Jeremiah 18 (BOYCB)
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: 2 “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. 4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀. 5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá pé: 6 “Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni OLÚWA wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun, 8 tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn. 11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní OLÚWA wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ” 13 Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí:“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe. 14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoniyóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí? 15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,àti ọ̀nà wọn àtijọ́.Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe. 16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì dinǹkan ẹ̀gàn títí láé,gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,wọn yóò sì mi orí wọn. 17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọnní ọjọ́ àjálù wọn.” 18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.” 19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi OLÚWA,gbọ́ ohun tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ. 20 Ṣe kí a fi rere san búburú?Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi.Rántí pé mo dúró níwájú rẹ,mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn,láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọnjọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idàjẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opójẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọnkí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrinwọn lójú ogun. 22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọnnígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagunkọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi. 23 Ṣùgbọ́n ìwọ OLÚWA mọgbogbo ète wọn láti pa mí,má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́nbẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.
In Other Versions
Jeremiah 18 in the ANGEFD
Jeremiah 18 in the ANTPNG2D
Jeremiah 18 in the AS21
Jeremiah 18 in the BAGH
Jeremiah 18 in the BBPNG
Jeremiah 18 in the BBT1E
Jeremiah 18 in the BDS
Jeremiah 18 in the BEV
Jeremiah 18 in the BHAD
Jeremiah 18 in the BIB
Jeremiah 18 in the BLPT
Jeremiah 18 in the BNT
Jeremiah 18 in the BNTABOOT
Jeremiah 18 in the BNTLV
Jeremiah 18 in the BOATCB
Jeremiah 18 in the BOATCB2
Jeremiah 18 in the BOBCV
Jeremiah 18 in the BOCNT
Jeremiah 18 in the BOECS
Jeremiah 18 in the BOGWICC
Jeremiah 18 in the BOHCB
Jeremiah 18 in the BOHCV
Jeremiah 18 in the BOHLNT
Jeremiah 18 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 18 in the BOICB
Jeremiah 18 in the BOILNTAP
Jeremiah 18 in the BOITCV
Jeremiah 18 in the BOKCV
Jeremiah 18 in the BOKCV2
Jeremiah 18 in the BOKHWOG
Jeremiah 18 in the BOKSSV
Jeremiah 18 in the BOLCB
Jeremiah 18 in the BOLCB2
Jeremiah 18 in the BOMCV
Jeremiah 18 in the BONAV
Jeremiah 18 in the BONCB
Jeremiah 18 in the BONLT
Jeremiah 18 in the BONUT2
Jeremiah 18 in the BOPLNT
Jeremiah 18 in the BOSCB
Jeremiah 18 in the BOSNC
Jeremiah 18 in the BOTLNT
Jeremiah 18 in the BOVCB
Jeremiah 18 in the BPBB
Jeremiah 18 in the BPH
Jeremiah 18 in the BSB
Jeremiah 18 in the CCB
Jeremiah 18 in the CUV
Jeremiah 18 in the CUVS
Jeremiah 18 in the DBT
Jeremiah 18 in the DGDNT
Jeremiah 18 in the DHNT
Jeremiah 18 in the DNT
Jeremiah 18 in the ELBE
Jeremiah 18 in the EMTV
Jeremiah 18 in the ESV
Jeremiah 18 in the FBV
Jeremiah 18 in the FEB
Jeremiah 18 in the GGMNT
Jeremiah 18 in the GNT
Jeremiah 18 in the HARY
Jeremiah 18 in the HNT
Jeremiah 18 in the IRVA
Jeremiah 18 in the IRVB
Jeremiah 18 in the IRVG
Jeremiah 18 in the IRVH
Jeremiah 18 in the IRVK
Jeremiah 18 in the IRVM
Jeremiah 18 in the IRVM2
Jeremiah 18 in the IRVO
Jeremiah 18 in the IRVP
Jeremiah 18 in the IRVT
Jeremiah 18 in the IRVT2
Jeremiah 18 in the IRVU
Jeremiah 18 in the ISVN
Jeremiah 18 in the JSNT
Jeremiah 18 in the KAPI
Jeremiah 18 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 18 in the KBV
Jeremiah 18 in the KJV
Jeremiah 18 in the KNFD
Jeremiah 18 in the LBA
Jeremiah 18 in the LBLA
Jeremiah 18 in the LNT
Jeremiah 18 in the LSV
Jeremiah 18 in the MAAL
Jeremiah 18 in the MBV
Jeremiah 18 in the MBV2
Jeremiah 18 in the MHNT
Jeremiah 18 in the MKNFD
Jeremiah 18 in the MNG
Jeremiah 18 in the MNT
Jeremiah 18 in the MNT2
Jeremiah 18 in the MRS1T
Jeremiah 18 in the NAA
Jeremiah 18 in the NASB
Jeremiah 18 in the NBLA
Jeremiah 18 in the NBS
Jeremiah 18 in the NBVTP
Jeremiah 18 in the NET2
Jeremiah 18 in the NIV11
Jeremiah 18 in the NNT
Jeremiah 18 in the NNT2
Jeremiah 18 in the NNT3
Jeremiah 18 in the PDDPT
Jeremiah 18 in the PFNT
Jeremiah 18 in the RMNT
Jeremiah 18 in the SBIAS
Jeremiah 18 in the SBIBS
Jeremiah 18 in the SBIBS2
Jeremiah 18 in the SBICS
Jeremiah 18 in the SBIDS
Jeremiah 18 in the SBIGS
Jeremiah 18 in the SBIHS
Jeremiah 18 in the SBIIS
Jeremiah 18 in the SBIIS2
Jeremiah 18 in the SBIIS3
Jeremiah 18 in the SBIKS
Jeremiah 18 in the SBIKS2
Jeremiah 18 in the SBIMS
Jeremiah 18 in the SBIOS
Jeremiah 18 in the SBIPS
Jeremiah 18 in the SBISS
Jeremiah 18 in the SBITS
Jeremiah 18 in the SBITS2
Jeremiah 18 in the SBITS3
Jeremiah 18 in the SBITS4
Jeremiah 18 in the SBIUS
Jeremiah 18 in the SBIVS
Jeremiah 18 in the SBT
Jeremiah 18 in the SBT1E
Jeremiah 18 in the SCHL
Jeremiah 18 in the SNT
Jeremiah 18 in the SUSU
Jeremiah 18 in the SUSU2
Jeremiah 18 in the SYNO
Jeremiah 18 in the TBIAOTANT
Jeremiah 18 in the TBT1E
Jeremiah 18 in the TBT1E2
Jeremiah 18 in the TFTIP
Jeremiah 18 in the TFTU
Jeremiah 18 in the TGNTATF3T
Jeremiah 18 in the THAI
Jeremiah 18 in the TNFD
Jeremiah 18 in the TNT
Jeremiah 18 in the TNTIK
Jeremiah 18 in the TNTIL
Jeremiah 18 in the TNTIN
Jeremiah 18 in the TNTIP
Jeremiah 18 in the TNTIZ
Jeremiah 18 in the TOMA
Jeremiah 18 in the TTENT
Jeremiah 18 in the UBG
Jeremiah 18 in the UGV
Jeremiah 18 in the UGV2
Jeremiah 18 in the UGV3
Jeremiah 18 in the VBL
Jeremiah 18 in the VDCC
Jeremiah 18 in the YALU
Jeremiah 18 in the YAPE
Jeremiah 18 in the YBVTP
Jeremiah 18 in the ZBP