Genesis 49 (BOYCB)
1 Nígbà náà ni Jakọbu ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí n le è sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú fún un yín. 2 “Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, kí ẹ sì tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu;ẹ fetí sí Israẹli baba yín. 3 “Reubeni, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ìpilẹ̀ṣẹ̀ ipá mi,títayọ ní ọlá àti títayọ ní agbára. 4 Ẹni ríru bí omi Òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́,nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ,lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́(ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lòpọ̀). 5 “Simeoni àti Lefi jẹ́ arákùnrin—idà wọn jẹ́ ohun èlò ogun alágbára. 6 Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn,kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn,nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn,wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n. 7 Ìfibú ni ìbínú wọn nítorí tí ó gbóná púpọ̀,àti fún ìrunú wọn nítorí tí ó kún fún ìkà!Èmi yóò tú wọn ká ní Jakọbu,èmi ó sì fọ́n wọn ká ní Israẹli. 8 “Juda, àwọn arákùnrin rẹ yóò yìn ọ,ọwọ́ rẹ yóò wà ní ọrùn àwọn ọ̀tá rẹ,àwọn ọmọkùnrin baba rẹ yóò foríbalẹ̀ fún ọ. 9 Ọmọ kìnnìún ni ọ́, ìwọ Juda,o darí láti igbó ọdẹ, ọmọ mi.Bí i kìnnìún, o ba mọ́lẹ̀, o sì sùn sílẹ̀ bí i abo kìnnìún,ta ni ó tó bẹ́ẹ̀, kí o lé e dìde? 10 Ọ̀pá oyè kì yóò kúrò ní Judabẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá-ìṣàkóso kì yóò kúrò láàrín ẹsẹ̀ rẹ̀,títí tí Ṣilo tí ó ni í yóò fi dé,tí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wárí fún un. 11 Yóò má so ọmọ ẹṣin rẹ̀ mọ́ igi àjàrà,àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ mọ́ ẹ̀ka tí ó dára jù.Yóò fọ aṣọ rẹ̀ nínú wáìnìàti ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi-pupa ti èso àjàrà. 12 Ojú rẹ̀ yóò rẹ̀ dòdò ju wáìnì lọ,eyín rẹ yóò sì funfun ju omi-ọyàn lọ. 13 “Sebuluni yóò máa gbé ní etí Òkun,yóò sì jẹ́ èbúté fún ọkọ̀ ojú omi,agbègbè rẹ yóò tàn ká títí dé Sidoni. 14 “Isakari jẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ alágbáratí ó dùbúlẹ̀ láàrín agbo àgùntàn. 15 Nígbà tí ó bá rí bí ibi ìsinmi òun ti dára tó,àti bí ilẹ̀ rẹ̀ ti ní ìdẹ̀ra tó,yóò tẹ èjìká rẹ̀ ba láti ru àjàgà,yóò sì fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ipá. 16 “Dani yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 17 Dani yóò jẹ́ ejò ni pópónààti paramọ́lẹ̀ ní ẹ̀bá ọ̀nà,tí ó bu ẹṣin jẹ ní ẹsẹ̀,kí ẹni tí ń gùn ún bá à le è ṣubú sẹ́yìn. 18 “Mo ń dúró de ìtúsílẹ̀ rẹ, OLÚWA. 19 “Ẹgbẹ́ ogun àwọn ẹlẹ́ṣin yóò kọlu Gadi,ṣùgbọ́n yóò kọlu wọ́n ní gìgísẹ̀ wọn. 20 “Oúnjẹ Aṣeri yóò dára;yóò ṣe àsè tí ó yẹ fún ọba. 21 “Naftali yóò jẹ́ abo àgbọ̀nríntí a tú sílẹ̀ tí ó ń bí ọmọ dáradára. 22 “Josẹfu jẹ́ àjàrà eléso,àjàrà eléso ní etí odò,tí ẹ̀ka rẹ̀ gun orí odi. 23 Pẹ̀lú ìkorò, àwọn tafàtafà dojú ìjà kọ ọ́,wọ́n tafà sí í pẹ̀lú ìkanra. 24 Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára,ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le,nítorí ọwọ́ alágbára Jakọbu,nítorí olùtọ́jú àti aláàbò àpáta Israẹli, 25 nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́,nítorí Olódùmarè tí ó bùkún ọpẹ̀lú láti ọ̀run wá,ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìsàlẹ̀,ìbùkún ti ọmú àti ti inú. 26 Ìbùkún baba rẹ pọ̀ púpọ̀ju ìbùkún àwọn òkè ńlá ìgbàanì,ju ẹ̀bùn ńlá àwọn òkè láéláé.Jẹ́ kí gbogbo èyí sọ̀kalẹ̀ sí orí Josẹfu,lé ìpéǹpéjú ọmọ-aládé láàrín arákùnrin rẹ̀. 27 “Benjamini jẹ́ ìkookò tí ó burú;ní òwúrọ̀ ni ó jẹ ẹran ọdẹ rẹ,ní àṣálẹ́, ó pín ìkógun.” 28 Gbogbo ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá, èyí sì ni ohun tí baba wọn sọ fún wọn nígbà tí ó súre fún wọn, tí ó sì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ìbùkún tí ó tọ́ sí i. 29 Nígbà náà ni ó fún wọn ní àwọn ìlànà yìí, “Ọjọ́ ikú mi kù fẹ́ẹ́rẹ́. Kí ẹ sin mí sí ibojì pẹ̀lú àwọn baba mi ní inú àpáta ní ilẹ̀ Hiti ará Efroni. 30 Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Makpela, nítòsí Mamre ní Kenaani, èyí tí Abrahamu rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Efroni ará Hiti pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀. 31 Níbẹ̀ ni a sin Abrahamu àti aya rẹ̀ Sara sí, níbẹ̀ ni a sin Isaaki àti Rebeka aya rẹ̀ sí, níbẹ̀ sì ni mo sìnkú Lea sí. 32 Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni a rà lọ́wọ́ ará Hiti.” 33 Nígbà tí Jakọbu ti pàṣẹ yìí fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè sórí ibùsùn, ó sì kú, a sì ko jọ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.
In Other Versions
Genesis 49 in the ANGEFD
Genesis 49 in the ANTPNG2D
Genesis 49 in the AS21
Genesis 49 in the BAGH
Genesis 49 in the BBPNG
Genesis 49 in the BBT1E
Genesis 49 in the BDS
Genesis 49 in the BEV
Genesis 49 in the BHAD
Genesis 49 in the BIB
Genesis 49 in the BLPT
Genesis 49 in the BNT
Genesis 49 in the BNTABOOT
Genesis 49 in the BNTLV
Genesis 49 in the BOATCB
Genesis 49 in the BOATCB2
Genesis 49 in the BOBCV
Genesis 49 in the BOCNT
Genesis 49 in the BOECS
Genesis 49 in the BOGWICC
Genesis 49 in the BOHCB
Genesis 49 in the BOHCV
Genesis 49 in the BOHLNT
Genesis 49 in the BOHNTLTAL
Genesis 49 in the BOICB
Genesis 49 in the BOILNTAP
Genesis 49 in the BOITCV
Genesis 49 in the BOKCV
Genesis 49 in the BOKCV2
Genesis 49 in the BOKHWOG
Genesis 49 in the BOKSSV
Genesis 49 in the BOLCB
Genesis 49 in the BOLCB2
Genesis 49 in the BOMCV
Genesis 49 in the BONAV
Genesis 49 in the BONCB
Genesis 49 in the BONLT
Genesis 49 in the BONUT2
Genesis 49 in the BOPLNT
Genesis 49 in the BOSCB
Genesis 49 in the BOSNC
Genesis 49 in the BOTLNT
Genesis 49 in the BOVCB
Genesis 49 in the BPBB
Genesis 49 in the BPH
Genesis 49 in the BSB
Genesis 49 in the CCB
Genesis 49 in the CUV
Genesis 49 in the CUVS
Genesis 49 in the DBT
Genesis 49 in the DGDNT
Genesis 49 in the DHNT
Genesis 49 in the DNT
Genesis 49 in the ELBE
Genesis 49 in the EMTV
Genesis 49 in the ESV
Genesis 49 in the FBV
Genesis 49 in the FEB
Genesis 49 in the GGMNT
Genesis 49 in the GNT
Genesis 49 in the HARY
Genesis 49 in the HNT
Genesis 49 in the IRVA
Genesis 49 in the IRVB
Genesis 49 in the IRVG
Genesis 49 in the IRVH
Genesis 49 in the IRVK
Genesis 49 in the IRVM
Genesis 49 in the IRVM2
Genesis 49 in the IRVO
Genesis 49 in the IRVP
Genesis 49 in the IRVT
Genesis 49 in the IRVT2
Genesis 49 in the IRVU
Genesis 49 in the ISVN
Genesis 49 in the JSNT
Genesis 49 in the KAPI
Genesis 49 in the KBT1ETNIK
Genesis 49 in the KBV
Genesis 49 in the KJV
Genesis 49 in the KNFD
Genesis 49 in the LBA
Genesis 49 in the LBLA
Genesis 49 in the LNT
Genesis 49 in the LSV
Genesis 49 in the MAAL
Genesis 49 in the MBV
Genesis 49 in the MBV2
Genesis 49 in the MHNT
Genesis 49 in the MKNFD
Genesis 49 in the MNG
Genesis 49 in the MNT
Genesis 49 in the MNT2
Genesis 49 in the MRS1T
Genesis 49 in the NAA
Genesis 49 in the NASB
Genesis 49 in the NBLA
Genesis 49 in the NBS
Genesis 49 in the NBVTP
Genesis 49 in the NET2
Genesis 49 in the NIV11
Genesis 49 in the NNT
Genesis 49 in the NNT2
Genesis 49 in the NNT3
Genesis 49 in the PDDPT
Genesis 49 in the PFNT
Genesis 49 in the RMNT
Genesis 49 in the SBIAS
Genesis 49 in the SBIBS
Genesis 49 in the SBIBS2
Genesis 49 in the SBICS
Genesis 49 in the SBIDS
Genesis 49 in the SBIGS
Genesis 49 in the SBIHS
Genesis 49 in the SBIIS
Genesis 49 in the SBIIS2
Genesis 49 in the SBIIS3
Genesis 49 in the SBIKS
Genesis 49 in the SBIKS2
Genesis 49 in the SBIMS
Genesis 49 in the SBIOS
Genesis 49 in the SBIPS
Genesis 49 in the SBISS
Genesis 49 in the SBITS
Genesis 49 in the SBITS2
Genesis 49 in the SBITS3
Genesis 49 in the SBITS4
Genesis 49 in the SBIUS
Genesis 49 in the SBIVS
Genesis 49 in the SBT
Genesis 49 in the SBT1E
Genesis 49 in the SCHL
Genesis 49 in the SNT
Genesis 49 in the SUSU
Genesis 49 in the SUSU2
Genesis 49 in the SYNO
Genesis 49 in the TBIAOTANT
Genesis 49 in the TBT1E
Genesis 49 in the TBT1E2
Genesis 49 in the TFTIP
Genesis 49 in the TFTU
Genesis 49 in the TGNTATF3T
Genesis 49 in the THAI
Genesis 49 in the TNFD
Genesis 49 in the TNT
Genesis 49 in the TNTIK
Genesis 49 in the TNTIL
Genesis 49 in the TNTIN
Genesis 49 in the TNTIP
Genesis 49 in the TNTIZ
Genesis 49 in the TOMA
Genesis 49 in the TTENT
Genesis 49 in the UBG
Genesis 49 in the UGV
Genesis 49 in the UGV2
Genesis 49 in the UGV3
Genesis 49 in the VBL
Genesis 49 in the VDCC
Genesis 49 in the YALU
Genesis 49 in the YAPE
Genesis 49 in the YBVTP
Genesis 49 in the ZBP