Joshua 1 (BOYCB)
1 Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ OLÚWA, OLÚWA sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose, 2 “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. 3 Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose. 4 Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun Ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. 5 Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́. 6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. 7 Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. 8 Má ṣe jẹ́ kí ìwé òfin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. 9 Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé OLÚWA à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.” 10 Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀, 11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ” 12 Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé, 13 “Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ OLÚWA pa fún yín: ‘OLÚWA Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’ 14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Mose fún un yin ní ìlà-oòrùn Jordani; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́ 15 títí OLÚWA yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mose ìránṣẹ́ OLÚWA fi fún un yin ní agbègbè ìlà-oòrùn ti Jordani.” 16 Nígbà náà ni wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pàṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe, ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ. 17 Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́rọ̀ sí Mose nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí OLÚWA Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Mose. 18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò pàṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ sá à ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”
In Other Versions
Joshua 1 in the ANGEFD
Joshua 1 in the ANTPNG2D
Joshua 1 in the AS21
Joshua 1 in the BAGH
Joshua 1 in the BBPNG
Joshua 1 in the BBT1E
Joshua 1 in the BDS
Joshua 1 in the BEV
Joshua 1 in the BHAD
Joshua 1 in the BIB
Joshua 1 in the BLPT
Joshua 1 in the BNT
Joshua 1 in the BNTABOOT
Joshua 1 in the BNTLV
Joshua 1 in the BOATCB
Joshua 1 in the BOATCB2
Joshua 1 in the BOBCV
Joshua 1 in the BOCNT
Joshua 1 in the BOECS
Joshua 1 in the BOGWICC
Joshua 1 in the BOHCB
Joshua 1 in the BOHCV
Joshua 1 in the BOHLNT
Joshua 1 in the BOHNTLTAL
Joshua 1 in the BOICB
Joshua 1 in the BOILNTAP
Joshua 1 in the BOITCV
Joshua 1 in the BOKCV
Joshua 1 in the BOKCV2
Joshua 1 in the BOKHWOG
Joshua 1 in the BOKSSV
Joshua 1 in the BOLCB
Joshua 1 in the BOLCB2
Joshua 1 in the BOMCV
Joshua 1 in the BONAV
Joshua 1 in the BONCB
Joshua 1 in the BONLT
Joshua 1 in the BONUT2
Joshua 1 in the BOPLNT
Joshua 1 in the BOSCB
Joshua 1 in the BOSNC
Joshua 1 in the BOTLNT
Joshua 1 in the BOVCB
Joshua 1 in the BPBB
Joshua 1 in the BPH
Joshua 1 in the BSB
Joshua 1 in the CCB
Joshua 1 in the CUV
Joshua 1 in the CUVS
Joshua 1 in the DBT
Joshua 1 in the DGDNT
Joshua 1 in the DHNT
Joshua 1 in the DNT
Joshua 1 in the ELBE
Joshua 1 in the EMTV
Joshua 1 in the ESV
Joshua 1 in the FBV
Joshua 1 in the FEB
Joshua 1 in the GGMNT
Joshua 1 in the GNT
Joshua 1 in the HARY
Joshua 1 in the HNT
Joshua 1 in the IRVA
Joshua 1 in the IRVB
Joshua 1 in the IRVG
Joshua 1 in the IRVH
Joshua 1 in the IRVK
Joshua 1 in the IRVM
Joshua 1 in the IRVM2
Joshua 1 in the IRVO
Joshua 1 in the IRVP
Joshua 1 in the IRVT
Joshua 1 in the IRVT2
Joshua 1 in the IRVU
Joshua 1 in the ISVN
Joshua 1 in the JSNT
Joshua 1 in the KAPI
Joshua 1 in the KBT1ETNIK
Joshua 1 in the KBV
Joshua 1 in the KJV
Joshua 1 in the KNFD
Joshua 1 in the LBA
Joshua 1 in the LBLA
Joshua 1 in the LNT
Joshua 1 in the LSV
Joshua 1 in the MAAL
Joshua 1 in the MBV
Joshua 1 in the MBV2
Joshua 1 in the MHNT
Joshua 1 in the MKNFD
Joshua 1 in the MNG
Joshua 1 in the MNT
Joshua 1 in the MNT2
Joshua 1 in the MRS1T
Joshua 1 in the NAA
Joshua 1 in the NASB
Joshua 1 in the NBLA
Joshua 1 in the NBS
Joshua 1 in the NBVTP
Joshua 1 in the NET2
Joshua 1 in the NIV11
Joshua 1 in the NNT
Joshua 1 in the NNT2
Joshua 1 in the NNT3
Joshua 1 in the PDDPT
Joshua 1 in the PFNT
Joshua 1 in the RMNT
Joshua 1 in the SBIAS
Joshua 1 in the SBIBS
Joshua 1 in the SBIBS2
Joshua 1 in the SBICS
Joshua 1 in the SBIDS
Joshua 1 in the SBIGS
Joshua 1 in the SBIHS
Joshua 1 in the SBIIS
Joshua 1 in the SBIIS2
Joshua 1 in the SBIIS3
Joshua 1 in the SBIKS
Joshua 1 in the SBIKS2
Joshua 1 in the SBIMS
Joshua 1 in the SBIOS
Joshua 1 in the SBIPS
Joshua 1 in the SBISS
Joshua 1 in the SBITS
Joshua 1 in the SBITS2
Joshua 1 in the SBITS3
Joshua 1 in the SBITS4
Joshua 1 in the SBIUS
Joshua 1 in the SBIVS
Joshua 1 in the SBT
Joshua 1 in the SBT1E
Joshua 1 in the SCHL
Joshua 1 in the SNT
Joshua 1 in the SUSU
Joshua 1 in the SUSU2
Joshua 1 in the SYNO
Joshua 1 in the TBIAOTANT
Joshua 1 in the TBT1E
Joshua 1 in the TBT1E2
Joshua 1 in the TFTIP
Joshua 1 in the TFTU
Joshua 1 in the TGNTATF3T
Joshua 1 in the THAI
Joshua 1 in the TNFD
Joshua 1 in the TNT
Joshua 1 in the TNTIK
Joshua 1 in the TNTIL
Joshua 1 in the TNTIN
Joshua 1 in the TNTIP
Joshua 1 in the TNTIZ
Joshua 1 in the TOMA
Joshua 1 in the TTENT
Joshua 1 in the UBG
Joshua 1 in the UGV
Joshua 1 in the UGV2
Joshua 1 in the UGV3
Joshua 1 in the VBL
Joshua 1 in the VDCC
Joshua 1 in the YALU
Joshua 1 in the YAPE
Joshua 1 in the YBVTP
Joshua 1 in the ZBP