Galatians 2 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá, ni mo tún gòkè lọ sì Jerusalẹmu pẹ̀lú Barnaba, mo sì mú Titu lọ pẹ̀lú mi. 2 Mo gòkè lọ nípa ohun ti a fihàn mi, mo fi ìyìnrere náà tí mo ń wàásù láàrín àwọn aláìkọlà yé àwọn tí ó jẹ́ ẹni ńlá nínú wọn, èyí i nì ní ìkọ̀kọ̀, kí èmi kí ó má ba á sáré, tàbí kí ó máa ba à jẹ́ pé mo ti sáré lásán. 3 Ṣùgbọ́n a kò fi agbára mú Titu tí ó wà pẹ̀lú mi, ẹni tí í ṣe ara Giriki láti kọlà. 4 Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nítorí àwọn èké arákùnrin tí wọn yọ́ wọ inú àárín wa láti yọ́ òmìnira wa wò, èyí tí àwa ni nínú Kristi Jesu, kí wọn lè mú wa wá sínú ìdè. 5 Àwọn ẹni ti a kò fún ni àǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn fún ìṣẹ́jú kan; kí ẹ̀yin kí o lè máa tẹ̀síwájú nínú òtítọ́ ìyìnrere náà. 6 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó dàbí ẹni pàtàkì—ohunkóhun tí ó wù kì wọn jásí, kò jẹ́ nǹkan kan fún mi; Ọlọ́run kò fi bí ẹnikẹ́ni ṣe rí ṣe ìdájọ́ rẹ̀—àwọn ènìyàn yìí kò fi ohunkóhun kún ọ̀rọ̀ mi. 7 Ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọn rí i pé a tí fi ìyìnrere tí àwọn aláìkọlà le mi lọ́wọ́, bí a tí fi ìyìnrere tí àwọn onílà lé Peteru lọ́wọ́. 8 Nítorí Ọlọ́run, ẹni tí ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Peteru gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn Júù, òun kan náà ni ó ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí aposteli sí àwọn aláìkọlà. 9 Jakọbu, Peteru, àti Johanu, àwọn ẹni tí ó dàbí ọ̀wọ́n, fún èmi àti Barnaba ni ọwọ́ ọ̀tún ìdàpọ̀ nígbà tí wọ́n rí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, wọ́n sì gbà pé kí àwa náà tọ àwọn aláìkọlà lọ, nígbà ti àwọn náà lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù. 10 Ohun gbogbo tí wọ́n béèrè fún ni wí pé, kí a máa rántí àwọn tálákà, ohun kan náà gan an tí mo ń làkàkà láti ṣe. 11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Peteru wá sí Antioku, mo takò ó lójú ara rẹ̀, nítorí tí ó jẹ̀bi, mo sì bá a wí. 12 Nítorí pé kí àwọn kan tí ó ti ọ̀dọ̀ Jakọbu wá tó dé, ó ti ń ba àwọn aláìkọlà jẹun; ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé, ó fàsẹ́yìn, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà nítorí ó bẹ̀rù àwọn ti ó kọlà. 13 Àwọn Júù tí ó kù pawọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti jùmọ̀ ṣe àgàbàgebè, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn sì fi àgàbàgebè wọn si Barnaba lọ́nà. 14 Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn kèfèrí, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn kèfèrí láti máa rìn bí àwọn Júù? 15 “Àwa tí i ṣe Júù nípa ìbí, tí kì i sí ì ṣe aláìkọlà ẹlẹ́ṣẹ̀, 16 tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹ́ni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, àní àwa pẹ̀lú gbà Jesu Kristi gbọ́, kí a bá a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kristi, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin, nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre. 17 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwa bá ń wá ọ̀nà láti rí ìdáláre nípa Kristi, ó di ẹ̀rí wí pé àwa pẹ̀lú jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ǹjẹ́ èyí ha jásí wí pé Kristi ń ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí ì! 18 Nítorí pé bí mo bá sì tún gbé àwọn ohun tí mo tí wó palẹ̀ ró, mo fi ara mi hàn bí arúfin. 19 “Nítorí pé nípa òfin, mo tí di òkú sí òfin, kí èmi lè wà láààyè sí Ọlọ́run. 20 A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kristi, èmí kò sì wà láààyè mọ́, ṣùgbọ́n Kristi ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láààyè nínú ara, mo wà láààyè nínú ìgbàgbọ́ Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkára rẹ̀ fún mi. 21 Èmi kò ya oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sí apá kan, nítorí pé bí a bá le ti ipasẹ̀ òfin jèrè òdodo, a jẹ́ pé Kristi kú lásán.”
In Other Versions
Galatians 2 in the ANGEFD
Galatians 2 in the ANTPNG2D
Galatians 2 in the AS21
Galatians 2 in the BAGH
Galatians 2 in the BBPNG
Galatians 2 in the BBT1E
Galatians 2 in the BDS
Galatians 2 in the BEV
Galatians 2 in the BHAD
Galatians 2 in the BIB
Galatians 2 in the BLPT
Galatians 2 in the BNT
Galatians 2 in the BNTABOOT
Galatians 2 in the BNTLV
Galatians 2 in the BOATCB
Galatians 2 in the BOATCB2
Galatians 2 in the BOBCV
Galatians 2 in the BOCNT
Galatians 2 in the BOECS
Galatians 2 in the BOGWICC
Galatians 2 in the BOHCB
Galatians 2 in the BOHCV
Galatians 2 in the BOHLNT
Galatians 2 in the BOHNTLTAL
Galatians 2 in the BOICB
Galatians 2 in the BOILNTAP
Galatians 2 in the BOITCV
Galatians 2 in the BOKCV
Galatians 2 in the BOKCV2
Galatians 2 in the BOKHWOG
Galatians 2 in the BOKSSV
Galatians 2 in the BOLCB
Galatians 2 in the BOLCB2
Galatians 2 in the BOMCV
Galatians 2 in the BONAV
Galatians 2 in the BONCB
Galatians 2 in the BONLT
Galatians 2 in the BONUT2
Galatians 2 in the BOPLNT
Galatians 2 in the BOSCB
Galatians 2 in the BOSNC
Galatians 2 in the BOTLNT
Galatians 2 in the BOVCB
Galatians 2 in the BPBB
Galatians 2 in the BPH
Galatians 2 in the BSB
Galatians 2 in the CCB
Galatians 2 in the CUV
Galatians 2 in the CUVS
Galatians 2 in the DBT
Galatians 2 in the DGDNT
Galatians 2 in the DHNT
Galatians 2 in the DNT
Galatians 2 in the ELBE
Galatians 2 in the EMTV
Galatians 2 in the ESV
Galatians 2 in the FBV
Galatians 2 in the FEB
Galatians 2 in the GGMNT
Galatians 2 in the GNT
Galatians 2 in the HARY
Galatians 2 in the HNT
Galatians 2 in the IRVA
Galatians 2 in the IRVB
Galatians 2 in the IRVG
Galatians 2 in the IRVH
Galatians 2 in the IRVK
Galatians 2 in the IRVM
Galatians 2 in the IRVM2
Galatians 2 in the IRVO
Galatians 2 in the IRVP
Galatians 2 in the IRVT
Galatians 2 in the IRVT2
Galatians 2 in the IRVU
Galatians 2 in the ISVN
Galatians 2 in the JSNT
Galatians 2 in the KAPI
Galatians 2 in the KBT1ETNIK
Galatians 2 in the KBV
Galatians 2 in the KJV
Galatians 2 in the KNFD
Galatians 2 in the LBA
Galatians 2 in the LBLA
Galatians 2 in the LNT
Galatians 2 in the LSV
Galatians 2 in the MAAL
Galatians 2 in the MBV
Galatians 2 in the MBV2
Galatians 2 in the MHNT
Galatians 2 in the MKNFD
Galatians 2 in the MNG
Galatians 2 in the MNT
Galatians 2 in the MNT2
Galatians 2 in the MRS1T
Galatians 2 in the NAA
Galatians 2 in the NASB
Galatians 2 in the NBLA
Galatians 2 in the NBS
Galatians 2 in the NBVTP
Galatians 2 in the NET2
Galatians 2 in the NIV11
Galatians 2 in the NNT
Galatians 2 in the NNT2
Galatians 2 in the NNT3
Galatians 2 in the PDDPT
Galatians 2 in the PFNT
Galatians 2 in the RMNT
Galatians 2 in the SBIAS
Galatians 2 in the SBIBS
Galatians 2 in the SBIBS2
Galatians 2 in the SBICS
Galatians 2 in the SBIDS
Galatians 2 in the SBIGS
Galatians 2 in the SBIHS
Galatians 2 in the SBIIS
Galatians 2 in the SBIIS2
Galatians 2 in the SBIIS3
Galatians 2 in the SBIKS
Galatians 2 in the SBIKS2
Galatians 2 in the SBIMS
Galatians 2 in the SBIOS
Galatians 2 in the SBIPS
Galatians 2 in the SBISS
Galatians 2 in the SBITS
Galatians 2 in the SBITS2
Galatians 2 in the SBITS3
Galatians 2 in the SBITS4
Galatians 2 in the SBIUS
Galatians 2 in the SBIVS
Galatians 2 in the SBT
Galatians 2 in the SBT1E
Galatians 2 in the SCHL
Galatians 2 in the SNT
Galatians 2 in the SUSU
Galatians 2 in the SUSU2
Galatians 2 in the SYNO
Galatians 2 in the TBIAOTANT
Galatians 2 in the TBT1E
Galatians 2 in the TBT1E2
Galatians 2 in the TFTIP
Galatians 2 in the TFTU
Galatians 2 in the TGNTATF3T
Galatians 2 in the THAI
Galatians 2 in the TNFD
Galatians 2 in the TNT
Galatians 2 in the TNTIK
Galatians 2 in the TNTIL
Galatians 2 in the TNTIN
Galatians 2 in the TNTIP
Galatians 2 in the TNTIZ
Galatians 2 in the TOMA
Galatians 2 in the TTENT
Galatians 2 in the UBG
Galatians 2 in the UGV
Galatians 2 in the UGV2
Galatians 2 in the UGV3
Galatians 2 in the VBL
Galatians 2 in the VDCC
Galatians 2 in the YALU
Galatians 2 in the YAPE
Galatians 2 in the YBVTP
Galatians 2 in the ZBP