Ezekiel 38 (BOYCB)
1 Ọrọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i 3 kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali. 4 Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ-ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹṣinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèké, gbogbo wọn ń fi idà wọn. 5 Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn 6 Gomeri náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti Beti-Togarma láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀. 7 “ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn. 8 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, àwa yóò bẹ̀ ọ wò; ní ọdún ìkẹyìn ìwọ yóò dó ti ilẹ̀ tí a ti gbà padà lọ́wọ́ idà, tí àwọn ènìyàn wọn kórajọ pọ̀ láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sí àwọn òkè gíga ti Israẹli, tí ó ti di ahoro fún ìgbà pípẹ́. A ti mú wọn jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, nísinsin yìí gbogbo wọn ń gbé ní àìléwu. 9 Ìwọ àti ọ̀wọ́ ogun rẹ àti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ yóò gòkè, ẹ̀yin yóò tẹ̀síwájú bí ìjì; ìwọ yóò dàbí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀ mọ́lẹ̀. 10 “ ‘Èyí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà èrò kan yóò wá sọ́kàn rẹ, ìwọ yóò sì pète ìlànà búburú. 11 Ìwọ yóò wí pé, “Èmi yóò gbé ogun ti ilẹ̀ àwọn tí a kò fi odi yíká, Èmi yóò gbé ogun ti àwọn ènìyàn àlàáfíà tí a kò funra sí gbogbo wọn ń gbé ní àìsí odi, ní àìsí ẹnu-ọ̀nà òde àti àsígbè-irin. 12 Èmi yóò mú ohun ọdẹ, èmi yóò sì kó ìkógun, èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sí ibi ìwólulẹ̀ ti a ti tún kọ́, àwọn ènìyàn tí a kójọpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, tí ó ní ọrọ̀ nínú ẹran ọ̀sìn àti ẹrú, tí ó ń gbé ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ náà.” 13 Ṣeba, Dedani àti àwọn oníṣòwò Tarṣiṣi àti gbogbo àwọn ọmọ kìnnìún wọn, yóò sọ fún un yín pé, “Ṣé ẹ̀yin wá fún ìkógun? Ṣé ẹ̀yin ti kó àwọn ogun yín jọ pọ̀ fún ìkógun, láti kó fàdákà àti wúrà lọ, láti kó ẹran ọ̀sìn àti ẹrú àti láti gba ọ̀pọ̀ ìkógun?” ’ ” 14 “Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì sọ fún Gogu: ‘Èyí yìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ náà, nígbà tí àwọn ènìyàn mi Israẹli ń gbé ní àìléwu, ìwọ kì yóò ha ṣe àkíyèsí rẹ̀? 15 Ìwọ yóò wá láti ààyè rẹ ní jìnnàjìnnà àríwá, ìwọ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ, gbogbo wọn yóò sì gun ẹṣin ẹgbẹ́ ńlá, jagunjagun alágbára. 16 Ìwọ yóò tẹ̀síwájú ní ìlòdì sí àwọn Israẹli ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí ìkùùkuu tí ó bo ilẹ̀. Ni àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ìwọ Gogu, èmi yóò mú ọ wá ní ìlòdì sí ilẹ̀ mi, kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ mi nígbà tí mo bá fi ara hàn ni mímọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ní ojú wọn. 17 “ ‘Èyí yìí ni OLÚWA Olódùmarè wí: Ìwọ ha kọ́ ni mo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ìgbà ìṣáájú láti ẹnu àwọn wòlíì ìránṣẹ́ mi ti Israẹli? Ní ìgbà náà wọ́n sọtẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pé èmi yóò mú ọ lòdì sí wọn. 18 Èyí ni ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Gogu bá kọlu ilẹ̀ Israẹli, gbígbóná ìbínú mi yóò ru sókè, ni OLÚWA Olódùmarè wí. 19 Ní ìtara mi àti ní gbígbóná ìbínú mi, mo tẹnumọ́ ọn pé; ní àsìkò náà ilẹ̀ mímì tí ó lágbára ní ilẹ̀ Israẹli yóò ṣẹlẹ̀. 20 Ẹja inú Òkun, àwọn ẹyẹ òfúrufú, àwọn ẹranko igbó, àti gbogbo ẹ̀dá tí ó ń rìn lórí ilẹ̀ yóò wárìrì fún ìfarahàn mi. A yóò yí òkè gíga po, àwọn bèbè òkúta ni àwa yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́, gbogbo ògiri ni yóò wó palẹ̀. 21 Èmi yóò fa idà yọ ni ìlòdì sí Gogu ní orí gbogbo àwọn òkè gíga mi ni OLÚWA Olódùmarè wí. Idà gbogbo ènìyàn yóò lòdì sí arákùnrin rẹ̀. 22 Èmi yóò gbé ìdájọ́ mi jáde lórí rẹ̀ pẹ̀lú ìyọnu àti ìtàjẹ̀ sílẹ̀, Èmi yóò dá àgbàrá òjò, òkúta yìnyín àti imí-ọjọ́ tí ń jó lé e lórí àti lórí ọ̀wọ́ ogun àti lórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀. 23 Nítorí náà, Èmi yóò fi títóbi mi àti ìjẹ́-mímọ́ mi hàn, Èmi yóò sì fi ara mi hàn ní ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’
In Other Versions
Ezekiel 38 in the ANGEFD
Ezekiel 38 in the ANTPNG2D
Ezekiel 38 in the AS21
Ezekiel 38 in the BAGH
Ezekiel 38 in the BBPNG
Ezekiel 38 in the BBT1E
Ezekiel 38 in the BDS
Ezekiel 38 in the BEV
Ezekiel 38 in the BHAD
Ezekiel 38 in the BIB
Ezekiel 38 in the BLPT
Ezekiel 38 in the BNT
Ezekiel 38 in the BNTABOOT
Ezekiel 38 in the BNTLV
Ezekiel 38 in the BOATCB
Ezekiel 38 in the BOATCB2
Ezekiel 38 in the BOBCV
Ezekiel 38 in the BOCNT
Ezekiel 38 in the BOECS
Ezekiel 38 in the BOGWICC
Ezekiel 38 in the BOHCB
Ezekiel 38 in the BOHCV
Ezekiel 38 in the BOHLNT
Ezekiel 38 in the BOHNTLTAL
Ezekiel 38 in the BOICB
Ezekiel 38 in the BOILNTAP
Ezekiel 38 in the BOITCV
Ezekiel 38 in the BOKCV
Ezekiel 38 in the BOKCV2
Ezekiel 38 in the BOKHWOG
Ezekiel 38 in the BOKSSV
Ezekiel 38 in the BOLCB
Ezekiel 38 in the BOLCB2
Ezekiel 38 in the BOMCV
Ezekiel 38 in the BONAV
Ezekiel 38 in the BONCB
Ezekiel 38 in the BONLT
Ezekiel 38 in the BONUT2
Ezekiel 38 in the BOPLNT
Ezekiel 38 in the BOSCB
Ezekiel 38 in the BOSNC
Ezekiel 38 in the BOTLNT
Ezekiel 38 in the BOVCB
Ezekiel 38 in the BPBB
Ezekiel 38 in the BPH
Ezekiel 38 in the BSB
Ezekiel 38 in the CCB
Ezekiel 38 in the CUV
Ezekiel 38 in the CUVS
Ezekiel 38 in the DBT
Ezekiel 38 in the DGDNT
Ezekiel 38 in the DHNT
Ezekiel 38 in the DNT
Ezekiel 38 in the ELBE
Ezekiel 38 in the EMTV
Ezekiel 38 in the ESV
Ezekiel 38 in the FBV
Ezekiel 38 in the FEB
Ezekiel 38 in the GGMNT
Ezekiel 38 in the GNT
Ezekiel 38 in the HARY
Ezekiel 38 in the HNT
Ezekiel 38 in the IRVA
Ezekiel 38 in the IRVB
Ezekiel 38 in the IRVG
Ezekiel 38 in the IRVH
Ezekiel 38 in the IRVK
Ezekiel 38 in the IRVM
Ezekiel 38 in the IRVM2
Ezekiel 38 in the IRVO
Ezekiel 38 in the IRVP
Ezekiel 38 in the IRVT
Ezekiel 38 in the IRVT2
Ezekiel 38 in the IRVU
Ezekiel 38 in the ISVN
Ezekiel 38 in the JSNT
Ezekiel 38 in the KAPI
Ezekiel 38 in the KBT1ETNIK
Ezekiel 38 in the KBV
Ezekiel 38 in the KJV
Ezekiel 38 in the KNFD
Ezekiel 38 in the LBA
Ezekiel 38 in the LBLA
Ezekiel 38 in the LNT
Ezekiel 38 in the LSV
Ezekiel 38 in the MAAL
Ezekiel 38 in the MBV
Ezekiel 38 in the MBV2
Ezekiel 38 in the MHNT
Ezekiel 38 in the MKNFD
Ezekiel 38 in the MNG
Ezekiel 38 in the MNT
Ezekiel 38 in the MNT2
Ezekiel 38 in the MRS1T
Ezekiel 38 in the NAA
Ezekiel 38 in the NASB
Ezekiel 38 in the NBLA
Ezekiel 38 in the NBS
Ezekiel 38 in the NBVTP
Ezekiel 38 in the NET2
Ezekiel 38 in the NIV11
Ezekiel 38 in the NNT
Ezekiel 38 in the NNT2
Ezekiel 38 in the NNT3
Ezekiel 38 in the PDDPT
Ezekiel 38 in the PFNT
Ezekiel 38 in the RMNT
Ezekiel 38 in the SBIAS
Ezekiel 38 in the SBIBS
Ezekiel 38 in the SBIBS2
Ezekiel 38 in the SBICS
Ezekiel 38 in the SBIDS
Ezekiel 38 in the SBIGS
Ezekiel 38 in the SBIHS
Ezekiel 38 in the SBIIS
Ezekiel 38 in the SBIIS2
Ezekiel 38 in the SBIIS3
Ezekiel 38 in the SBIKS
Ezekiel 38 in the SBIKS2
Ezekiel 38 in the SBIMS
Ezekiel 38 in the SBIOS
Ezekiel 38 in the SBIPS
Ezekiel 38 in the SBISS
Ezekiel 38 in the SBITS
Ezekiel 38 in the SBITS2
Ezekiel 38 in the SBITS3
Ezekiel 38 in the SBITS4
Ezekiel 38 in the SBIUS
Ezekiel 38 in the SBIVS
Ezekiel 38 in the SBT
Ezekiel 38 in the SBT1E
Ezekiel 38 in the SCHL
Ezekiel 38 in the SNT
Ezekiel 38 in the SUSU
Ezekiel 38 in the SUSU2
Ezekiel 38 in the SYNO
Ezekiel 38 in the TBIAOTANT
Ezekiel 38 in the TBT1E
Ezekiel 38 in the TBT1E2
Ezekiel 38 in the TFTIP
Ezekiel 38 in the TFTU
Ezekiel 38 in the TGNTATF3T
Ezekiel 38 in the THAI
Ezekiel 38 in the TNFD
Ezekiel 38 in the TNT
Ezekiel 38 in the TNTIK
Ezekiel 38 in the TNTIL
Ezekiel 38 in the TNTIN
Ezekiel 38 in the TNTIP
Ezekiel 38 in the TNTIZ
Ezekiel 38 in the TOMA
Ezekiel 38 in the TTENT
Ezekiel 38 in the UBG
Ezekiel 38 in the UGV
Ezekiel 38 in the UGV2
Ezekiel 38 in the UGV3
Ezekiel 38 in the VBL
Ezekiel 38 in the VDCC
Ezekiel 38 in the YALU
Ezekiel 38 in the YAPE
Ezekiel 38 in the YBVTP
Ezekiel 38 in the ZBP