Job 1 (BOYCB)

1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú. 2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. 3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ. 4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. 5 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo. 6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú OLÚWA, Satani sì wá pẹ̀lú wọn. 7 OLÚWA sì bi Satani wí pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?”Nígbà náà ní Satani dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Ní ìlọsíwá-sẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, àti ní ìrìnkèrindò nínú rẹ̀.” 8 OLÚWA sì sọ fún Satani pé, “Ìwọ ha kíyèsi Jobu ìránṣẹ́ mi, pé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀ ní ayé, ọkùnrin tí í ṣe olóòtítọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti ó sì kórìíra ìwà búburú.” 9 Nígbà náà ni Satani dá OLÚWA lóhùn wí pé, “Jobu ha bẹ̀rù Ọlọ́run ní asán bí?” 10 “Ìwọ kò ha ti ṣọgbà yìí ká, àti yí ilé rẹ̀ àti yí ohun tí ó ní ká, ní ìhà gbogbo? Ìwọ bùsi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì ń pọ̀ si ní ilẹ̀. 11 Ǹjẹ́, nawọ́ rẹ nísinsin yìí, kí ó sì fi tọ́ ohun gbogbo tí ó ni; bí kì yóò sì bọ́hùn ni ojú rẹ.” 12 OLÚWA sì dá Satani lóhùn wí pé, “Kíyèsi i, ohun gbogbo tí ó ní ń bẹ ní ìkáwọ́ rẹ, kìkì òun tìkára rẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ rẹ kàn.”Bẹ́ẹ̀ ni Satani jáde lọ kúrò níwájú OLÚWA. 13 Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, 14 oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn, 15 àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.” 16 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.” 17 Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!” 18 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. 19 Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ. 20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21 wí pé,“Ní ìhòhò ní mo ti inú ìyá mi jáde wá,ni ìhòhò ní èmi yóò sì tún padà lọ. OLÚWA fi fún ni, OLÚWA sì gbà á lọ,ìbùkún ni fún orúkọ OLÚWA.” 22 Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.

In Other Versions

Job 1 in the ANGEFD

Job 1 in the ANTPNG2D

Job 1 in the AS21

Job 1 in the BAGH

Job 1 in the BBPNG

Job 1 in the BBT1E

Job 1 in the BDS

Job 1 in the BEV

Job 1 in the BHAD

Job 1 in the BIB

Job 1 in the BLPT

Job 1 in the BNT

Job 1 in the BNTABOOT

Job 1 in the BNTLV

Job 1 in the BOATCB

Job 1 in the BOATCB2

Job 1 in the BOBCV

Job 1 in the BOCNT

Job 1 in the BOECS

Job 1 in the BOGWICC

Job 1 in the BOHCB

Job 1 in the BOHCV

Job 1 in the BOHLNT

Job 1 in the BOHNTLTAL

Job 1 in the BOICB

Job 1 in the BOILNTAP

Job 1 in the BOITCV

Job 1 in the BOKCV

Job 1 in the BOKCV2

Job 1 in the BOKHWOG

Job 1 in the BOKSSV

Job 1 in the BOLCB

Job 1 in the BOLCB2

Job 1 in the BOMCV

Job 1 in the BONAV

Job 1 in the BONCB

Job 1 in the BONLT

Job 1 in the BONUT2

Job 1 in the BOPLNT

Job 1 in the BOSCB

Job 1 in the BOSNC

Job 1 in the BOTLNT

Job 1 in the BOVCB

Job 1 in the BPBB

Job 1 in the BPH

Job 1 in the BSB

Job 1 in the CCB

Job 1 in the CUV

Job 1 in the CUVS

Job 1 in the DBT

Job 1 in the DGDNT

Job 1 in the DHNT

Job 1 in the DNT

Job 1 in the ELBE

Job 1 in the EMTV

Job 1 in the ESV

Job 1 in the FBV

Job 1 in the FEB

Job 1 in the GGMNT

Job 1 in the GNT

Job 1 in the HARY

Job 1 in the HNT

Job 1 in the IRVA

Job 1 in the IRVB

Job 1 in the IRVG

Job 1 in the IRVH

Job 1 in the IRVK

Job 1 in the IRVM

Job 1 in the IRVM2

Job 1 in the IRVO

Job 1 in the IRVP

Job 1 in the IRVT

Job 1 in the IRVT2

Job 1 in the IRVU

Job 1 in the ISVN

Job 1 in the JSNT

Job 1 in the KAPI

Job 1 in the KBT1ETNIK

Job 1 in the KBV

Job 1 in the KJV

Job 1 in the KNFD

Job 1 in the LBA

Job 1 in the LBLA

Job 1 in the LNT

Job 1 in the LSV

Job 1 in the MAAL

Job 1 in the MBV

Job 1 in the MBV2

Job 1 in the MHNT

Job 1 in the MKNFD

Job 1 in the MNG

Job 1 in the MNT

Job 1 in the MNT2

Job 1 in the MRS1T

Job 1 in the NAA

Job 1 in the NASB

Job 1 in the NBLA

Job 1 in the NBS

Job 1 in the NBVTP

Job 1 in the NET2

Job 1 in the NIV11

Job 1 in the NNT

Job 1 in the NNT2

Job 1 in the NNT3

Job 1 in the PDDPT

Job 1 in the PFNT

Job 1 in the RMNT

Job 1 in the SBIAS

Job 1 in the SBIBS

Job 1 in the SBIBS2

Job 1 in the SBICS

Job 1 in the SBIDS

Job 1 in the SBIGS

Job 1 in the SBIHS

Job 1 in the SBIIS

Job 1 in the SBIIS2

Job 1 in the SBIIS3

Job 1 in the SBIKS

Job 1 in the SBIKS2

Job 1 in the SBIMS

Job 1 in the SBIOS

Job 1 in the SBIPS

Job 1 in the SBISS

Job 1 in the SBITS

Job 1 in the SBITS2

Job 1 in the SBITS3

Job 1 in the SBITS4

Job 1 in the SBIUS

Job 1 in the SBIVS

Job 1 in the SBT

Job 1 in the SBT1E

Job 1 in the SCHL

Job 1 in the SNT

Job 1 in the SUSU

Job 1 in the SUSU2

Job 1 in the SYNO

Job 1 in the TBIAOTANT

Job 1 in the TBT1E

Job 1 in the TBT1E2

Job 1 in the TFTIP

Job 1 in the TFTU

Job 1 in the TGNTATF3T

Job 1 in the THAI

Job 1 in the TNFD

Job 1 in the TNT

Job 1 in the TNTIK

Job 1 in the TNTIL

Job 1 in the TNTIN

Job 1 in the TNTIP

Job 1 in the TNTIZ

Job 1 in the TOMA

Job 1 in the TTENT

Job 1 in the UBG

Job 1 in the UGV

Job 1 in the UGV2

Job 1 in the UGV3

Job 1 in the VBL

Job 1 in the VDCC

Job 1 in the YALU

Job 1 in the YAPE

Job 1 in the YBVTP

Job 1 in the ZBP