Ezekiel 24 (BOYCB)
1 Ní ọdún kẹsànán, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí ọba Babeli náà ti da ojú ti Jerusalẹmu ní ọjọ́ yìí gan an. 3 Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná,gbé e ka iná kí o sì da omi sí i nínú. 4 Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀,gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá.Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀, 5 mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran.Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀;sì jẹ́ kí ó hó dáradárasì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀. 6 Nítorí báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà,fún ìkòkò náà tí èérí rẹ̀ wà nínú rẹ̀,tí èérí kò dà kúrò lójú rẹ̀!Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrímá ṣe ṣà wọ́n mú. 7 “ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárín rẹ̀;à á sí orí àpáta kan lásánkò dà á sí orí ilẹ̀,níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó. 8 Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀sanmo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán,kí o ma bà á wà ni bíbò. 9 Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà!Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkìtì iná náà tóbi. 10 Nítorí náà kó igi náà jọ sí i,kí o sì fi iná sí i.Ṣe ẹran náà dáradára,fi tùràrí dùn ún;kí o sì jẹ́ kí egungun náà jóná. 11 Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin inákí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́nàti ki ìfófó rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀kí èérí rẹ̀ le jó dànù. 12 Ó ti ba gbogbo akitiyan jẹ:èérí rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀,èérí náà gan an yóò wà nínú iná. 13 “ ‘Nísinsin yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èérí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀. 14 “ ‘Èmi OLÚWA ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni OLÚWA Olódùmarè wí.’ ” 15 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá pé: 16 “Ọmọ ènìyàn, kíyèsi i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sọkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀. 17 Má ṣe sọkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ, má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.” 18 Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàṣẹ fún mi. 19 Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?” 20 Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 21 Sọ fún ilé Israẹli, ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Kíyèsi i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ tayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáàánú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà. 22 Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà. 23 Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedéédéé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrín ara yín. 24 Esekiẹli yóò jẹ àmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Olódùmarè.’ 25 “Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn, 26 ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ. 27 Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì ṣí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní OLÚWA.”
In Other Versions
Ezekiel 24 in the ANGEFD
Ezekiel 24 in the ANTPNG2D
Ezekiel 24 in the AS21
Ezekiel 24 in the BAGH
Ezekiel 24 in the BBPNG
Ezekiel 24 in the BBT1E
Ezekiel 24 in the BDS
Ezekiel 24 in the BEV
Ezekiel 24 in the BHAD
Ezekiel 24 in the BIB
Ezekiel 24 in the BLPT
Ezekiel 24 in the BNT
Ezekiel 24 in the BNTABOOT
Ezekiel 24 in the BNTLV
Ezekiel 24 in the BOATCB
Ezekiel 24 in the BOATCB2
Ezekiel 24 in the BOBCV
Ezekiel 24 in the BOCNT
Ezekiel 24 in the BOECS
Ezekiel 24 in the BOGWICC
Ezekiel 24 in the BOHCB
Ezekiel 24 in the BOHCV
Ezekiel 24 in the BOHLNT
Ezekiel 24 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 24 in the BOICB
Ezekiel 24 in the BOILNTAP
Ezekiel 24 in the BOITCV
Ezekiel 24 in the BOKCV
Ezekiel 24 in the BOKCV2
Ezekiel 24 in the BOKHWOG
Ezekiel 24 in the BOKSSV
Ezekiel 24 in the BOLCB
Ezekiel 24 in the BOLCB2
Ezekiel 24 in the BOMCV
Ezekiel 24 in the BONAV
Ezekiel 24 in the BONCB
Ezekiel 24 in the BONLT
Ezekiel 24 in the BONUT2
Ezekiel 24 in the BOPLNT
Ezekiel 24 in the BOSCB
Ezekiel 24 in the BOSNC
Ezekiel 24 in the BOTLNT
Ezekiel 24 in the BOVCB
Ezekiel 24 in the BPBB
Ezekiel 24 in the BPH
Ezekiel 24 in the BSB
Ezekiel 24 in the CCB
Ezekiel 24 in the CUV
Ezekiel 24 in the CUVS
Ezekiel 24 in the DBT
Ezekiel 24 in the DGDNT
Ezekiel 24 in the DHNT
Ezekiel 24 in the DNT
Ezekiel 24 in the ELBE
Ezekiel 24 in the EMTV
Ezekiel 24 in the ESV
Ezekiel 24 in the FBV
Ezekiel 24 in the FEB
Ezekiel 24 in the GGMNT
Ezekiel 24 in the GNT
Ezekiel 24 in the HARY
Ezekiel 24 in the HNT
Ezekiel 24 in the IRVA
Ezekiel 24 in the IRVB
Ezekiel 24 in the IRVG
Ezekiel 24 in the IRVH
Ezekiel 24 in the IRVK
Ezekiel 24 in the IRVM
Ezekiel 24 in the IRVM2
Ezekiel 24 in the IRVO
Ezekiel 24 in the IRVP
Ezekiel 24 in the IRVT
Ezekiel 24 in the IRVT2
Ezekiel 24 in the IRVU
Ezekiel 24 in the ISVN
Ezekiel 24 in the JSNT
Ezekiel 24 in the KAPI
Ezekiel 24 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 24 in the KBV
Ezekiel 24 in the KJV
Ezekiel 24 in the KNFD
Ezekiel 24 in the LBA
Ezekiel 24 in the LBLA
Ezekiel 24 in the LNT
Ezekiel 24 in the LSV
Ezekiel 24 in the MAAL
Ezekiel 24 in the MBV
Ezekiel 24 in the MBV2
Ezekiel 24 in the MHNT
Ezekiel 24 in the MKNFD
Ezekiel 24 in the MNG
Ezekiel 24 in the MNT
Ezekiel 24 in the MNT2
Ezekiel 24 in the MRS1T
Ezekiel 24 in the NAA
Ezekiel 24 in the NASB
Ezekiel 24 in the NBLA
Ezekiel 24 in the NBS
Ezekiel 24 in the NBVTP
Ezekiel 24 in the NET2
Ezekiel 24 in the NIV11
Ezekiel 24 in the NNT
Ezekiel 24 in the NNT2
Ezekiel 24 in the NNT3
Ezekiel 24 in the PDDPT
Ezekiel 24 in the PFNT
Ezekiel 24 in the RMNT
Ezekiel 24 in the SBIAS
Ezekiel 24 in the SBIBS
Ezekiel 24 in the SBIBS2
Ezekiel 24 in the SBICS
Ezekiel 24 in the SBIDS
Ezekiel 24 in the SBIGS
Ezekiel 24 in the SBIHS
Ezekiel 24 in the SBIIS
Ezekiel 24 in the SBIIS2
Ezekiel 24 in the SBIIS3
Ezekiel 24 in the SBIKS
Ezekiel 24 in the SBIKS2
Ezekiel 24 in the SBIMS
Ezekiel 24 in the SBIOS
Ezekiel 24 in the SBIPS
Ezekiel 24 in the SBISS
Ezekiel 24 in the SBITS
Ezekiel 24 in the SBITS2
Ezekiel 24 in the SBITS3
Ezekiel 24 in the SBITS4
Ezekiel 24 in the SBIUS
Ezekiel 24 in the SBIVS
Ezekiel 24 in the SBT
Ezekiel 24 in the SBT1E
Ezekiel 24 in the SCHL
Ezekiel 24 in the SNT
Ezekiel 24 in the SUSU
Ezekiel 24 in the SUSU2
Ezekiel 24 in the SYNO
Ezekiel 24 in the TBIAOTANT
Ezekiel 24 in the TBT1E
Ezekiel 24 in the TBT1E2
Ezekiel 24 in the TFTIP
Ezekiel 24 in the TFTU
Ezekiel 24 in the TGNTATF3T
Ezekiel 24 in the THAI
Ezekiel 24 in the TNFD
Ezekiel 24 in the TNT
Ezekiel 24 in the TNTIK
Ezekiel 24 in the TNTIL
Ezekiel 24 in the TNTIN
Ezekiel 24 in the TNTIP
Ezekiel 24 in the TNTIZ
Ezekiel 24 in the TOMA
Ezekiel 24 in the TTENT
Ezekiel 24 in the UBG
Ezekiel 24 in the UGV
Ezekiel 24 in the UGV2
Ezekiel 24 in the UGV3
Ezekiel 24 in the VBL
Ezekiel 24 in the VDCC
Ezekiel 24 in the YALU
Ezekiel 24 in the YAPE
Ezekiel 24 in the YBVTP
Ezekiel 24 in the ZBP