Ezekiel 33 (BOYCB)

1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá: 2 “Ọmọ ènìyàn sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ kí ó sì sọ fún wọn: ‘Nígbà tí mo bá fi idà kọlu ilẹ̀ kan, tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yan ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin wọn láti jẹ́ alóre wọn, 3 tí ó sì rí i pé idà ń bọ̀ lórí ilẹ̀ náà, tí ó sì fọn ìpè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, 4 nígbà náà tí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ìpè ṣùgbọ́n tí kò gbọ́ ìkìlọ̀, tí idà náà wá tí ó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀. 5 Nítorí tí ó gbọ́ ohùn ìpè ṣùgbọ́n tí kò sì gbọ́ ìkìlọ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí ara rẹ̀. Tí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀, òun ìbá ti gba ara rẹ̀ là. 6 Ṣùgbọ́n bí alóre bá rí idà tí o ń bọ̀, tí kò sì fọn ìpè láti ki àwọn ènìyàn nílọ̀, tí idà náà wá, tí ó sì gba ẹ̀mí ọ̀kan nínú wọn, a yóò mú ọkùnrin náà lọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.’ 7 “Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. 8 Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! Ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. 9 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí òun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là. 10 “Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń ṣòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’ 11 Sọ fún wọn pé, ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ni OLÚWA Olódùmarè wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè. Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú ẹ̀yin ènìyàn Israẹli?’ 12 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, ‘Ìṣòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀. Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀.’ 13 Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí nǹkan kan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe. 14 Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ. 15 Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú. 16 A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú. 17 “Síbẹ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ sọ pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò tọ́.’ Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí àwọn ní ó tọ́. 18 Bí olódodo ènìyàn ba yípadà kúrò nínú òdodo rẹ̀, tí o sì ṣe búburú, òun yóò kú nítorí rẹ̀. 19 Bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú búburú rẹ̀, tí ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ, òun yóò yè nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀. 20 Síbẹ̀, ilé Israẹli ìwọ wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa ki i ṣe òtítọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣe ìdájọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí.” 21 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kẹwàá, ọdún kejìlá ìkólọ wa, ọkùnrin kan tí ó sá kúrò ni Jerusalẹmu wá sọ́dọ̀ mi, ó sì wí pé, “Ìlú ńlá náà ti ṣubú!” 22 Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ku ọ̀la tí ẹni tí ó sálọ náà yóò dé, ọwọ́ OLÚWA sì níbẹ̀ lára mi, o sì ya ẹnu mi ki ọkùnrin náà tó wá sọ́dọ̀ mi ní òwúrọ̀. Ẹnu mí sì ṣí, èmi kò sì yadi mọ́. 23 Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá: 24 “Ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn tí ó ń gbé nínú ìparun ní ilẹ̀ Israẹli ń wí pé, ‘Abrahamu jẹ́ ọkùnrin kan, síbẹ̀ o gba ilẹ̀ ìní náà. Ṣùgbọ́n àwa pọ̀, lóòótọ́ a ti fi ilẹ̀ náà fún wa gẹ́gẹ́ bí ìní wa.’ 25 Nítorí náà, sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ní OLÚWA Olódùmarè wí: Níwọ́n ìgbà tí ẹ̀yin jẹ ẹran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ni inú rẹ̀, tí ẹ̀yin sì wó àwọn ère yín, tí ẹ sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà? 26 Ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé idà yín, ẹ̀yin ṣe nǹkan ìríra, ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú yín ba á obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́. Ẹ̀yin yóò ha gba ilẹ̀ náà?’ 27 “Sọ èyí fún wọn: ‘Èyí yìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Bí mo ti wà láààyè, àwọn tí ó kúrò nínú ìparun yóò ti ipa idà ṣubú, àwọn tí ẹranko búburú yóò pajẹ, àwọn tí ó sì wà ní ilé ìṣọ́ àti inú ihò òkúta ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò pa. 28 Èmi yóò mú kí ilẹ̀ náà di ahoro, ọ̀ṣọ́ ńlá agbára rẹ̀ kì yóò sí mọ́, àwọn òkè Israẹli yóò sì di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní le là á kọjá. 29 Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA, nígbà tí mo bá mú ilẹ̀ náà di ahoro nítorí gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ti ṣe.’ 30 “Ní tìrẹ, ọmọ ènìyàn, àwọn ènìyàn ìlú n sọ̀rọ̀ nípa rẹ ní ẹ̀gbẹ́ ògiri àti ní ẹnu-ọ̀nà ilé wọn, wọ́n ń sọ sí ara wọn wí pé, ‘Ẹ wá gbọ́ iṣẹ́ ti a ran láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá.’ 31 Àwọn ènìyàn mi wá sọ́dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń ṣe, wọn sì jókòó níwájú rẹ láti fetísí ọ̀rọ̀ rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò mú wá sí ìṣe. Ẹnu wọn ni wọ́n fi n sọ̀rọ̀ ìfọkànsìn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn ní ìwọra èrè tí kò tọ́. 32 Nítòótọ́ lójú wọn, ìwọ jẹ́ ẹni kan tí ó ń kọrin ìfẹ́ pẹ̀lú ohun dídára àti ohun èlò orin kíkọ, nítorí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ṣùgbọ́n wọn kò mu wá sí ìṣe. 33 “Nígbà tí gbogbo ìwọ̀nyí bá ṣẹ tí yóò sì ṣẹ dandan, nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan ti wa láàrín wọn rí.”

In Other Versions

Ezekiel 33 in the ANGEFD

Ezekiel 33 in the ANTPNG2D

Ezekiel 33 in the AS21

Ezekiel 33 in the BAGH

Ezekiel 33 in the BBPNG

Ezekiel 33 in the BBT1E

Ezekiel 33 in the BDS

Ezekiel 33 in the BEV

Ezekiel 33 in the BHAD

Ezekiel 33 in the BIB

Ezekiel 33 in the BLPT

Ezekiel 33 in the BNT

Ezekiel 33 in the BNTABOOT

Ezekiel 33 in the BNTLV

Ezekiel 33 in the BOATCB

Ezekiel 33 in the BOATCB2

Ezekiel 33 in the BOBCV

Ezekiel 33 in the BOCNT

Ezekiel 33 in the BOECS

Ezekiel 33 in the BOGWICC

Ezekiel 33 in the BOHCB

Ezekiel 33 in the BOHCV

Ezekiel 33 in the BOHLNT

Ezekiel 33 in the BOHNTLTAL

Ezekiel 33 in the BOICB

Ezekiel 33 in the BOILNTAP

Ezekiel 33 in the BOITCV

Ezekiel 33 in the BOKCV

Ezekiel 33 in the BOKCV2

Ezekiel 33 in the BOKHWOG

Ezekiel 33 in the BOKSSV

Ezekiel 33 in the BOLCB

Ezekiel 33 in the BOLCB2

Ezekiel 33 in the BOMCV

Ezekiel 33 in the BONAV

Ezekiel 33 in the BONCB

Ezekiel 33 in the BONLT

Ezekiel 33 in the BONUT2

Ezekiel 33 in the BOPLNT

Ezekiel 33 in the BOSCB

Ezekiel 33 in the BOSNC

Ezekiel 33 in the BOTLNT

Ezekiel 33 in the BOVCB

Ezekiel 33 in the BPBB

Ezekiel 33 in the BPH

Ezekiel 33 in the BSB

Ezekiel 33 in the CCB

Ezekiel 33 in the CUV

Ezekiel 33 in the CUVS

Ezekiel 33 in the DBT

Ezekiel 33 in the DGDNT

Ezekiel 33 in the DHNT

Ezekiel 33 in the DNT

Ezekiel 33 in the ELBE

Ezekiel 33 in the EMTV

Ezekiel 33 in the ESV

Ezekiel 33 in the FBV

Ezekiel 33 in the FEB

Ezekiel 33 in the GGMNT

Ezekiel 33 in the GNT

Ezekiel 33 in the HARY

Ezekiel 33 in the HNT

Ezekiel 33 in the IRVA

Ezekiel 33 in the IRVB

Ezekiel 33 in the IRVG

Ezekiel 33 in the IRVH

Ezekiel 33 in the IRVK

Ezekiel 33 in the IRVM

Ezekiel 33 in the IRVM2

Ezekiel 33 in the IRVO

Ezekiel 33 in the IRVP

Ezekiel 33 in the IRVT

Ezekiel 33 in the IRVT2

Ezekiel 33 in the IRVU

Ezekiel 33 in the ISVN

Ezekiel 33 in the JSNT

Ezekiel 33 in the KAPI

Ezekiel 33 in the KBT1ETNIK

Ezekiel 33 in the KBV

Ezekiel 33 in the KJV

Ezekiel 33 in the KNFD

Ezekiel 33 in the LBA

Ezekiel 33 in the LBLA

Ezekiel 33 in the LNT

Ezekiel 33 in the LSV

Ezekiel 33 in the MAAL

Ezekiel 33 in the MBV

Ezekiel 33 in the MBV2

Ezekiel 33 in the MHNT

Ezekiel 33 in the MKNFD

Ezekiel 33 in the MNG

Ezekiel 33 in the MNT

Ezekiel 33 in the MNT2

Ezekiel 33 in the MRS1T

Ezekiel 33 in the NAA

Ezekiel 33 in the NASB

Ezekiel 33 in the NBLA

Ezekiel 33 in the NBS

Ezekiel 33 in the NBVTP

Ezekiel 33 in the NET2

Ezekiel 33 in the NIV11

Ezekiel 33 in the NNT

Ezekiel 33 in the NNT2

Ezekiel 33 in the NNT3

Ezekiel 33 in the PDDPT

Ezekiel 33 in the PFNT

Ezekiel 33 in the RMNT

Ezekiel 33 in the SBIAS

Ezekiel 33 in the SBIBS

Ezekiel 33 in the SBIBS2

Ezekiel 33 in the SBICS

Ezekiel 33 in the SBIDS

Ezekiel 33 in the SBIGS

Ezekiel 33 in the SBIHS

Ezekiel 33 in the SBIIS

Ezekiel 33 in the SBIIS2

Ezekiel 33 in the SBIIS3

Ezekiel 33 in the SBIKS

Ezekiel 33 in the SBIKS2

Ezekiel 33 in the SBIMS

Ezekiel 33 in the SBIOS

Ezekiel 33 in the SBIPS

Ezekiel 33 in the SBISS

Ezekiel 33 in the SBITS

Ezekiel 33 in the SBITS2

Ezekiel 33 in the SBITS3

Ezekiel 33 in the SBITS4

Ezekiel 33 in the SBIUS

Ezekiel 33 in the SBIVS

Ezekiel 33 in the SBT

Ezekiel 33 in the SBT1E

Ezekiel 33 in the SCHL

Ezekiel 33 in the SNT

Ezekiel 33 in the SUSU

Ezekiel 33 in the SUSU2

Ezekiel 33 in the SYNO

Ezekiel 33 in the TBIAOTANT

Ezekiel 33 in the TBT1E

Ezekiel 33 in the TBT1E2

Ezekiel 33 in the TFTIP

Ezekiel 33 in the TFTU

Ezekiel 33 in the TGNTATF3T

Ezekiel 33 in the THAI

Ezekiel 33 in the TNFD

Ezekiel 33 in the TNT

Ezekiel 33 in the TNTIK

Ezekiel 33 in the TNTIL

Ezekiel 33 in the TNTIN

Ezekiel 33 in the TNTIP

Ezekiel 33 in the TNTIZ

Ezekiel 33 in the TOMA

Ezekiel 33 in the TTENT

Ezekiel 33 in the UBG

Ezekiel 33 in the UGV

Ezekiel 33 in the UGV2

Ezekiel 33 in the UGV3

Ezekiel 33 in the VBL

Ezekiel 33 in the VDCC

Ezekiel 33 in the YALU

Ezekiel 33 in the YAPE

Ezekiel 33 in the YBVTP

Ezekiel 33 in the ZBP