James 3 (BOYCB)
1 Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù. 2 Nítorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu. 3 Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú. 4 Kíyèsi i, àwọn ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀. 5 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kékeré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóná! 6 Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárín àwọn ẹ̀yà ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà. 7 Nítorí olúkúlùkù ẹ̀dá ẹranko, àti ti ẹyẹ, àti ti ejò, àti ti ohun tí ó ń bẹ ní Òkun, ni à ń tù lójú, tí a sì ti tù lójú láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn wá. 8 Ṣùgbọ́n ahọ́n ni ẹnikẹ́ni kò le tù lójú; ohun búburú aláìgbọ́ràn ni, ó kún fún oró ikú tí í pa ni. 9 Òun ni àwa fi ń yin Olúwa àti Baba, òun ni a sì fi ń bú ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run. 10 Láti ẹnu kan náà ni ìyìn àti èébú ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, nǹkan wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. 11 Orísun odò kan a ha máa sun omi dídára àti omi iyọ̀ jáde láti orísun kan náà bí? 12 Ẹ̀yin ará mi, igi ọ̀pọ̀tọ́ ha le so èso olifi bí? Tàbí àjàrà ha lè so èso ọ̀pọ̀tọ́? Bẹ́ẹ̀ ni orísun kan kò le sun omíró àti omi tútù. 13 Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. 14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́. 15 Ọgbọ́n yìí kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ṣùgbọ́n ti ayé ni, ti ara ni, ti ẹ̀mí èṣù ni. 16 Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà. 17 Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́. 18 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.
In Other Versions
James 3 in the ANGEFD
James 3 in the ANTPNG2D
James 3 in the AS21
James 3 in the BAGH
James 3 in the BBPNG
James 3 in the BBT1E
James 3 in the BDS
James 3 in the BEV
James 3 in the BHAD
James 3 in the BIB
James 3 in the BLPT
James 3 in the BNT
James 3 in the BNTABOOT
James 3 in the BNTLV
James 3 in the BOATCB
James 3 in the BOATCB2
James 3 in the BOBCV
James 3 in the BOCNT
James 3 in the BOECS
James 3 in the BOGWICC
James 3 in the BOHCB
James 3 in the BOHCV
James 3 in the BOHLNT
James 3 in the BOHNTLTAL
James 3 in the BOICB
James 3 in the BOILNTAP
James 3 in the BOITCV
James 3 in the BOKCV
James 3 in the BOKCV2
James 3 in the BOKHWOG
James 3 in the BOKSSV
James 3 in the BOLCB
James 3 in the BOLCB2
James 3 in the BOMCV
James 3 in the BONAV
James 3 in the BONCB
James 3 in the BONLT
James 3 in the BONUT2
James 3 in the BOPLNT
James 3 in the BOSCB
James 3 in the BOSNC
James 3 in the BOTLNT
James 3 in the BOVCB
James 3 in the BPBB
James 3 in the BPH
James 3 in the BSB
James 3 in the CCB
James 3 in the CUV
James 3 in the CUVS
James 3 in the DBT
James 3 in the DGDNT
James 3 in the DHNT
James 3 in the DNT
James 3 in the ELBE
James 3 in the EMTV
James 3 in the ESV
James 3 in the FBV
James 3 in the FEB
James 3 in the GGMNT
James 3 in the GNT
James 3 in the HARY
James 3 in the HNT
James 3 in the IRVA
James 3 in the IRVB
James 3 in the IRVG
James 3 in the IRVH
James 3 in the IRVK
James 3 in the IRVM
James 3 in the IRVM2
James 3 in the IRVO
James 3 in the IRVP
James 3 in the IRVT
James 3 in the IRVT2
James 3 in the IRVU
James 3 in the ISVN
James 3 in the JSNT
James 3 in the KAPI
James 3 in the KBT1ETNIK
James 3 in the KBV
James 3 in the KJV
James 3 in the KNFD
James 3 in the LBA
James 3 in the LBLA
James 3 in the LNT
James 3 in the LSV
James 3 in the MAAL
James 3 in the MBV
James 3 in the MBV2
James 3 in the MHNT
James 3 in the MKNFD
James 3 in the MNG
James 3 in the MNT
James 3 in the MNT2
James 3 in the MRS1T
James 3 in the NAA
James 3 in the NASB
James 3 in the NBLA
James 3 in the NBS
James 3 in the NBVTP
James 3 in the NET2
James 3 in the NIV11
James 3 in the NNT
James 3 in the NNT2
James 3 in the NNT3
James 3 in the PDDPT
James 3 in the PFNT
James 3 in the RMNT
James 3 in the SBIAS
James 3 in the SBIBS
James 3 in the SBIBS2
James 3 in the SBICS
James 3 in the SBIDS
James 3 in the SBIGS
James 3 in the SBIHS
James 3 in the SBIIS
James 3 in the SBIIS2
James 3 in the SBIIS3
James 3 in the SBIKS
James 3 in the SBIKS2
James 3 in the SBIMS
James 3 in the SBIOS
James 3 in the SBIPS
James 3 in the SBISS
James 3 in the SBITS
James 3 in the SBITS2
James 3 in the SBITS3
James 3 in the SBITS4
James 3 in the SBIUS
James 3 in the SBIVS
James 3 in the SBT
James 3 in the SBT1E
James 3 in the SCHL
James 3 in the SNT
James 3 in the SUSU
James 3 in the SUSU2
James 3 in the SYNO
James 3 in the TBIAOTANT
James 3 in the TBT1E
James 3 in the TBT1E2
James 3 in the TFTIP
James 3 in the TFTU
James 3 in the TGNTATF3T
James 3 in the THAI
James 3 in the TNFD
James 3 in the TNT
James 3 in the TNTIK
James 3 in the TNTIL
James 3 in the TNTIN
James 3 in the TNTIP
James 3 in the TNTIZ
James 3 in the TOMA
James 3 in the TTENT
James 3 in the UBG
James 3 in the UGV
James 3 in the UGV2
James 3 in the UGV3
James 3 in the VBL
James 3 in the VDCC
James 3 in the YALU
James 3 in the YAPE
James 3 in the YBVTP
James 3 in the ZBP