Jeremiah 27 (BOYCB)
1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wí pé. 2 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí, “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ. 3 Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda. 4 Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ. 5 Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi. 6 Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀. 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún. 8 “ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni OLÚWA wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀. 9 Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’ 10 Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé. 11 Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni OLÚWA wí.” ’ ” 12 Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè. 13 Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí OLÚWA fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli? 14 Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín. 15 ‘Èmi kò rán wọn ni OLÚWA wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ” 16 Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA sọ, ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé OLÚWA ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn. 17 Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro? 18 Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ OLÚWA, jẹ́ kí wọ́n bẹ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé OLÚWA àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 19 Nítorí pé, èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sọ nípa àwọn opó, omi Òkun ní ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ní ti ohun èlò ìyókù tí ó kù ní ìlú náà. 20 Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu. 21 Lóòótọ́, èyí ni ọ̀rọ̀ tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí nípa àwọn ohun ìṣúra tí ó ṣẹ́kù ní ilé OLÚWA àti ní ààfin ọba Juda àti ní Jerusalẹmu: 22 ‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Babeli, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA. ‘Lẹ́yìn èyí, Èmi yóò mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”
In Other Versions
Jeremiah 27 in the ANGEFD
Jeremiah 27 in the ANTPNG2D
Jeremiah 27 in the AS21
Jeremiah 27 in the BAGH
Jeremiah 27 in the BBPNG
Jeremiah 27 in the BBT1E
Jeremiah 27 in the BDS
Jeremiah 27 in the BEV
Jeremiah 27 in the BHAD
Jeremiah 27 in the BIB
Jeremiah 27 in the BLPT
Jeremiah 27 in the BNT
Jeremiah 27 in the BNTABOOT
Jeremiah 27 in the BNTLV
Jeremiah 27 in the BOATCB
Jeremiah 27 in the BOATCB2
Jeremiah 27 in the BOBCV
Jeremiah 27 in the BOCNT
Jeremiah 27 in the BOECS
Jeremiah 27 in the BOGWICC
Jeremiah 27 in the BOHCB
Jeremiah 27 in the BOHCV
Jeremiah 27 in the BOHLNT
Jeremiah 27 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 27 in the BOICB
Jeremiah 27 in the BOILNTAP
Jeremiah 27 in the BOITCV
Jeremiah 27 in the BOKCV
Jeremiah 27 in the BOKCV2
Jeremiah 27 in the BOKHWOG
Jeremiah 27 in the BOKSSV
Jeremiah 27 in the BOLCB
Jeremiah 27 in the BOLCB2
Jeremiah 27 in the BOMCV
Jeremiah 27 in the BONAV
Jeremiah 27 in the BONCB
Jeremiah 27 in the BONLT
Jeremiah 27 in the BONUT2
Jeremiah 27 in the BOPLNT
Jeremiah 27 in the BOSCB
Jeremiah 27 in the BOSNC
Jeremiah 27 in the BOTLNT
Jeremiah 27 in the BOVCB
Jeremiah 27 in the BPBB
Jeremiah 27 in the BPH
Jeremiah 27 in the BSB
Jeremiah 27 in the CCB
Jeremiah 27 in the CUV
Jeremiah 27 in the CUVS
Jeremiah 27 in the DBT
Jeremiah 27 in the DGDNT
Jeremiah 27 in the DHNT
Jeremiah 27 in the DNT
Jeremiah 27 in the ELBE
Jeremiah 27 in the EMTV
Jeremiah 27 in the ESV
Jeremiah 27 in the FBV
Jeremiah 27 in the FEB
Jeremiah 27 in the GGMNT
Jeremiah 27 in the GNT
Jeremiah 27 in the HARY
Jeremiah 27 in the HNT
Jeremiah 27 in the IRVA
Jeremiah 27 in the IRVB
Jeremiah 27 in the IRVG
Jeremiah 27 in the IRVH
Jeremiah 27 in the IRVK
Jeremiah 27 in the IRVM
Jeremiah 27 in the IRVM2
Jeremiah 27 in the IRVO
Jeremiah 27 in the IRVP
Jeremiah 27 in the IRVT
Jeremiah 27 in the IRVT2
Jeremiah 27 in the IRVU
Jeremiah 27 in the ISVN
Jeremiah 27 in the JSNT
Jeremiah 27 in the KAPI
Jeremiah 27 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 27 in the KBV
Jeremiah 27 in the KJV
Jeremiah 27 in the KNFD
Jeremiah 27 in the LBA
Jeremiah 27 in the LBLA
Jeremiah 27 in the LNT
Jeremiah 27 in the LSV
Jeremiah 27 in the MAAL
Jeremiah 27 in the MBV
Jeremiah 27 in the MBV2
Jeremiah 27 in the MHNT
Jeremiah 27 in the MKNFD
Jeremiah 27 in the MNG
Jeremiah 27 in the MNT
Jeremiah 27 in the MNT2
Jeremiah 27 in the MRS1T
Jeremiah 27 in the NAA
Jeremiah 27 in the NASB
Jeremiah 27 in the NBLA
Jeremiah 27 in the NBS
Jeremiah 27 in the NBVTP
Jeremiah 27 in the NET2
Jeremiah 27 in the NIV11
Jeremiah 27 in the NNT
Jeremiah 27 in the NNT2
Jeremiah 27 in the NNT3
Jeremiah 27 in the PDDPT
Jeremiah 27 in the PFNT
Jeremiah 27 in the RMNT
Jeremiah 27 in the SBIAS
Jeremiah 27 in the SBIBS
Jeremiah 27 in the SBIBS2
Jeremiah 27 in the SBICS
Jeremiah 27 in the SBIDS
Jeremiah 27 in the SBIGS
Jeremiah 27 in the SBIHS
Jeremiah 27 in the SBIIS
Jeremiah 27 in the SBIIS2
Jeremiah 27 in the SBIIS3
Jeremiah 27 in the SBIKS
Jeremiah 27 in the SBIKS2
Jeremiah 27 in the SBIMS
Jeremiah 27 in the SBIOS
Jeremiah 27 in the SBIPS
Jeremiah 27 in the SBISS
Jeremiah 27 in the SBITS
Jeremiah 27 in the SBITS2
Jeremiah 27 in the SBITS3
Jeremiah 27 in the SBITS4
Jeremiah 27 in the SBIUS
Jeremiah 27 in the SBIVS
Jeremiah 27 in the SBT
Jeremiah 27 in the SBT1E
Jeremiah 27 in the SCHL
Jeremiah 27 in the SNT
Jeremiah 27 in the SUSU
Jeremiah 27 in the SUSU2
Jeremiah 27 in the SYNO
Jeremiah 27 in the TBIAOTANT
Jeremiah 27 in the TBT1E
Jeremiah 27 in the TBT1E2
Jeremiah 27 in the TFTIP
Jeremiah 27 in the TFTU
Jeremiah 27 in the TGNTATF3T
Jeremiah 27 in the THAI
Jeremiah 27 in the TNFD
Jeremiah 27 in the TNT
Jeremiah 27 in the TNTIK
Jeremiah 27 in the TNTIL
Jeremiah 27 in the TNTIN
Jeremiah 27 in the TNTIP
Jeremiah 27 in the TNTIZ
Jeremiah 27 in the TOMA
Jeremiah 27 in the TTENT
Jeremiah 27 in the UBG
Jeremiah 27 in the UGV
Jeremiah 27 in the UGV2
Jeremiah 27 in the UGV3
Jeremiah 27 in the VBL
Jeremiah 27 in the VDCC
Jeremiah 27 in the YALU
Jeremiah 27 in the YAPE
Jeremiah 27 in the YBVTP
Jeremiah 27 in the ZBP