mú mi tó dà wa sórí rẹ̀. 20 Èmi yóò ta àwọ̀n mi sórí rẹ̀, yóò sì bọ sínú okùn mi, Èmi yóò mú ọ lọ Babeli láti ṣe ìdájọ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó hù sí mi. 21 Gbogbo ìgbèkùn àti ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ ni yóò kú pẹ̀lú idà, èmi yóò sì fọn àwọn ìyókù ká sínú afẹ́fẹ́ káàkiri. Nígbà náà ni yóò mọ̀ pé, “Èmi OLÚWA ni ó ti sọ̀rọ̀.” 22 “ ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí, Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí. 23 Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀. 24 Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi OLÚWA ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkúrú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.“ ‘Èmi OLÚWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì ṣe e.’ ”
In Other Versions
Ezekiel 17 in the ANGEFD
Ezekiel 17 in the ANTPNG2D
Ezekiel 17 in the AS21
Ezekiel 17 in the BAGH
Ezekiel 17 in the BBPNG
Ezekiel 17 in the BBT1E
Ezekiel 17 in the BDS
Ezekiel 17 in the BEV
Ezekiel 17 in the BHAD
Ezekiel 17 in the BIB
Ezekiel 17 in the BLPT
Ezekiel 17 in the BNT
Ezekiel 17 in the BNTABOOT
Ezekiel 17 in the BNTLV
Ezekiel 17 in the BOATCB
Ezekiel 17 in the BOATCB2
Ezekiel 17 in the BOBCV
Ezekiel 17 in the BOCNT
Ezekiel 17 in the BOECS
Ezekiel 17 in the BOGWICC
Ezekiel 17 in the BOHCB
Ezekiel 17 in the BOHCV
Ezekiel 17 in the BOHLNT
Ezekiel 17 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 17 in the BOICB
Ezekiel 17 in the BOILNTAP
Ezekiel 17 in the BOITCV
Ezekiel 17 in the BOKCV
Ezekiel 17 in the BOKCV2
Ezekiel 17 in the BOKHWOG
Ezekiel 17 in the BOKSSV
Ezekiel 17 in the BOLCB
Ezekiel 17 in the BOLCB2
Ezekiel 17 in the BOMCV
Ezekiel 17 in the BONAV
Ezekiel 17 in the BONCB
Ezekiel 17 in the BONLT
Ezekiel 17 in the BONUT2
Ezekiel 17 in the BOPLNT
Ezekiel 17 in the BOSCB
Ezekiel 17 in the BOSNC
Ezekiel 17 in the BOTLNT
Ezekiel 17 in the BOVCB
Ezekiel 17 in the BPBB
Ezekiel 17 in the BPH
Ezekiel 17 in the BSB
Ezekiel 17 in the CCB
Ezekiel 17 in the CUV
Ezekiel 17 in the CUVS
Ezekiel 17 in the DBT
Ezekiel 17 in the DGDNT
Ezekiel 17 in the DHNT
Ezekiel 17 in the DNT
Ezekiel 17 in the ELBE
Ezekiel 17 in the EMTV
Ezekiel 17 in the ESV
Ezekiel 17 in the FBV
Ezekiel 17 in the FEB
Ezekiel 17 in the GGMNT
Ezekiel 17 in the GNT
Ezekiel 17 in the HARY
Ezekiel 17 in the HNT
Ezekiel 17 in the IRVA
Ezekiel 17 in the IRVB
Ezekiel 17 in the IRVG
Ezekiel 17 in the IRVH
Ezekiel 17 in the IRVK
Ezekiel 17 in the IRVM
Ezekiel 17 in the IRVM2
Ezekiel 17 in the IRVO
Ezekiel 17 in the IRVP
Ezekiel 17 in the IRVT
Ezekiel 17 in the IRVT2
Ezekiel 17 in the IRVU
Ezekiel 17 in the ISVN
Ezekiel 17 in the JSNT
Ezekiel 17 in the KAPI
Ezekiel 17 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 17 in the KBV
Ezekiel 17 in the KJV
Ezekiel 17 in the KNFD
Ezekiel 17 in the LBA
Ezekiel 17 in the LBLA
Ezekiel 17 in the LNT
Ezekiel 17 in the LSV
Ezekiel 17 in the MAAL
Ezekiel 17 in the MBV
Ezekiel 17 in the MBV2
Ezekiel 17 in the MHNT
Ezekiel 17 in the MKNFD
Ezekiel 17 in the MNG
Ezekiel 17 in the MNT
Ezekiel 17 in the MNT2
Ezekiel 17 in the MRS1T
Ezekiel 17 in the NAA
Ezekiel 17 in the NASB
Ezekiel 17 in the NBLA
Ezekiel 17 in the NBS
Ezekiel 17 in the NBVTP
Ezekiel 17 in the NET2
Ezekiel 17 in the NIV11
Ezekiel 17 in the NNT
Ezekiel 17 in the NNT2
Ezekiel 17 in the NNT3
Ezekiel 17 in the PDDPT
Ezekiel 17 in the PFNT
Ezekiel 17 in the RMNT
Ezekiel 17 in the SBIAS
Ezekiel 17 in the SBIBS
Ezekiel 17 in the SBIBS2
Ezekiel 17 in the SBICS
Ezekiel 17 in the SBIDS
Ezekiel 17 in the SBIGS
Ezekiel 17 in the SBIHS
Ezekiel 17 in the SBIIS
Ezekiel 17 in the SBIIS2
Ezekiel 17 in the SBIIS3
Ezekiel 17 in the SBIKS
Ezekiel 17 in the SBIKS2
Ezekiel 17 in the SBIMS
Ezekiel 17 in the SBIOS
Ezekiel 17 in the SBIPS
Ezekiel 17 in the SBISS
Ezekiel 17 in the SBITS
Ezekiel 17 in the SBITS2
Ezekiel 17 in the SBITS3
Ezekiel 17 in the SBITS4
Ezekiel 17 in the SBIUS
Ezekiel 17 in the SBIVS
Ezekiel 17 in the SBT
Ezekiel 17 in the SBT1E
Ezekiel 17 in the SCHL
Ezekiel 17 in the SNT
Ezekiel 17 in the SUSU
Ezekiel 17 in the SUSU2
Ezekiel 17 in the SYNO
Ezekiel 17 in the TBIAOTANT
Ezekiel 17 in the TBT1E
Ezekiel 17 in the TBT1E2
Ezekiel 17 in the TFTIP
Ezekiel 17 in the TFTU
Ezekiel 17 in the TGNTATF3T
Ezekiel 17 in the THAI
Ezekiel 17 in the TNFD
Ezekiel 17 in the TNT
Ezekiel 17 in the TNTIK
Ezekiel 17 in the TNTIL
Ezekiel 17 in the TNTIN
Ezekiel 17 in the TNTIP
Ezekiel 17 in the TNTIZ
Ezekiel 17 in the TOMA
Ezekiel 17 in the TTENT
Ezekiel 17 in the UBG
Ezekiel 17 in the UGV
Ezekiel 17 in the UGV2
Ezekiel 17 in the UGV3
Ezekiel 17 in the VBL
Ezekiel 17 in the VDCC
Ezekiel 17 in the YALU
Ezekiel 17 in the YAPE
Ezekiel 17 in the YBVTP
Ezekiel 17 in the ZBP