Jeremiah 46 (BOYCB)
1 Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè. 2 Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: 3 “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà! 4 Ẹ di ẹṣin ní gàárì,kí ẹ sì gùn ún.Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹpẹ̀lú àṣíborí yín!Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin. 5 Kí ni nǹkan tí mo tún rí?Wọ́n bẹ̀rù,wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.Wọ́n sá,wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”ni OLÚWA wí. 6 “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.Ní àríwá ní ibi odò Eufuratewọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. 7 “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì? 8 Ejibiti dìde bí odò náà,bí omi odò tí ń ru.Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run. 9 Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun. 10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun,ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.Nítorí pé Olúwa, OLÚWA àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate. 11 “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,kì yóò sí ìwòsàn fún ọ. 12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.” 13 Èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti: 14 “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’ 15 Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí OLÚWA yóò tì wọ́n ṣubú. 16 Wọn yóò máa ṣubú léralérawọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padàsí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,kúrò níbi idà àwọn aninilára.’ 17 Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’ 18 “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé,“Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àtigẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé. 19 Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibitipèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹnítorí Memfisi yóò di ahoroa ó sì fi jóná, láìní olùgbé. 20 “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibitiṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,ó dé láti àríwá. 21 Àwọn jagunjagun rẹ̀dàbí àbọ́pa akọ màlúù.Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,wọn ó sì jùmọ̀ sá,wọn kò ní le dúró,nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọnàsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà. 22 Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sábí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,gẹ́gẹ́ bí i ti agégi. 23 Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni OLÚWA wí,“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀.Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye. 24 A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti,a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.” 25 OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26 Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni OLÚWA wí. 27 “Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,má fòyà, ìwọ Israẹli.Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á. 28 Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí.“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.Èmi kò ní run yín tán.Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
In Other Versions
Jeremiah 46 in the ANGEFD
Jeremiah 46 in the ANTPNG2D
Jeremiah 46 in the AS21
Jeremiah 46 in the BAGH
Jeremiah 46 in the BBPNG
Jeremiah 46 in the BBT1E
Jeremiah 46 in the BDS
Jeremiah 46 in the BEV
Jeremiah 46 in the BHAD
Jeremiah 46 in the BIB
Jeremiah 46 in the BLPT
Jeremiah 46 in the BNT
Jeremiah 46 in the BNTABOOT
Jeremiah 46 in the BNTLV
Jeremiah 46 in the BOATCB
Jeremiah 46 in the BOATCB2
Jeremiah 46 in the BOBCV
Jeremiah 46 in the BOCNT
Jeremiah 46 in the BOECS
Jeremiah 46 in the BOGWICC
Jeremiah 46 in the BOHCB
Jeremiah 46 in the BOHCV
Jeremiah 46 in the BOHLNT
Jeremiah 46 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 46 in the BOICB
Jeremiah 46 in the BOILNTAP
Jeremiah 46 in the BOITCV
Jeremiah 46 in the BOKCV
Jeremiah 46 in the BOKCV2
Jeremiah 46 in the BOKHWOG
Jeremiah 46 in the BOKSSV
Jeremiah 46 in the BOLCB
Jeremiah 46 in the BOLCB2
Jeremiah 46 in the BOMCV
Jeremiah 46 in the BONAV
Jeremiah 46 in the BONCB
Jeremiah 46 in the BONLT
Jeremiah 46 in the BONUT2
Jeremiah 46 in the BOPLNT
Jeremiah 46 in the BOSCB
Jeremiah 46 in the BOSNC
Jeremiah 46 in the BOTLNT
Jeremiah 46 in the BOVCB
Jeremiah 46 in the BPBB
Jeremiah 46 in the BPH
Jeremiah 46 in the BSB
Jeremiah 46 in the CCB
Jeremiah 46 in the CUV
Jeremiah 46 in the CUVS
Jeremiah 46 in the DBT
Jeremiah 46 in the DGDNT
Jeremiah 46 in the DHNT
Jeremiah 46 in the DNT
Jeremiah 46 in the ELBE
Jeremiah 46 in the EMTV
Jeremiah 46 in the ESV
Jeremiah 46 in the FBV
Jeremiah 46 in the FEB
Jeremiah 46 in the GGMNT
Jeremiah 46 in the GNT
Jeremiah 46 in the HARY
Jeremiah 46 in the HNT
Jeremiah 46 in the IRVA
Jeremiah 46 in the IRVB
Jeremiah 46 in the IRVG
Jeremiah 46 in the IRVH
Jeremiah 46 in the IRVK
Jeremiah 46 in the IRVM
Jeremiah 46 in the IRVM2
Jeremiah 46 in the IRVO
Jeremiah 46 in the IRVP
Jeremiah 46 in the IRVT
Jeremiah 46 in the IRVT2
Jeremiah 46 in the IRVU
Jeremiah 46 in the ISVN
Jeremiah 46 in the JSNT
Jeremiah 46 in the KAPI
Jeremiah 46 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 46 in the KBV
Jeremiah 46 in the KJV
Jeremiah 46 in the KNFD
Jeremiah 46 in the LBA
Jeremiah 46 in the LBLA
Jeremiah 46 in the LNT
Jeremiah 46 in the LSV
Jeremiah 46 in the MAAL
Jeremiah 46 in the MBV
Jeremiah 46 in the MBV2
Jeremiah 46 in the MHNT
Jeremiah 46 in the MKNFD
Jeremiah 46 in the MNG
Jeremiah 46 in the MNT
Jeremiah 46 in the MNT2
Jeremiah 46 in the MRS1T
Jeremiah 46 in the NAA
Jeremiah 46 in the NASB
Jeremiah 46 in the NBLA
Jeremiah 46 in the NBS
Jeremiah 46 in the NBVTP
Jeremiah 46 in the NET2
Jeremiah 46 in the NIV11
Jeremiah 46 in the NNT
Jeremiah 46 in the NNT2
Jeremiah 46 in the NNT3
Jeremiah 46 in the PDDPT
Jeremiah 46 in the PFNT
Jeremiah 46 in the RMNT
Jeremiah 46 in the SBIAS
Jeremiah 46 in the SBIBS
Jeremiah 46 in the SBIBS2
Jeremiah 46 in the SBICS
Jeremiah 46 in the SBIDS
Jeremiah 46 in the SBIGS
Jeremiah 46 in the SBIHS
Jeremiah 46 in the SBIIS
Jeremiah 46 in the SBIIS2
Jeremiah 46 in the SBIIS3
Jeremiah 46 in the SBIKS
Jeremiah 46 in the SBIKS2
Jeremiah 46 in the SBIMS
Jeremiah 46 in the SBIOS
Jeremiah 46 in the SBIPS
Jeremiah 46 in the SBISS
Jeremiah 46 in the SBITS
Jeremiah 46 in the SBITS2
Jeremiah 46 in the SBITS3
Jeremiah 46 in the SBITS4
Jeremiah 46 in the SBIUS
Jeremiah 46 in the SBIVS
Jeremiah 46 in the SBT
Jeremiah 46 in the SBT1E
Jeremiah 46 in the SCHL
Jeremiah 46 in the SNT
Jeremiah 46 in the SUSU
Jeremiah 46 in the SUSU2
Jeremiah 46 in the SYNO
Jeremiah 46 in the TBIAOTANT
Jeremiah 46 in the TBT1E
Jeremiah 46 in the TBT1E2
Jeremiah 46 in the TFTIP
Jeremiah 46 in the TFTU
Jeremiah 46 in the TGNTATF3T
Jeremiah 46 in the THAI
Jeremiah 46 in the TNFD
Jeremiah 46 in the TNT
Jeremiah 46 in the TNTIK
Jeremiah 46 in the TNTIL
Jeremiah 46 in the TNTIN
Jeremiah 46 in the TNTIP
Jeremiah 46 in the TNTIZ
Jeremiah 46 in the TOMA
Jeremiah 46 in the TTENT
Jeremiah 46 in the UBG
Jeremiah 46 in the UGV
Jeremiah 46 in the UGV2
Jeremiah 46 in the UGV3
Jeremiah 46 in the VBL
Jeremiah 46 in the VDCC
Jeremiah 46 in the YALU
Jeremiah 46 in the YAPE
Jeremiah 46 in the YBVTP
Jeremiah 46 in the ZBP