Isaiah 8 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi kálàmù ìkọ̀wé lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 2 Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi. 3 Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. OLÚWA sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 4 Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé, ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi,’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.” 5 OLÚWA sì tún sọ fún mi pé, 6 “Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọomi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resiniàti ọmọ Remaliah, 7 ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le,tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn,àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀,yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀,yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀, 8 yóò sì gbá àárín Juda kọjá,yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,ìwọ Emmanueli.” 9 Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú,fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré.Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú! 10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán,ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa. 11 OLÚWA bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé, 12 “Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,má sì ṣe fòyà rẹ̀. 13 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,Òun ni kí o bẹ̀rùÒun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́, 14 Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀àti àpáta tí ó mú wọn ṣubúàti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn. 15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.” 16 Di májẹ̀mú náàkí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi. 17 Èmi yóò dúró de OLÚWA,ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ. 18 Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí OLÚWA fi fún mi. Àwa jẹ́ àmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni. 19 Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè? 20 Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́. 21 Nínú ìnilára àti ebi, ni wọn yóò máa kọjá lọ láàrín ilẹ̀ náà, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni wọn yóò máa kanra, wọn yóò wòkè, wọn yóò sì fi ọba àti Ọlọ́run wọn ré. 22 Nígbà náà ni wọn yóò sì wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúru tí ó ba ni lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.
In Other Versions
Isaiah 8 in the ANGEFD
Isaiah 8 in the ANTPNG2D
Isaiah 8 in the AS21
Isaiah 8 in the BAGH
Isaiah 8 in the BBPNG
Isaiah 8 in the BBT1E
Isaiah 8 in the BDS
Isaiah 8 in the BEV
Isaiah 8 in the BHAD
Isaiah 8 in the BIB
Isaiah 8 in the BLPT
Isaiah 8 in the BNT
Isaiah 8 in the BNTABOOT
Isaiah 8 in the BNTLV
Isaiah 8 in the BOATCB
Isaiah 8 in the BOATCB2
Isaiah 8 in the BOBCV
Isaiah 8 in the BOCNT
Isaiah 8 in the BOECS
Isaiah 8 in the BOGWICC
Isaiah 8 in the BOHCB
Isaiah 8 in the BOHCV
Isaiah 8 in the BOHLNT
Isaiah 8 in the BOHNTLTAL
Isaiah 8 in the BOICB
Isaiah 8 in the BOILNTAP
Isaiah 8 in the BOITCV
Isaiah 8 in the BOKCV
Isaiah 8 in the BOKCV2
Isaiah 8 in the BOKHWOG
Isaiah 8 in the BOKSSV
Isaiah 8 in the BOLCB
Isaiah 8 in the BOLCB2
Isaiah 8 in the BOMCV
Isaiah 8 in the BONAV
Isaiah 8 in the BONCB
Isaiah 8 in the BONLT
Isaiah 8 in the BONUT2
Isaiah 8 in the BOPLNT
Isaiah 8 in the BOSCB
Isaiah 8 in the BOSNC
Isaiah 8 in the BOTLNT
Isaiah 8 in the BOVCB
Isaiah 8 in the BPBB
Isaiah 8 in the BPH
Isaiah 8 in the BSB
Isaiah 8 in the CCB
Isaiah 8 in the CUV
Isaiah 8 in the CUVS
Isaiah 8 in the DBT
Isaiah 8 in the DGDNT
Isaiah 8 in the DHNT
Isaiah 8 in the DNT
Isaiah 8 in the ELBE
Isaiah 8 in the EMTV
Isaiah 8 in the ESV
Isaiah 8 in the FBV
Isaiah 8 in the FEB
Isaiah 8 in the GGMNT
Isaiah 8 in the GNT
Isaiah 8 in the HARY
Isaiah 8 in the HNT
Isaiah 8 in the IRVA
Isaiah 8 in the IRVB
Isaiah 8 in the IRVG
Isaiah 8 in the IRVH
Isaiah 8 in the IRVK
Isaiah 8 in the IRVM
Isaiah 8 in the IRVM2
Isaiah 8 in the IRVO
Isaiah 8 in the IRVP
Isaiah 8 in the IRVT
Isaiah 8 in the IRVT2
Isaiah 8 in the IRVU
Isaiah 8 in the ISVN
Isaiah 8 in the JSNT
Isaiah 8 in the KAPI
Isaiah 8 in the KBT1ETNIK
Isaiah 8 in the KBV
Isaiah 8 in the KJV
Isaiah 8 in the KNFD
Isaiah 8 in the LBA
Isaiah 8 in the LBLA
Isaiah 8 in the LNT
Isaiah 8 in the LSV
Isaiah 8 in the MAAL
Isaiah 8 in the MBV
Isaiah 8 in the MBV2
Isaiah 8 in the MHNT
Isaiah 8 in the MKNFD
Isaiah 8 in the MNG
Isaiah 8 in the MNT
Isaiah 8 in the MNT2
Isaiah 8 in the MRS1T
Isaiah 8 in the NAA
Isaiah 8 in the NASB
Isaiah 8 in the NBLA
Isaiah 8 in the NBS
Isaiah 8 in the NBVTP
Isaiah 8 in the NET2
Isaiah 8 in the NIV11
Isaiah 8 in the NNT
Isaiah 8 in the NNT2
Isaiah 8 in the NNT3
Isaiah 8 in the PDDPT
Isaiah 8 in the PFNT
Isaiah 8 in the RMNT
Isaiah 8 in the SBIAS
Isaiah 8 in the SBIBS
Isaiah 8 in the SBIBS2
Isaiah 8 in the SBICS
Isaiah 8 in the SBIDS
Isaiah 8 in the SBIGS
Isaiah 8 in the SBIHS
Isaiah 8 in the SBIIS
Isaiah 8 in the SBIIS2
Isaiah 8 in the SBIIS3
Isaiah 8 in the SBIKS
Isaiah 8 in the SBIKS2
Isaiah 8 in the SBIMS
Isaiah 8 in the SBIOS
Isaiah 8 in the SBIPS
Isaiah 8 in the SBISS
Isaiah 8 in the SBITS
Isaiah 8 in the SBITS2
Isaiah 8 in the SBITS3
Isaiah 8 in the SBITS4
Isaiah 8 in the SBIUS
Isaiah 8 in the SBIVS
Isaiah 8 in the SBT
Isaiah 8 in the SBT1E
Isaiah 8 in the SCHL
Isaiah 8 in the SNT
Isaiah 8 in the SUSU
Isaiah 8 in the SUSU2
Isaiah 8 in the SYNO
Isaiah 8 in the TBIAOTANT
Isaiah 8 in the TBT1E
Isaiah 8 in the TBT1E2
Isaiah 8 in the TFTIP
Isaiah 8 in the TFTU
Isaiah 8 in the TGNTATF3T
Isaiah 8 in the THAI
Isaiah 8 in the TNFD
Isaiah 8 in the TNT
Isaiah 8 in the TNTIK
Isaiah 8 in the TNTIL
Isaiah 8 in the TNTIN
Isaiah 8 in the TNTIP
Isaiah 8 in the TNTIZ
Isaiah 8 in the TOMA
Isaiah 8 in the TTENT
Isaiah 8 in the UBG
Isaiah 8 in the UGV
Isaiah 8 in the UGV2
Isaiah 8 in the UGV3
Isaiah 8 in the VBL
Isaiah 8 in the VDCC
Isaiah 8 in the YALU
Isaiah 8 in the YAPE
Isaiah 8 in the YBVTP
Isaiah 8 in the ZBP