Isaiah 41 (BOYCB)

1 “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú mi ẹ̀yin erékùṣù!Jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tún agbára wọn ṣe!Jẹ́ kí wọn wá síwájú kí wọn sọ̀rọ̀,jẹ́ kí a pàdé pọ̀ ní ibi ìdájọ́. 2 “Ta ni ó ti ru ẹnìkan sókè láti ìlà-oòrùn wá,tí ó pè é ní olódodo sí iṣẹ́ tirẹ̀?Ó gbé àwọn orílẹ̀-èdè lé e lọ́wọ́ó sì ṣẹ́gun àwọn ọba níwájú rẹ̀.Ó sọ wọ́n di erùpẹ̀ pẹ̀lú idà rẹ̀,láti kù ú ní ìyàngbò pẹ̀lú ọrun rẹ̀. 3 Ó ń lépa wọn ó sì ń kọjá ní àlàáfíà,ní ojú ọ̀nà tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò rìn rí. 4 Ta ni ó ti ṣe èyí tí ó sì ti jẹ́ kí ó wáyé,tí ó ti pe ìran-ìran láti àtètèkọ́ṣe?Èmi OLÚWA pẹ̀lú ẹni kìn-ín-ní wọnàti ẹni tí ó gbẹ̀yìn, Èmi náà ni.” 5 Àwọn erékùṣù ti rí i wọ́n bẹ̀rù;ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé wárìrì.Wọ́n súnmọ́ tòsí wọ́n sì wá síwájú; 6 èkínní ran èkejì lọ́wọ́ó sì sọ fún arákùnrin rẹ̀ pé, “Jẹ́ alágbára!” 7 Oníṣọ̀nà gba alágbẹ̀dẹ wúrà níyànjú,àti ẹni tí ó fi òòlù dánmú òun lọ́kàn le, àní ẹni tí ó ń lu owú.Ó sọ nípa àjópọ̀ náà pé, “Ó dára.”Ó fi ìṣó kan ère náà mọ́lẹ̀ kí ó má ba à wó lulẹ̀. 8 “Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ Israẹli, ìránṣẹ́ mi,Jakọbu, ẹni tí mo ti yàn,ẹ̀yin ìran Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi, 9 mo mú ọ láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,láti kọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnnà jùlọ ni mo ti pè ọ́.Èmi wí pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi’;Èmi ti yàn ọ́ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì tí ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 10 Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́.Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi. 11 “Gbogbo àwọn tí ó bínú sí ọni ojú yóò tì, tí wọn yóò sì di ẹlẹ́yà;àwọn tó ń bá ọ jàyóò dàbí asán, wọn yóò ṣègbé. 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yóò wá àwọn ọ̀tá rẹ,ìwọ kì yóò rí wọn.Gbogbo àwọn tí ó gbóguntì ọ́yóò dàbí ohun tí kò sí. 13 Nítorí Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ,tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mútí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù;Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. 14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,ìwọ Israẹli kékeré,nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”ni OLÚWA wí,olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò. 16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù.Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú OLÚWAìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli. 17 “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,ṣùgbọ́n kò sí;ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.Ṣùgbọ́n Èmi OLÚWA yóò dá wọn lóhùn;Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gígaàti orísun omi ní àárín àfonífojì.Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi. 19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀ 20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,pé ọwọ́ OLÚWA ni ó ti ṣe èyí,àti pé, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí. 21 “Mú ẹjọ́ wá,” ni OLÚWA wí.“Tẹ́ àwọn àwíjàre rẹ sílẹ̀,” ni ọba Jakọbu wí, 22 “Mú àwọn ère òrìṣà rẹ wọlé láti sọ fún waohun tí yóò ṣẹlẹ̀.Sọ fún wa ohun tí àwọn nǹkan àtijọ́ jẹ́,kí àwa lè ṣe àgbéyẹ̀wò wọnkí àwa sì mọ àbájáde wọn ní ìparí.Tàbí kí o sọ fún wa ohun tí ó ń bọ̀ wá, 23 ẹ sọ fún wa ohun ti ọjọ́ iwájú mú dáníkí àwa kí ó lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín.Ẹ ṣe nǹkan kan, ìbá à ṣe rere tàbí búburú,tó bẹ́ẹ̀ tí àyà yóò fi fò wá tí ẹ̀rù yóò sì fi kún inú wa. 24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yìn ko jásí nǹkan kaniṣẹ́ yín ni kò sì wúlò fún ohunkóhun;ẹni tí ó yàn yín jẹ́ ẹni ìríra. 25 “Èmi ti ru ẹnìkan sókè láti àríwá, òun sì ń bọẹnìkan láti ìlà-oòrùn tí ó pe orúkọ mi.Òun gun àwọn aláṣẹ mọ́lẹ̀ bí ẹni pé odò ni wọ́n,àfi bí ẹni pé amọ̀kòkò nì ti ń gún amọ̀. 26 Ta ni ó sọ èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, tí àwa kò bá fi mọ̀,tàbí ṣáájú àkókò, tí àwa kò bá fi wí pé, ‘Òun sọ òtítọ́’?Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa èyí,ẹnikẹ́ni kò sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀,ẹnikẹ́ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. 27 Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Wò ó, àwọn nìyìí!’Mo fún Jerusalẹmu ní ìránṣẹ́ ìrò ìròyìn ayọ̀ kan. 28 Èmi wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan—kò sí ẹnìkan nínú wọn tí ó lè mú ìmọ̀ràn wá,kò sí ẹnìkan tí ó lè dáhùn nígbà tí mo bi wọ́n. 29 Kíyèsi i, irọ́ ni gbogbo wọn!Gbogbo ìṣe wọn jásí asán;àwọn ère wọn kò ṣé kò yà fún afẹ́fẹ́ àti dàrúdàpọ̀.

In Other Versions

Isaiah 41 in the ANGEFD

Isaiah 41 in the ANTPNG2D

Isaiah 41 in the AS21

Isaiah 41 in the BAGH

Isaiah 41 in the BBPNG

Isaiah 41 in the BBT1E

Isaiah 41 in the BDS

Isaiah 41 in the BEV

Isaiah 41 in the BHAD

Isaiah 41 in the BIB

Isaiah 41 in the BLPT

Isaiah 41 in the BNT

Isaiah 41 in the BNTABOOT

Isaiah 41 in the BNTLV

Isaiah 41 in the BOATCB

Isaiah 41 in the BOATCB2

Isaiah 41 in the BOBCV

Isaiah 41 in the BOCNT

Isaiah 41 in the BOECS

Isaiah 41 in the BOGWICC

Isaiah 41 in the BOHCB

Isaiah 41 in the BOHCV

Isaiah 41 in the BOHLNT

Isaiah 41 in the BOHNTLTAL

Isaiah 41 in the BOICB

Isaiah 41 in the BOILNTAP

Isaiah 41 in the BOITCV

Isaiah 41 in the BOKCV

Isaiah 41 in the BOKCV2

Isaiah 41 in the BOKHWOG

Isaiah 41 in the BOKSSV

Isaiah 41 in the BOLCB

Isaiah 41 in the BOLCB2

Isaiah 41 in the BOMCV

Isaiah 41 in the BONAV

Isaiah 41 in the BONCB

Isaiah 41 in the BONLT

Isaiah 41 in the BONUT2

Isaiah 41 in the BOPLNT

Isaiah 41 in the BOSCB

Isaiah 41 in the BOSNC

Isaiah 41 in the BOTLNT

Isaiah 41 in the BOVCB

Isaiah 41 in the BPBB

Isaiah 41 in the BPH

Isaiah 41 in the BSB

Isaiah 41 in the CCB

Isaiah 41 in the CUV

Isaiah 41 in the CUVS

Isaiah 41 in the DBT

Isaiah 41 in the DGDNT

Isaiah 41 in the DHNT

Isaiah 41 in the DNT

Isaiah 41 in the ELBE

Isaiah 41 in the EMTV

Isaiah 41 in the ESV

Isaiah 41 in the FBV

Isaiah 41 in the FEB

Isaiah 41 in the GGMNT

Isaiah 41 in the GNT

Isaiah 41 in the HARY

Isaiah 41 in the HNT

Isaiah 41 in the IRVA

Isaiah 41 in the IRVB

Isaiah 41 in the IRVG

Isaiah 41 in the IRVH

Isaiah 41 in the IRVK

Isaiah 41 in the IRVM

Isaiah 41 in the IRVM2

Isaiah 41 in the IRVO

Isaiah 41 in the IRVP

Isaiah 41 in the IRVT

Isaiah 41 in the IRVT2

Isaiah 41 in the IRVU

Isaiah 41 in the ISVN

Isaiah 41 in the JSNT

Isaiah 41 in the KAPI

Isaiah 41 in the KBT1ETNIK

Isaiah 41 in the KBV

Isaiah 41 in the KJV

Isaiah 41 in the KNFD

Isaiah 41 in the LBA

Isaiah 41 in the LBLA

Isaiah 41 in the LNT

Isaiah 41 in the LSV

Isaiah 41 in the MAAL

Isaiah 41 in the MBV

Isaiah 41 in the MBV2

Isaiah 41 in the MHNT

Isaiah 41 in the MKNFD

Isaiah 41 in the MNG

Isaiah 41 in the MNT

Isaiah 41 in the MNT2

Isaiah 41 in the MRS1T

Isaiah 41 in the NAA

Isaiah 41 in the NASB

Isaiah 41 in the NBLA

Isaiah 41 in the NBS

Isaiah 41 in the NBVTP

Isaiah 41 in the NET2

Isaiah 41 in the NIV11

Isaiah 41 in the NNT

Isaiah 41 in the NNT2

Isaiah 41 in the NNT3

Isaiah 41 in the PDDPT

Isaiah 41 in the PFNT

Isaiah 41 in the RMNT

Isaiah 41 in the SBIAS

Isaiah 41 in the SBIBS

Isaiah 41 in the SBIBS2

Isaiah 41 in the SBICS

Isaiah 41 in the SBIDS

Isaiah 41 in the SBIGS

Isaiah 41 in the SBIHS

Isaiah 41 in the SBIIS

Isaiah 41 in the SBIIS2

Isaiah 41 in the SBIIS3

Isaiah 41 in the SBIKS

Isaiah 41 in the SBIKS2

Isaiah 41 in the SBIMS

Isaiah 41 in the SBIOS

Isaiah 41 in the SBIPS

Isaiah 41 in the SBISS

Isaiah 41 in the SBITS

Isaiah 41 in the SBITS2

Isaiah 41 in the SBITS3

Isaiah 41 in the SBITS4

Isaiah 41 in the SBIUS

Isaiah 41 in the SBIVS

Isaiah 41 in the SBT

Isaiah 41 in the SBT1E

Isaiah 41 in the SCHL

Isaiah 41 in the SNT

Isaiah 41 in the SUSU

Isaiah 41 in the SUSU2

Isaiah 41 in the SYNO

Isaiah 41 in the TBIAOTANT

Isaiah 41 in the TBT1E

Isaiah 41 in the TBT1E2

Isaiah 41 in the TFTIP

Isaiah 41 in the TFTU

Isaiah 41 in the TGNTATF3T

Isaiah 41 in the THAI

Isaiah 41 in the TNFD

Isaiah 41 in the TNT

Isaiah 41 in the TNTIK

Isaiah 41 in the TNTIL

Isaiah 41 in the TNTIN

Isaiah 41 in the TNTIP

Isaiah 41 in the TNTIZ

Isaiah 41 in the TOMA

Isaiah 41 in the TTENT

Isaiah 41 in the UBG

Isaiah 41 in the UGV

Isaiah 41 in the UGV2

Isaiah 41 in the UGV3

Isaiah 41 in the VBL

Isaiah 41 in the VDCC

Isaiah 41 in the YALU

Isaiah 41 in the YAPE

Isaiah 41 in the YBVTP

Isaiah 41 in the ZBP