Ezekiel 29 (BOYCB)
1 Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3 Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí:“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibitiìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú òkun tí ó dùbúlẹ̀ síàárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ.Èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.” 4 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹèmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹgbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ. 5 Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjùìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:ìwọ yóò ṣubú sí gbangba okoa kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbóàti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ. 6 Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé, Èmi ni OLÚWA. “ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7 Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n. 8 “ ‘Nítorí náà, èyí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Kíyèsi, Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9 Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní OLÚWA.“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili, Èmi ni mo ṣe é,” 10 nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀. 13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16 Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Olódùmarè.’ ” 17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19 Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20 Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni OLÚWA Olódùmarè wí. 21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.”
In Other Versions
Ezekiel 29 in the ANGEFD
Ezekiel 29 in the ANTPNG2D
Ezekiel 29 in the AS21
Ezekiel 29 in the BAGH
Ezekiel 29 in the BBPNG
Ezekiel 29 in the BBT1E
Ezekiel 29 in the BDS
Ezekiel 29 in the BEV
Ezekiel 29 in the BHAD
Ezekiel 29 in the BIB
Ezekiel 29 in the BLPT
Ezekiel 29 in the BNT
Ezekiel 29 in the BNTABOOT
Ezekiel 29 in the BNTLV
Ezekiel 29 in the BOATCB
Ezekiel 29 in the BOATCB2
Ezekiel 29 in the BOBCV
Ezekiel 29 in the BOCNT
Ezekiel 29 in the BOECS
Ezekiel 29 in the BOGWICC
Ezekiel 29 in the BOHCB
Ezekiel 29 in the BOHCV
Ezekiel 29 in the BOHLNT
Ezekiel 29 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 29 in the BOICB
Ezekiel 29 in the BOILNTAP
Ezekiel 29 in the BOITCV
Ezekiel 29 in the BOKCV
Ezekiel 29 in the BOKCV2
Ezekiel 29 in the BOKHWOG
Ezekiel 29 in the BOKSSV
Ezekiel 29 in the BOLCB
Ezekiel 29 in the BOLCB2
Ezekiel 29 in the BOMCV
Ezekiel 29 in the BONAV
Ezekiel 29 in the BONCB
Ezekiel 29 in the BONLT
Ezekiel 29 in the BONUT2
Ezekiel 29 in the BOPLNT
Ezekiel 29 in the BOSCB
Ezekiel 29 in the BOSNC
Ezekiel 29 in the BOTLNT
Ezekiel 29 in the BOVCB
Ezekiel 29 in the BPBB
Ezekiel 29 in the BPH
Ezekiel 29 in the BSB
Ezekiel 29 in the CCB
Ezekiel 29 in the CUV
Ezekiel 29 in the CUVS
Ezekiel 29 in the DBT
Ezekiel 29 in the DGDNT
Ezekiel 29 in the DHNT
Ezekiel 29 in the DNT
Ezekiel 29 in the ELBE
Ezekiel 29 in the EMTV
Ezekiel 29 in the ESV
Ezekiel 29 in the FBV
Ezekiel 29 in the FEB
Ezekiel 29 in the GGMNT
Ezekiel 29 in the GNT
Ezekiel 29 in the HARY
Ezekiel 29 in the HNT
Ezekiel 29 in the IRVA
Ezekiel 29 in the IRVB
Ezekiel 29 in the IRVG
Ezekiel 29 in the IRVH
Ezekiel 29 in the IRVK
Ezekiel 29 in the IRVM
Ezekiel 29 in the IRVM2
Ezekiel 29 in the IRVO
Ezekiel 29 in the IRVP
Ezekiel 29 in the IRVT
Ezekiel 29 in the IRVT2
Ezekiel 29 in the IRVU
Ezekiel 29 in the ISVN
Ezekiel 29 in the JSNT
Ezekiel 29 in the KAPI
Ezekiel 29 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 29 in the KBV
Ezekiel 29 in the KJV
Ezekiel 29 in the KNFD
Ezekiel 29 in the LBA
Ezekiel 29 in the LBLA
Ezekiel 29 in the LNT
Ezekiel 29 in the LSV
Ezekiel 29 in the MAAL
Ezekiel 29 in the MBV
Ezekiel 29 in the MBV2
Ezekiel 29 in the MHNT
Ezekiel 29 in the MKNFD
Ezekiel 29 in the MNG
Ezekiel 29 in the MNT
Ezekiel 29 in the MNT2
Ezekiel 29 in the MRS1T
Ezekiel 29 in the NAA
Ezekiel 29 in the NASB
Ezekiel 29 in the NBLA
Ezekiel 29 in the NBS
Ezekiel 29 in the NBVTP
Ezekiel 29 in the NET2
Ezekiel 29 in the NIV11
Ezekiel 29 in the NNT
Ezekiel 29 in the NNT2
Ezekiel 29 in the NNT3
Ezekiel 29 in the PDDPT
Ezekiel 29 in the PFNT
Ezekiel 29 in the RMNT
Ezekiel 29 in the SBIAS
Ezekiel 29 in the SBIBS
Ezekiel 29 in the SBIBS2
Ezekiel 29 in the SBICS
Ezekiel 29 in the SBIDS
Ezekiel 29 in the SBIGS
Ezekiel 29 in the SBIHS
Ezekiel 29 in the SBIIS
Ezekiel 29 in the SBIIS2
Ezekiel 29 in the SBIIS3
Ezekiel 29 in the SBIKS
Ezekiel 29 in the SBIKS2
Ezekiel 29 in the SBIMS
Ezekiel 29 in the SBIOS
Ezekiel 29 in the SBIPS
Ezekiel 29 in the SBISS
Ezekiel 29 in the SBITS
Ezekiel 29 in the SBITS2
Ezekiel 29 in the SBITS3
Ezekiel 29 in the SBITS4
Ezekiel 29 in the SBIUS
Ezekiel 29 in the SBIVS
Ezekiel 29 in the SBT
Ezekiel 29 in the SBT1E
Ezekiel 29 in the SCHL
Ezekiel 29 in the SNT
Ezekiel 29 in the SUSU
Ezekiel 29 in the SUSU2
Ezekiel 29 in the SYNO
Ezekiel 29 in the TBIAOTANT
Ezekiel 29 in the TBT1E
Ezekiel 29 in the TBT1E2
Ezekiel 29 in the TFTIP
Ezekiel 29 in the TFTU
Ezekiel 29 in the TGNTATF3T
Ezekiel 29 in the THAI
Ezekiel 29 in the TNFD
Ezekiel 29 in the TNT
Ezekiel 29 in the TNTIK
Ezekiel 29 in the TNTIL
Ezekiel 29 in the TNTIN
Ezekiel 29 in the TNTIP
Ezekiel 29 in the TNTIZ
Ezekiel 29 in the TOMA
Ezekiel 29 in the TTENT
Ezekiel 29 in the UBG
Ezekiel 29 in the UGV
Ezekiel 29 in the UGV2
Ezekiel 29 in the UGV3
Ezekiel 29 in the VBL
Ezekiel 29 in the VDCC
Ezekiel 29 in the YALU
Ezekiel 29 in the YAPE
Ezekiel 29 in the YBVTP
Ezekiel 29 in the ZBP