Judges 15 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè alikama, Samsoni mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láààyè láti wọlé. 2 Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣe bí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jùlọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.” 3 Samsoni dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Filistini ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.” 4 Samsoni sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjì méjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀. 5 Ó fi iná ran àwọn ètùfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Filistini. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn ọgbà àjàrà àti olifi. 6 Nígbà tí àwọn Filistini béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ará Timna ni, nítorí a gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”Nítorí náà àwọn Filistini lọ wọ́n sì sun obìnrin náà àti baba rẹ̀. 7 Samsoni sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi ó gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà èmi yóò sì dẹ́kun.” 8 Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu. 9 Àwọn ará Filistini sì dìde ogun sí Juda, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbègbè Lehi. 10 Àwọn ọkùnrin Juda sì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbóguntì wá?”Ìdáhùn wọn ni pé, “A wá láti mú Samsoni ní ìgbèkùn, kí a ṣe sí i bí òun ti ṣe sí wa.” 11 Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Etamu, wọ́n sì sọ fún Samsoni pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Filistini ní ń ṣe alákòóso lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?”Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.” 12 Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Filistini lọ́wọ́.”Samsoni wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.” 13 “Àwa gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, àwa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn tuntun méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà. 14 Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. 15 Nígbà tí ó rí egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tuntun kan, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin. 16 Samsoni sì wí pé,“Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan,mo sọ wọ́n di òkìtì kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.Pẹ̀lú egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan,mo ti pa ẹgbẹ̀rún (1,000) ọkùnrin.” 17 Nígbà tí ó dákẹ́ ọ̀rọ̀ í sọ, ó ju egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ náà nù, wọ́n sì pe ibẹ̀ ní Ramati-Lehi (ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́ egungun àgbọ̀n ìsàlẹ̀ pa). 18 Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe OLÚWA, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?” 19 Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìsun omi tí ó wà ní Lehi, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Samsoni mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìsun omi náà ni. Ẹni Hakkore (orísun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Lehi di òní. 20 Samsoni ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Filistini.
In Other Versions
Judges 15 in the ANGEFD
Judges 15 in the ANTPNG2D
Judges 15 in the AS21
Judges 15 in the BAGH
Judges 15 in the BBPNG
Judges 15 in the BBT1E
Judges 15 in the BDS
Judges 15 in the BEV
Judges 15 in the BHAD
Judges 15 in the BIB
Judges 15 in the BLPT
Judges 15 in the BNT
Judges 15 in the BNTABOOT
Judges 15 in the BNTLV
Judges 15 in the BOATCB
Judges 15 in the BOATCB2
Judges 15 in the BOBCV
Judges 15 in the BOCNT
Judges 15 in the BOECS
Judges 15 in the BOGWICC
Judges 15 in the BOHCB
Judges 15 in the BOHCV
Judges 15 in the BOHLNT
Judges 15 in the BOHNTLTAL
Judges 15 in the BOICB
Judges 15 in the BOILNTAP
Judges 15 in the BOITCV
Judges 15 in the BOKCV
Judges 15 in the BOKCV2
Judges 15 in the BOKHWOG
Judges 15 in the BOKSSV
Judges 15 in the BOLCB
Judges 15 in the BOLCB2
Judges 15 in the BOMCV
Judges 15 in the BONAV
Judges 15 in the BONCB
Judges 15 in the BONLT
Judges 15 in the BONUT2
Judges 15 in the BOPLNT
Judges 15 in the BOSCB
Judges 15 in the BOSNC
Judges 15 in the BOTLNT
Judges 15 in the BOVCB
Judges 15 in the BPBB
Judges 15 in the BPH
Judges 15 in the BSB
Judges 15 in the CCB
Judges 15 in the CUV
Judges 15 in the CUVS
Judges 15 in the DBT
Judges 15 in the DGDNT
Judges 15 in the DHNT
Judges 15 in the DNT
Judges 15 in the ELBE
Judges 15 in the EMTV
Judges 15 in the ESV
Judges 15 in the FBV
Judges 15 in the FEB
Judges 15 in the GGMNT
Judges 15 in the GNT
Judges 15 in the HARY
Judges 15 in the HNT
Judges 15 in the IRVA
Judges 15 in the IRVB
Judges 15 in the IRVG
Judges 15 in the IRVH
Judges 15 in the IRVK
Judges 15 in the IRVM
Judges 15 in the IRVM2
Judges 15 in the IRVO
Judges 15 in the IRVP
Judges 15 in the IRVT
Judges 15 in the IRVT2
Judges 15 in the IRVU
Judges 15 in the ISVN
Judges 15 in the JSNT
Judges 15 in the KAPI
Judges 15 in the KBT1ETNIK
Judges 15 in the KBV
Judges 15 in the KJV
Judges 15 in the KNFD
Judges 15 in the LBA
Judges 15 in the LBLA
Judges 15 in the LNT
Judges 15 in the LSV
Judges 15 in the MAAL
Judges 15 in the MBV
Judges 15 in the MBV2
Judges 15 in the MHNT
Judges 15 in the MKNFD
Judges 15 in the MNG
Judges 15 in the MNT
Judges 15 in the MNT2
Judges 15 in the MRS1T
Judges 15 in the NAA
Judges 15 in the NASB
Judges 15 in the NBLA
Judges 15 in the NBS
Judges 15 in the NBVTP
Judges 15 in the NET2
Judges 15 in the NIV11
Judges 15 in the NNT
Judges 15 in the NNT2
Judges 15 in the NNT3
Judges 15 in the PDDPT
Judges 15 in the PFNT
Judges 15 in the RMNT
Judges 15 in the SBIAS
Judges 15 in the SBIBS
Judges 15 in the SBIBS2
Judges 15 in the SBICS
Judges 15 in the SBIDS
Judges 15 in the SBIGS
Judges 15 in the SBIHS
Judges 15 in the SBIIS
Judges 15 in the SBIIS2
Judges 15 in the SBIIS3
Judges 15 in the SBIKS
Judges 15 in the SBIKS2
Judges 15 in the SBIMS
Judges 15 in the SBIOS
Judges 15 in the SBIPS
Judges 15 in the SBISS
Judges 15 in the SBITS
Judges 15 in the SBITS2
Judges 15 in the SBITS3
Judges 15 in the SBITS4
Judges 15 in the SBIUS
Judges 15 in the SBIVS
Judges 15 in the SBT
Judges 15 in the SBT1E
Judges 15 in the SCHL
Judges 15 in the SNT
Judges 15 in the SUSU
Judges 15 in the SUSU2
Judges 15 in the SYNO
Judges 15 in the TBIAOTANT
Judges 15 in the TBT1E
Judges 15 in the TBT1E2
Judges 15 in the TFTIP
Judges 15 in the TFTU
Judges 15 in the TGNTATF3T
Judges 15 in the THAI
Judges 15 in the TNFD
Judges 15 in the TNT
Judges 15 in the TNTIK
Judges 15 in the TNTIL
Judges 15 in the TNTIN
Judges 15 in the TNTIP
Judges 15 in the TNTIZ
Judges 15 in the TOMA
Judges 15 in the TTENT
Judges 15 in the UBG
Judges 15 in the UGV
Judges 15 in the UGV2
Judges 15 in the UGV3
Judges 15 in the VBL
Judges 15 in the VDCC
Judges 15 in the YALU
Judges 15 in the YAPE
Judges 15 in the YBVTP
Judges 15 in the ZBP