James 4 (BOYCB)
1 Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? 2 Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní, ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. 3 Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín. 4 Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. 5 Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé Mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? 6 Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé,“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.” 7 Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. 8 Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. 9 Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga. 11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́? 13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni. 17 Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.
In Other Versions
James 4 in the ANGEFD
James 4 in the ANTPNG2D
James 4 in the AS21
James 4 in the BAGH
James 4 in the BBPNG
James 4 in the BBT1E
James 4 in the BDS
James 4 in the BEV
James 4 in the BHAD
James 4 in the BIB
James 4 in the BLPT
James 4 in the BNT
James 4 in the BNTABOOT
James 4 in the BNTLV
James 4 in the BOATCB
James 4 in the BOATCB2
James 4 in the BOBCV
James 4 in the BOCNT
James 4 in the BOECS
James 4 in the BOGWICC
James 4 in the BOHCB
James 4 in the BOHCV
James 4 in the BOHLNT
James 4 in the BOHNTLTAL
James 4 in the BOICB
James 4 in the BOILNTAP
James 4 in the BOITCV
James 4 in the BOKCV
James 4 in the BOKCV2
James 4 in the BOKHWOG
James 4 in the BOKSSV
James 4 in the BOLCB
James 4 in the BOLCB2
James 4 in the BOMCV
James 4 in the BONAV
James 4 in the BONCB
James 4 in the BONLT
James 4 in the BONUT2
James 4 in the BOPLNT
James 4 in the BOSCB
James 4 in the BOSNC
James 4 in the BOTLNT
James 4 in the BOVCB
James 4 in the BPBB
James 4 in the BPH
James 4 in the BSB
James 4 in the CCB
James 4 in the CUV
James 4 in the CUVS
James 4 in the DBT
James 4 in the DGDNT
James 4 in the DHNT
James 4 in the DNT
James 4 in the ELBE
James 4 in the EMTV
James 4 in the ESV
James 4 in the FBV
James 4 in the FEB
James 4 in the GGMNT
James 4 in the GNT
James 4 in the HARY
James 4 in the HNT
James 4 in the IRVA
James 4 in the IRVB
James 4 in the IRVG
James 4 in the IRVH
James 4 in the IRVK
James 4 in the IRVM
James 4 in the IRVM2
James 4 in the IRVO
James 4 in the IRVP
James 4 in the IRVT
James 4 in the IRVT2
James 4 in the IRVU
James 4 in the ISVN
James 4 in the JSNT
James 4 in the KAPI
James 4 in the KBT1ETNIK
James 4 in the KBV
James 4 in the KJV
James 4 in the KNFD
James 4 in the LBA
James 4 in the LBLA
James 4 in the LNT
James 4 in the LSV
James 4 in the MAAL
James 4 in the MBV
James 4 in the MBV2
James 4 in the MHNT
James 4 in the MKNFD
James 4 in the MNG
James 4 in the MNT
James 4 in the MNT2
James 4 in the MRS1T
James 4 in the NAA
James 4 in the NASB
James 4 in the NBLA
James 4 in the NBS
James 4 in the NBVTP
James 4 in the NET2
James 4 in the NIV11
James 4 in the NNT
James 4 in the NNT2
James 4 in the NNT3
James 4 in the PDDPT
James 4 in the PFNT
James 4 in the RMNT
James 4 in the SBIAS
James 4 in the SBIBS
James 4 in the SBIBS2
James 4 in the SBICS
James 4 in the SBIDS
James 4 in the SBIGS
James 4 in the SBIHS
James 4 in the SBIIS
James 4 in the SBIIS2
James 4 in the SBIIS3
James 4 in the SBIKS
James 4 in the SBIKS2
James 4 in the SBIMS
James 4 in the SBIOS
James 4 in the SBIPS
James 4 in the SBISS
James 4 in the SBITS
James 4 in the SBITS2
James 4 in the SBITS3
James 4 in the SBITS4
James 4 in the SBIUS
James 4 in the SBIVS
James 4 in the SBT
James 4 in the SBT1E
James 4 in the SCHL
James 4 in the SNT
James 4 in the SUSU
James 4 in the SUSU2
James 4 in the SYNO
James 4 in the TBIAOTANT
James 4 in the TBT1E
James 4 in the TBT1E2
James 4 in the TFTIP
James 4 in the TFTU
James 4 in the TGNTATF3T
James 4 in the THAI
James 4 in the TNFD
James 4 in the TNT
James 4 in the TNTIK
James 4 in the TNTIL
James 4 in the TNTIN
James 4 in the TNTIP
James 4 in the TNTIZ
James 4 in the TOMA
James 4 in the TTENT
James 4 in the UBG
James 4 in the UGV
James 4 in the UGV2
James 4 in the UGV3
James 4 in the VBL
James 4 in the VDCC
James 4 in the YALU
James 4 in the YAPE
James 4 in the YBVTP
James 4 in the ZBP