Genesis 1 (BOYCB)
1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ohun gbogbo Ọlọ́run dá àwọn ọ̀run àti ayé. 2 Ayé sì wà ní rúdurùdu, ó sì ṣófo, òkùnkùn sì wà lójú ibú omi, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì ń rábàbà lójú omi. 3 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà,” ìmọ́lẹ̀ sì wà. 4 Ọlọ́run rí i pé ìmọ́lẹ̀ náà dára, ó sì ya ìmọ́lẹ̀ náà sọ́tọ̀ kúrò lára òkùnkùn. 5 Ọlọ́run sì pe ìmọ́lẹ̀ náà ní “ọ̀sán,” àti òkùnkùn ní “òru.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní. 6 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí òfúrufú kí ó wà ní àárín àwọn omi, láti pààlà sí àárín àwọn omi.” 7 Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 8 Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “ọ̀run.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. 9 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10 Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. 11 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 12 Ilẹ̀ sì hù ọ̀gbìn: ewéko tí ó ń so èso ní irú tirẹ̀, àti igi tí ń so èso, tí ó ní irúgbìn nínú ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì ri pé ó dára. 13 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹta. 14 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, láti pààlà sí àárín ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún. 15 Kí wọn ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti tan ìmọ́lẹ̀ sí orí ilẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 16 Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú. 17 Ọlọ́run sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ si orí ilẹ̀, 18 láti ṣàkóso ọ̀sán àti òru àti láti pààlà sí àárín ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 19 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹrin. 20 Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi kí ó kún fún àwọn ohun alààyè, kí àwọn ẹyẹ kí ó sì máa fò ní òfúrufú.” 21 Nítorí náà Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá alààyè ńlá ńlá sí inú òkun, àwọn ohun ẹlẹ́mìí àti àwọn ohun tí ń rìn ní onírúurú tiwọn, àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́ ní onírúurú tiwọn. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 22 Ọlọ́run súre fún wọn, ó sì wí pé, “Ẹ máa bí sí i, ẹ sì máa pọ̀ sí i, ẹ kún inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i ní orí ilẹ̀.” 23 Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ karùn-ún. 24 Ọlọ́run sì wí pé, “Kí ilẹ̀ kí ó mú ohun alààyè jáde ní onírúurú wọn: ẹran ọ̀sìn, àwọn ohun afàyàfà àti àwọn ẹran inú igbó, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní irú tirẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 25 Ọlọ́run sì dá ẹranko inú igbó àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ní irú tirẹ̀ àti gbogbo ohun alààyè tí ń rìn ní ilẹ̀ ní irú tirẹ̀. Ọlọ́run sì rí i pé ó dára. 26 Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, gẹ́gẹ́ bí àwa ti rí, kí wọn kí ó jẹ ọba lórí ẹja òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, ẹran ọ̀sìn, gbogbo ilẹ̀ àti lórí ohun gbogbo tí ń rìn lórí ilẹ̀.” 27 Nítorí náà, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀,ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a,akọ àti abo ni ó dá wọn. 28 Ọlọ́run sì súre fún wọn, Ọlọ́run sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa bí sí i, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ sì gbilẹ̀, kí ẹ ṣe ìkápá ayé. Ẹ ṣe àkóso àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó ń rìn ní orí ilẹ̀.” 29 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo fi gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso fún un yín bí oúnjẹ àti àwọn igi eléso pẹ̀lú. Gbogbo rẹ̀ yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín. 30 Àti fún àwọn ẹranko inú igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ohun afàyàfà, gbogbo ohun tó ní èémí ìyè nínú ni mo fi ewéko fún bí oúnjẹ.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 31 Ọlọ́run sì rí àwọn ohun gbogbo tí ó dá, ó dára gidigidi. Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kẹfà.
In Other Versions
Genesis 1 in the ANGEFD
Genesis 1 in the ANTPNG2D
Genesis 1 in the AS21
Genesis 1 in the BAGH
Genesis 1 in the BBPNG
Genesis 1 in the BBT1E
Genesis 1 in the BDS
Genesis 1 in the BEV
Genesis 1 in the BHAD
Genesis 1 in the BIB
Genesis 1 in the BLPT
Genesis 1 in the BNT
Genesis 1 in the BNTABOOT
Genesis 1 in the BNTLV
Genesis 1 in the BOATCB
Genesis 1 in the BOATCB2
Genesis 1 in the BOBCV
Genesis 1 in the BOCNT
Genesis 1 in the BOECS
Genesis 1 in the BOGWICC
Genesis 1 in the BOHCB
Genesis 1 in the BOHCV
Genesis 1 in the BOHLNT
Genesis 1 in the BOHNTLTAL
Genesis 1 in the BOICB
Genesis 1 in the BOILNTAP
Genesis 1 in the BOITCV
Genesis 1 in the BOKCV
Genesis 1 in the BOKCV2
Genesis 1 in the BOKHWOG
Genesis 1 in the BOKSSV
Genesis 1 in the BOLCB
Genesis 1 in the BOLCB2
Genesis 1 in the BOMCV
Genesis 1 in the BONAV
Genesis 1 in the BONCB
Genesis 1 in the BONLT
Genesis 1 in the BONUT2
Genesis 1 in the BOPLNT
Genesis 1 in the BOSCB
Genesis 1 in the BOSNC
Genesis 1 in the BOTLNT
Genesis 1 in the BOVCB
Genesis 1 in the BPBB
Genesis 1 in the BPH
Genesis 1 in the BSB
Genesis 1 in the CCB
Genesis 1 in the CUV
Genesis 1 in the CUVS
Genesis 1 in the DBT
Genesis 1 in the DGDNT
Genesis 1 in the DHNT
Genesis 1 in the DNT
Genesis 1 in the ELBE
Genesis 1 in the EMTV
Genesis 1 in the ESV
Genesis 1 in the FBV
Genesis 1 in the FEB
Genesis 1 in the GGMNT
Genesis 1 in the GNT
Genesis 1 in the HARY
Genesis 1 in the HNT
Genesis 1 in the IRVA
Genesis 1 in the IRVB
Genesis 1 in the IRVG
Genesis 1 in the IRVH
Genesis 1 in the IRVK
Genesis 1 in the IRVM
Genesis 1 in the IRVM2
Genesis 1 in the IRVO
Genesis 1 in the IRVP
Genesis 1 in the IRVT
Genesis 1 in the IRVT2
Genesis 1 in the IRVU
Genesis 1 in the ISVN
Genesis 1 in the JSNT
Genesis 1 in the KAPI
Genesis 1 in the KBT1ETNIK
Genesis 1 in the KBV
Genesis 1 in the KJV
Genesis 1 in the KNFD
Genesis 1 in the LBA
Genesis 1 in the LBLA
Genesis 1 in the LNT
Genesis 1 in the LSV
Genesis 1 in the MAAL
Genesis 1 in the MBV
Genesis 1 in the MBV2
Genesis 1 in the MHNT
Genesis 1 in the MKNFD
Genesis 1 in the MNG
Genesis 1 in the MNT
Genesis 1 in the MNT2
Genesis 1 in the MRS1T
Genesis 1 in the NAA
Genesis 1 in the NASB
Genesis 1 in the NBLA
Genesis 1 in the NBS
Genesis 1 in the NBVTP
Genesis 1 in the NET2
Genesis 1 in the NIV11
Genesis 1 in the NNT
Genesis 1 in the NNT2
Genesis 1 in the NNT3
Genesis 1 in the PDDPT
Genesis 1 in the PFNT
Genesis 1 in the RMNT
Genesis 1 in the SBIAS
Genesis 1 in the SBIBS
Genesis 1 in the SBIBS2
Genesis 1 in the SBICS
Genesis 1 in the SBIDS
Genesis 1 in the SBIGS
Genesis 1 in the SBIHS
Genesis 1 in the SBIIS
Genesis 1 in the SBIIS2
Genesis 1 in the SBIIS3
Genesis 1 in the SBIKS
Genesis 1 in the SBIKS2
Genesis 1 in the SBIMS
Genesis 1 in the SBIOS
Genesis 1 in the SBIPS
Genesis 1 in the SBISS
Genesis 1 in the SBITS
Genesis 1 in the SBITS2
Genesis 1 in the SBITS3
Genesis 1 in the SBITS4
Genesis 1 in the SBIUS
Genesis 1 in the SBIVS
Genesis 1 in the SBT
Genesis 1 in the SBT1E
Genesis 1 in the SCHL
Genesis 1 in the SNT
Genesis 1 in the SUSU
Genesis 1 in the SUSU2
Genesis 1 in the SYNO
Genesis 1 in the TBIAOTANT
Genesis 1 in the TBT1E
Genesis 1 in the TBT1E2
Genesis 1 in the TFTIP
Genesis 1 in the TFTU
Genesis 1 in the TGNTATF3T
Genesis 1 in the THAI
Genesis 1 in the TNFD
Genesis 1 in the TNT
Genesis 1 in the TNTIK
Genesis 1 in the TNTIL
Genesis 1 in the TNTIN
Genesis 1 in the TNTIP
Genesis 1 in the TNTIZ
Genesis 1 in the TOMA
Genesis 1 in the TTENT
Genesis 1 in the UBG
Genesis 1 in the UGV
Genesis 1 in the UGV2
Genesis 1 in the UGV3
Genesis 1 in the VBL
Genesis 1 in the VDCC
Genesis 1 in the YALU
Genesis 1 in the YAPE
Genesis 1 in the YBVTP
Genesis 1 in the ZBP