Jeremiah 1 (BOYCB)
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. 2 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, 3 àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn. 4 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá, wí pé, 5 “Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” 6 Mo sọ pé, “Háà! OLÚWA Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.” 7 OLÚWA sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” 8 OLÚWA sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́. 9 OLÚWA sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ. 10 Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn. 11 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ mí wá wí pé: “Kí ni o rí Jeremiah?”Mo sì dáhùn wí pé, “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.” 12 OLÚWA sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.” 13 Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?”Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá. 14 OLÚWA sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15 Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni OLÚWA wí.“Àwọn ọba wọn yóò wá gbé ìtẹ́ wọn róní ojú ọ̀nà àbáwọlé Jerusalẹmu.Wọn ó sì dìde sí gbogbo àyíká wọnàti sí gbogbo àwọn ìlú Juda. 16 Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn minítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìírànàti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. 17 “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18 Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19 Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni OLÚWA wí.
In Other Versions
Jeremiah 1 in the ANGEFD
Jeremiah 1 in the ANTPNG2D
Jeremiah 1 in the AS21
Jeremiah 1 in the BAGH
Jeremiah 1 in the BBPNG
Jeremiah 1 in the BBT1E
Jeremiah 1 in the BDS
Jeremiah 1 in the BEV
Jeremiah 1 in the BHAD
Jeremiah 1 in the BIB
Jeremiah 1 in the BLPT
Jeremiah 1 in the BNT
Jeremiah 1 in the BNTABOOT
Jeremiah 1 in the BNTLV
Jeremiah 1 in the BOATCB
Jeremiah 1 in the BOATCB2
Jeremiah 1 in the BOBCV
Jeremiah 1 in the BOCNT
Jeremiah 1 in the BOECS
Jeremiah 1 in the BOGWICC
Jeremiah 1 in the BOHCB
Jeremiah 1 in the BOHCV
Jeremiah 1 in the BOHLNT
Jeremiah 1 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 1 in the BOICB
Jeremiah 1 in the BOILNTAP
Jeremiah 1 in the BOITCV
Jeremiah 1 in the BOKCV
Jeremiah 1 in the BOKCV2
Jeremiah 1 in the BOKHWOG
Jeremiah 1 in the BOKSSV
Jeremiah 1 in the BOLCB
Jeremiah 1 in the BOLCB2
Jeremiah 1 in the BOMCV
Jeremiah 1 in the BONAV
Jeremiah 1 in the BONCB
Jeremiah 1 in the BONLT
Jeremiah 1 in the BONUT2
Jeremiah 1 in the BOPLNT
Jeremiah 1 in the BOSCB
Jeremiah 1 in the BOSNC
Jeremiah 1 in the BOTLNT
Jeremiah 1 in the BOVCB
Jeremiah 1 in the BPBB
Jeremiah 1 in the BPH
Jeremiah 1 in the BSB
Jeremiah 1 in the CCB
Jeremiah 1 in the CUV
Jeremiah 1 in the CUVS
Jeremiah 1 in the DBT
Jeremiah 1 in the DGDNT
Jeremiah 1 in the DHNT
Jeremiah 1 in the DNT
Jeremiah 1 in the ELBE
Jeremiah 1 in the EMTV
Jeremiah 1 in the ESV
Jeremiah 1 in the FBV
Jeremiah 1 in the FEB
Jeremiah 1 in the GGMNT
Jeremiah 1 in the GNT
Jeremiah 1 in the HARY
Jeremiah 1 in the HNT
Jeremiah 1 in the IRVA
Jeremiah 1 in the IRVB
Jeremiah 1 in the IRVG
Jeremiah 1 in the IRVH
Jeremiah 1 in the IRVK
Jeremiah 1 in the IRVM
Jeremiah 1 in the IRVM2
Jeremiah 1 in the IRVO
Jeremiah 1 in the IRVP
Jeremiah 1 in the IRVT
Jeremiah 1 in the IRVT2
Jeremiah 1 in the IRVU
Jeremiah 1 in the ISVN
Jeremiah 1 in the JSNT
Jeremiah 1 in the KAPI
Jeremiah 1 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 1 in the KBV
Jeremiah 1 in the KJV
Jeremiah 1 in the KNFD
Jeremiah 1 in the LBA
Jeremiah 1 in the LBLA
Jeremiah 1 in the LNT
Jeremiah 1 in the LSV
Jeremiah 1 in the MAAL
Jeremiah 1 in the MBV
Jeremiah 1 in the MBV2
Jeremiah 1 in the MHNT
Jeremiah 1 in the MKNFD
Jeremiah 1 in the MNG
Jeremiah 1 in the MNT
Jeremiah 1 in the MNT2
Jeremiah 1 in the MRS1T
Jeremiah 1 in the NAA
Jeremiah 1 in the NASB
Jeremiah 1 in the NBLA
Jeremiah 1 in the NBS
Jeremiah 1 in the NBVTP
Jeremiah 1 in the NET2
Jeremiah 1 in the NIV11
Jeremiah 1 in the NNT
Jeremiah 1 in the NNT2
Jeremiah 1 in the NNT3
Jeremiah 1 in the PDDPT
Jeremiah 1 in the PFNT
Jeremiah 1 in the RMNT
Jeremiah 1 in the SBIAS
Jeremiah 1 in the SBIBS
Jeremiah 1 in the SBIBS2
Jeremiah 1 in the SBICS
Jeremiah 1 in the SBIDS
Jeremiah 1 in the SBIGS
Jeremiah 1 in the SBIHS
Jeremiah 1 in the SBIIS
Jeremiah 1 in the SBIIS2
Jeremiah 1 in the SBIIS3
Jeremiah 1 in the SBIKS
Jeremiah 1 in the SBIKS2
Jeremiah 1 in the SBIMS
Jeremiah 1 in the SBIOS
Jeremiah 1 in the SBIPS
Jeremiah 1 in the SBISS
Jeremiah 1 in the SBITS
Jeremiah 1 in the SBITS2
Jeremiah 1 in the SBITS3
Jeremiah 1 in the SBITS4
Jeremiah 1 in the SBIUS
Jeremiah 1 in the SBIVS
Jeremiah 1 in the SBT
Jeremiah 1 in the SBT1E
Jeremiah 1 in the SCHL
Jeremiah 1 in the SNT
Jeremiah 1 in the SUSU
Jeremiah 1 in the SUSU2
Jeremiah 1 in the SYNO
Jeremiah 1 in the TBIAOTANT
Jeremiah 1 in the TBT1E
Jeremiah 1 in the TBT1E2
Jeremiah 1 in the TFTIP
Jeremiah 1 in the TFTU
Jeremiah 1 in the TGNTATF3T
Jeremiah 1 in the THAI
Jeremiah 1 in the TNFD
Jeremiah 1 in the TNT
Jeremiah 1 in the TNTIK
Jeremiah 1 in the TNTIL
Jeremiah 1 in the TNTIN
Jeremiah 1 in the TNTIP
Jeremiah 1 in the TNTIZ
Jeremiah 1 in the TOMA
Jeremiah 1 in the TTENT
Jeremiah 1 in the UBG
Jeremiah 1 in the UGV
Jeremiah 1 in the UGV2
Jeremiah 1 in the UGV3
Jeremiah 1 in the VBL
Jeremiah 1 in the VDCC
Jeremiah 1 in the YALU
Jeremiah 1 in the YAPE
Jeremiah 1 in the YBVTP
Jeremiah 1 in the ZBP