James 5 (BOYCB)
1 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. 2 Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. 3 Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. 4 Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 5 Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. 6 Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín. 7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò. 8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. 9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn. 10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù. 11 Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú. 12 Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi. 13 Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́. 14 Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa. 15 Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í. 16 Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀. 17 Ènìyàn bí àwa ni Elijah, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà. 18 Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde. 19 Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà; 20 jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
In Other Versions
James 5 in the ANGEFD
James 5 in the ANTPNG2D
James 5 in the AS21
James 5 in the BAGH
James 5 in the BBPNG
James 5 in the BBT1E
James 5 in the BDS
James 5 in the BEV
James 5 in the BHAD
James 5 in the BIB
James 5 in the BLPT
James 5 in the BNT
James 5 in the BNTABOOT
James 5 in the BNTLV
James 5 in the BOATCB
James 5 in the BOATCB2
James 5 in the BOBCV
James 5 in the BOCNT
James 5 in the BOECS
James 5 in the BOGWICC
James 5 in the BOHCB
James 5 in the BOHCV
James 5 in the BOHLNT
James 5 in the BOHNTLTAL
James 5 in the BOICB
James 5 in the BOILNTAP
James 5 in the BOITCV
James 5 in the BOKCV
James 5 in the BOKCV2
James 5 in the BOKHWOG
James 5 in the BOKSSV
James 5 in the BOLCB
James 5 in the BOLCB2
James 5 in the BOMCV
James 5 in the BONAV
James 5 in the BONCB
James 5 in the BONLT
James 5 in the BONUT2
James 5 in the BOPLNT
James 5 in the BOSCB
James 5 in the BOSNC
James 5 in the BOTLNT
James 5 in the BOVCB
James 5 in the BPBB
James 5 in the BPH
James 5 in the BSB
James 5 in the CCB
James 5 in the CUV
James 5 in the CUVS
James 5 in the DBT
James 5 in the DGDNT
James 5 in the DHNT
James 5 in the DNT
James 5 in the ELBE
James 5 in the EMTV
James 5 in the ESV
James 5 in the FBV
James 5 in the FEB
James 5 in the GGMNT
James 5 in the GNT
James 5 in the HARY
James 5 in the HNT
James 5 in the IRVA
James 5 in the IRVB
James 5 in the IRVG
James 5 in the IRVH
James 5 in the IRVK
James 5 in the IRVM
James 5 in the IRVM2
James 5 in the IRVO
James 5 in the IRVP
James 5 in the IRVT
James 5 in the IRVT2
James 5 in the IRVU
James 5 in the ISVN
James 5 in the JSNT
James 5 in the KAPI
James 5 in the KBT1ETNIK
James 5 in the KBV
James 5 in the KJV
James 5 in the KNFD
James 5 in the LBA
James 5 in the LBLA
James 5 in the LNT
James 5 in the LSV
James 5 in the MAAL
James 5 in the MBV
James 5 in the MBV2
James 5 in the MHNT
James 5 in the MKNFD
James 5 in the MNG
James 5 in the MNT
James 5 in the MNT2
James 5 in the MRS1T
James 5 in the NAA
James 5 in the NASB
James 5 in the NBLA
James 5 in the NBS
James 5 in the NBVTP
James 5 in the NET2
James 5 in the NIV11
James 5 in the NNT
James 5 in the NNT2
James 5 in the NNT3
James 5 in the PDDPT
James 5 in the PFNT
James 5 in the RMNT
James 5 in the SBIAS
James 5 in the SBIBS
James 5 in the SBIBS2
James 5 in the SBICS
James 5 in the SBIDS
James 5 in the SBIGS
James 5 in the SBIHS
James 5 in the SBIIS
James 5 in the SBIIS2
James 5 in the SBIIS3
James 5 in the SBIKS
James 5 in the SBIKS2
James 5 in the SBIMS
James 5 in the SBIOS
James 5 in the SBIPS
James 5 in the SBISS
James 5 in the SBITS
James 5 in the SBITS2
James 5 in the SBITS3
James 5 in the SBITS4
James 5 in the SBIUS
James 5 in the SBIVS
James 5 in the SBT
James 5 in the SBT1E
James 5 in the SCHL
James 5 in the SNT
James 5 in the SUSU
James 5 in the SUSU2
James 5 in the SYNO
James 5 in the TBIAOTANT
James 5 in the TBT1E
James 5 in the TBT1E2
James 5 in the TFTIP
James 5 in the TFTU
James 5 in the TGNTATF3T
James 5 in the THAI
James 5 in the TNFD
James 5 in the TNT
James 5 in the TNTIK
James 5 in the TNTIL
James 5 in the TNTIN
James 5 in the TNTIP
James 5 in the TNTIZ
James 5 in the TOMA
James 5 in the TTENT
James 5 in the UBG
James 5 in the UGV
James 5 in the UGV2
James 5 in the UGV3
James 5 in the VBL
James 5 in the VDCC
James 5 in the YALU
James 5 in the YAPE
James 5 in the YBVTP
James 5 in the ZBP