Genesis 33 (BOYCB)

1 Jakọbu sì gbójú sókè, ó sì rí Esau àti irinwó (400) ọkùnrin tí wọ́n ń bọ̀, ó sì pín àwọn ọmọ fún Lea, Rakeli àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì. 2 Ó sì ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn síwájú, Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọ̀wọ́ kejì tí ó tẹ̀lé wọn, Rakeli àti Josẹfu sì wà lẹ́yìn pátápátá. 3 Jakọbu fúnra rẹ̀ wa lọ síwájú pátápátá, ó sì tẹríba ní ìgbà méje bí ó ti ń súnmọ́ Esau, arákùnrin rẹ̀. 4 Ṣùgbọ́n Esau sáré pàdé Jakọbu, ó sì dì mọ́ ọn, ó rọ̀ mọ́ ọn lọ́rùn, ó sì fẹnukò ó lẹ́nu. Àwọn méjèèjì sì sọkún. 5 Nígbà tí Esau sì ṣe àkíyèsí àwọn ìyàwó àti ọmọ Jakọbu, ó béèrè lọ́wọ́ Jakọbu pé, “Ti ta ni àwọn wọ̀nyí?”Jakọbu sì fèsì wí pé, “Èyí ni àwọn ọmọ tí Ọlọ́run nínú àánú rẹ̀ ti fi fún ìránṣẹ́ rẹ.” 6 Nígbà náà ni àwọn ìránṣẹ́bìnrin àti àwọn ọmọ wọn súnmọ́ tòsí, wọ́n sì tẹríba. 7 Lẹ́yìn náà ni Lea àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú dé, wọ́n sì tún tẹríba. Ní ìkẹyìn ni Josẹfu àti Rakeli dé, wọ́n sì tún tẹríba pẹ̀lú. 8 Esau sì béèrè pé, “Kí ni èrò rẹ tí o fi to àwọn ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ tí mo pàdé wọ̀nyí?”Jakọbu dáhùn pé, “Kí n ba le rí ojúrere rẹ ni olúwa mi.” 9 Ṣùgbọ́n Esau wí pé, “Tèmi ti tó mi, pa èyí tí o ní mọ́ fún ara rẹ.” 10 Jakọbu bẹ̀ ẹ́ wí pé, “Rárá bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ṣe pé, mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ gba ọrẹ lọ́wọ́ mi. Bí mo ṣe rí ojú rẹ̀ yìí, ó dàbí wí pé mo rí ojú Ọlọ́run ni báyìí, tí inú rẹ̀ ti dùn sí mi. 11 Jọ̀wọ́ gba àwọn ohun tí mo mú wá wọ̀nyí lọ́wọ́ mi. Nítorí Ọlọ́run ti fi oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ hàn sí mi, gbogbo ohun tí mo fẹ́ sì ni mo ní.” Nígbà tí Jakọbu sì rọ̀ ọ́ pé Esau gbọdọ̀ gbà wọ́n, Esau sì gbà á. 12 Nígbà náà ni Esau wí pé, “Jẹ́ kí a máa lọ, n ó sìn ọ.” 13 Ṣùgbọ́n Jakọbu wí fún un pé, “Ṣe ìwọ náà ṣe àkíyèsí pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí kéré, àwọn màlúù àti àgùntàn pẹ̀lú sì ní àwọn ọmọ kéékèèké. Bí a bá dà wọ́n rìn jìnnà ju bí agbára wọn ṣe mọ lọ, wọ́n lè kú. 14 Èmi bẹ̀ ọ́, máa lọ síwájú ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ó sì máa rọra bọ̀, títí èmi àti àwọn ọmọ yóò fi dé ọ̀dọ̀ olúwa mi ní Seiri.” 15 Esau wí pé, “Jẹ́ kí n fi díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ nínú àwọn ọkùnrin mi nígbà náà.”Jakọbu wí pé, “Èéṣe, àní kí n sá à rí ojúrere olúwa mi?” 16 Ní ọjọ́ náà gan an ni Esau padà lọ sí Seiri. 17 Jakọbu sì lọ sí Sukkoti, ó sì kọ́ ilé fún ara rẹ̀, ó sì ṣe ọgbà fún àwọn ẹran. Ìdí èyí ní a fi ń pe ibẹ̀ ní Sukkoti. 18 Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu tí Padani-Aramu dé, àlàáfíà ni Jakọbu dé ìlú Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani, ó sì pàgọ́ sí itòsí ìlú náà. 19 Ó sì ra ilẹ̀ kan tí ó pàgọ́ sí ni ọgọ́rùn-ún owó fàdákà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori tí í ṣe baba Ṣekemu. 20 Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan tí ó pè ní El Elohe Israẹli.

In Other Versions

Genesis 33 in the ANGEFD

Genesis 33 in the ANTPNG2D

Genesis 33 in the AS21

Genesis 33 in the BAGH

Genesis 33 in the BBPNG

Genesis 33 in the BBT1E

Genesis 33 in the BDS

Genesis 33 in the BEV

Genesis 33 in the BHAD

Genesis 33 in the BIB

Genesis 33 in the BLPT

Genesis 33 in the BNT

Genesis 33 in the BNTABOOT

Genesis 33 in the BNTLV

Genesis 33 in the BOATCB

Genesis 33 in the BOATCB2

Genesis 33 in the BOBCV

Genesis 33 in the BOCNT

Genesis 33 in the BOECS

Genesis 33 in the BOGWICC

Genesis 33 in the BOHCB

Genesis 33 in the BOHCV

Genesis 33 in the BOHLNT

Genesis 33 in the BOHNTLTAL

Genesis 33 in the BOICB

Genesis 33 in the BOILNTAP

Genesis 33 in the BOITCV

Genesis 33 in the BOKCV

Genesis 33 in the BOKCV2

Genesis 33 in the BOKHWOG

Genesis 33 in the BOKSSV

Genesis 33 in the BOLCB

Genesis 33 in the BOLCB2

Genesis 33 in the BOMCV

Genesis 33 in the BONAV

Genesis 33 in the BONCB

Genesis 33 in the BONLT

Genesis 33 in the BONUT2

Genesis 33 in the BOPLNT

Genesis 33 in the BOSCB

Genesis 33 in the BOSNC

Genesis 33 in the BOTLNT

Genesis 33 in the BOVCB

Genesis 33 in the BPBB

Genesis 33 in the BPH

Genesis 33 in the BSB

Genesis 33 in the CCB

Genesis 33 in the CUV

Genesis 33 in the CUVS

Genesis 33 in the DBT

Genesis 33 in the DGDNT

Genesis 33 in the DHNT

Genesis 33 in the DNT

Genesis 33 in the ELBE

Genesis 33 in the EMTV

Genesis 33 in the ESV

Genesis 33 in the FBV

Genesis 33 in the FEB

Genesis 33 in the GGMNT

Genesis 33 in the GNT

Genesis 33 in the HARY

Genesis 33 in the HNT

Genesis 33 in the IRVA

Genesis 33 in the IRVB

Genesis 33 in the IRVG

Genesis 33 in the IRVH

Genesis 33 in the IRVK

Genesis 33 in the IRVM

Genesis 33 in the IRVM2

Genesis 33 in the IRVO

Genesis 33 in the IRVP

Genesis 33 in the IRVT

Genesis 33 in the IRVT2

Genesis 33 in the IRVU

Genesis 33 in the ISVN

Genesis 33 in the JSNT

Genesis 33 in the KAPI

Genesis 33 in the KBT1ETNIK

Genesis 33 in the KBV

Genesis 33 in the KJV

Genesis 33 in the KNFD

Genesis 33 in the LBA

Genesis 33 in the LBLA

Genesis 33 in the LNT

Genesis 33 in the LSV

Genesis 33 in the MAAL

Genesis 33 in the MBV

Genesis 33 in the MBV2

Genesis 33 in the MHNT

Genesis 33 in the MKNFD

Genesis 33 in the MNG

Genesis 33 in the MNT

Genesis 33 in the MNT2

Genesis 33 in the MRS1T

Genesis 33 in the NAA

Genesis 33 in the NASB

Genesis 33 in the NBLA

Genesis 33 in the NBS

Genesis 33 in the NBVTP

Genesis 33 in the NET2

Genesis 33 in the NIV11

Genesis 33 in the NNT

Genesis 33 in the NNT2

Genesis 33 in the NNT3

Genesis 33 in the PDDPT

Genesis 33 in the PFNT

Genesis 33 in the RMNT

Genesis 33 in the SBIAS

Genesis 33 in the SBIBS

Genesis 33 in the SBIBS2

Genesis 33 in the SBICS

Genesis 33 in the SBIDS

Genesis 33 in the SBIGS

Genesis 33 in the SBIHS

Genesis 33 in the SBIIS

Genesis 33 in the SBIIS2

Genesis 33 in the SBIIS3

Genesis 33 in the SBIKS

Genesis 33 in the SBIKS2

Genesis 33 in the SBIMS

Genesis 33 in the SBIOS

Genesis 33 in the SBIPS

Genesis 33 in the SBISS

Genesis 33 in the SBITS

Genesis 33 in the SBITS2

Genesis 33 in the SBITS3

Genesis 33 in the SBITS4

Genesis 33 in the SBIUS

Genesis 33 in the SBIVS

Genesis 33 in the SBT

Genesis 33 in the SBT1E

Genesis 33 in the SCHL

Genesis 33 in the SNT

Genesis 33 in the SUSU

Genesis 33 in the SUSU2

Genesis 33 in the SYNO

Genesis 33 in the TBIAOTANT

Genesis 33 in the TBT1E

Genesis 33 in the TBT1E2

Genesis 33 in the TFTIP

Genesis 33 in the TFTU

Genesis 33 in the TGNTATF3T

Genesis 33 in the THAI

Genesis 33 in the TNFD

Genesis 33 in the TNT

Genesis 33 in the TNTIK

Genesis 33 in the TNTIL

Genesis 33 in the TNTIN

Genesis 33 in the TNTIP

Genesis 33 in the TNTIZ

Genesis 33 in the TOMA

Genesis 33 in the TTENT

Genesis 33 in the UBG

Genesis 33 in the UGV

Genesis 33 in the UGV2

Genesis 33 in the UGV3

Genesis 33 in the VBL

Genesis 33 in the VDCC

Genesis 33 in the YALU

Genesis 33 in the YAPE

Genesis 33 in the YBVTP

Genesis 33 in the ZBP