Haggai 2 (BOYCB)
1 Ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA wá nípasẹ̀ wòlíì Hagai wí pé, 2 “Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé, 3 ‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín? 4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni OLÚWA wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni OLÚWA wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 5 ‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’ 6 “Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. 7 Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 8 ‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 9 ‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.” 10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ wòlíì Hagai wá pé, 11 “Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé: 12 Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” 13 Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?”Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.” 14 Nígbà náà ni Hagai dáhùn ó sì wí pé, “ ‘Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn wọ̀nyí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni OLÚWA wí. ‘Bẹ́ẹ̀ sì ni olúkúlùkù iṣẹ́ ọwọ́ wọn; èyí tí wọ́n sì fi rú ẹbọ níbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́. 15 “ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili OLÚWA. 16 Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òsùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀. 17 Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni OLÚWA wí. 18 ‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili OLÚWA lélẹ̀, rò ó dáradára. 19 Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan.“ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ” 20 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé, 21 “Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé. 22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run, Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.” 23 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”
In Other Versions
Haggai 2 in the ANGEFD
Haggai 2 in the ANTPNG2D
Haggai 2 in the AS21
Haggai 2 in the BAGH
Haggai 2 in the BBPNG
Haggai 2 in the BBT1E
Haggai 2 in the BDS
Haggai 2 in the BEV
Haggai 2 in the BHAD
Haggai 2 in the BIB
Haggai 2 in the BLPT
Haggai 2 in the BNT
Haggai 2 in the BNTABOOT
Haggai 2 in the BNTLV
Haggai 2 in the BOATCB
Haggai 2 in the BOATCB2
Haggai 2 in the BOBCV
Haggai 2 in the BOCNT
Haggai 2 in the BOECS
Haggai 2 in the BOGWICC
Haggai 2 in the BOHCB
Haggai 2 in the BOHCV
Haggai 2 in the BOHLNT
Haggai 2 in the BOHNTLTAL
Haggai 2 in the BOICB
Haggai 2 in the BOILNTAP
Haggai 2 in the BOITCV
Haggai 2 in the BOKCV
Haggai 2 in the BOKCV2
Haggai 2 in the BOKHWOG
Haggai 2 in the BOKSSV
Haggai 2 in the BOLCB
Haggai 2 in the BOLCB2
Haggai 2 in the BOMCV
Haggai 2 in the BONAV
Haggai 2 in the BONCB
Haggai 2 in the BONLT
Haggai 2 in the BONUT2
Haggai 2 in the BOPLNT
Haggai 2 in the BOSCB
Haggai 2 in the BOSNC
Haggai 2 in the BOTLNT
Haggai 2 in the BOVCB
Haggai 2 in the BPBB
Haggai 2 in the BPH
Haggai 2 in the BSB
Haggai 2 in the CCB
Haggai 2 in the CUV
Haggai 2 in the CUVS
Haggai 2 in the DBT
Haggai 2 in the DGDNT
Haggai 2 in the DHNT
Haggai 2 in the DNT
Haggai 2 in the ELBE
Haggai 2 in the EMTV
Haggai 2 in the ESV
Haggai 2 in the FBV
Haggai 2 in the FEB
Haggai 2 in the GGMNT
Haggai 2 in the GNT
Haggai 2 in the HARY
Haggai 2 in the HNT
Haggai 2 in the IRVA
Haggai 2 in the IRVB
Haggai 2 in the IRVG
Haggai 2 in the IRVH
Haggai 2 in the IRVK
Haggai 2 in the IRVM
Haggai 2 in the IRVM2
Haggai 2 in the IRVO
Haggai 2 in the IRVP
Haggai 2 in the IRVT
Haggai 2 in the IRVT2
Haggai 2 in the IRVU
Haggai 2 in the ISVN
Haggai 2 in the JSNT
Haggai 2 in the KAPI
Haggai 2 in the KBT1ETNIK
Haggai 2 in the KBV
Haggai 2 in the KJV
Haggai 2 in the KNFD
Haggai 2 in the LBA
Haggai 2 in the LBLA
Haggai 2 in the LNT
Haggai 2 in the LSV
Haggai 2 in the MAAL
Haggai 2 in the MBV
Haggai 2 in the MBV2
Haggai 2 in the MHNT
Haggai 2 in the MKNFD
Haggai 2 in the MNG
Haggai 2 in the MNT
Haggai 2 in the MNT2
Haggai 2 in the MRS1T
Haggai 2 in the NAA
Haggai 2 in the NASB
Haggai 2 in the NBLA
Haggai 2 in the NBS
Haggai 2 in the NBVTP
Haggai 2 in the NET2
Haggai 2 in the NIV11
Haggai 2 in the NNT
Haggai 2 in the NNT2
Haggai 2 in the NNT3
Haggai 2 in the PDDPT
Haggai 2 in the PFNT
Haggai 2 in the RMNT
Haggai 2 in the SBIAS
Haggai 2 in the SBIBS
Haggai 2 in the SBIBS2
Haggai 2 in the SBICS
Haggai 2 in the SBIDS
Haggai 2 in the SBIGS
Haggai 2 in the SBIHS
Haggai 2 in the SBIIS
Haggai 2 in the SBIIS2
Haggai 2 in the SBIIS3
Haggai 2 in the SBIKS
Haggai 2 in the SBIKS2
Haggai 2 in the SBIMS
Haggai 2 in the SBIOS
Haggai 2 in the SBIPS
Haggai 2 in the SBISS
Haggai 2 in the SBITS
Haggai 2 in the SBITS2
Haggai 2 in the SBITS3
Haggai 2 in the SBITS4
Haggai 2 in the SBIUS
Haggai 2 in the SBIVS
Haggai 2 in the SBT
Haggai 2 in the SBT1E
Haggai 2 in the SCHL
Haggai 2 in the SNT
Haggai 2 in the SUSU
Haggai 2 in the SUSU2
Haggai 2 in the SYNO
Haggai 2 in the TBIAOTANT
Haggai 2 in the TBT1E
Haggai 2 in the TBT1E2
Haggai 2 in the TFTIP
Haggai 2 in the TFTU
Haggai 2 in the TGNTATF3T
Haggai 2 in the THAI
Haggai 2 in the TNFD
Haggai 2 in the TNT
Haggai 2 in the TNTIK
Haggai 2 in the TNTIL
Haggai 2 in the TNTIN
Haggai 2 in the TNTIP
Haggai 2 in the TNTIZ
Haggai 2 in the TOMA
Haggai 2 in the TTENT
Haggai 2 in the UBG
Haggai 2 in the UGV
Haggai 2 in the UGV2
Haggai 2 in the UGV3
Haggai 2 in the VBL
Haggai 2 in the VDCC
Haggai 2 in the YALU
Haggai 2 in the YAPE
Haggai 2 in the YBVTP
Haggai 2 in the ZBP