Joshua 11 (BOYCB)
1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jobabu ọba Madoni, sí ọba Ṣimroni àti Akṣafu, 2 àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúúsù ti Kinnereti, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafoti Dori ní ìwọ̀-oòrùn; 3 sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa. 4 Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun. 5 Gbogbo àwọn ọba yìí pa ọmọ-ogun wọn pọ̀, wọ́n sì pa ibùdó sí ibi omi Meromu láti bá Israẹli jà. 6 OLÚWA sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí ní àkókò yìí ní ọ̀la, gbogbo wọn ni èmi yóò fi lé Israẹli lọ́wọ́ ní pípa. Ìwọ yóò já iṣan ẹ̀yìn ẹṣin wọn, ìwọ yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn.” 7 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ yọ sí wọn ní òjijì ní ibi omi Meromu, wọ́n sì kọlù wọ́n, 8 OLÚWA sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀. 9 Joṣua sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ: Ó sì já iṣan ẹ̀yìn ẹsẹ̀ ẹṣin wọn ó sì sun kẹ̀kẹ́ ogun wọn. 10 Ní àkókò náà Joṣua sì padà sẹ́yìn, ó sì ṣẹ́gun Hasori, ó sì fi idà pa ọba rẹ̀. (Hasori tí jẹ́ olú fún gbogbo àwọn ìlú wọ̀nyí kó tó di àkókò yí.) 11 Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátápátá, wọn kò sì fi ohun alààyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hasori fúnra rẹ̀. 12 Joṣua sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ OLÚWA ti pàṣẹ. 13 Síbẹ̀ Israẹli kò sun ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kéékèèké, àyàfi Hasori nìkan tí Joṣua sun. 14 Àwọn ará Israẹli sì kó gbogbo ìkógun àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátápátá, kò sí ẹni tí ó wà láààyè. 15 Bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún Mose. 16 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo gúúsù, gbogbo agbègbè Goṣeni, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Israẹli, 17 láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n. 18 Joṣua sì bá gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́. 19 Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Israẹli ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hifi tí wọ́n ń gbé ní Gibeoni, gbogbo wọn ló bá a jagun. 20 Nítorí OLÚWA fúnra rẹ̀ ní ó sé ọkàn wọn le, kí wọn kí ó lè bá Israẹli jagun, kí òun lè pa wọ́n run pátápátá, kí wọn má sì ṣe rí ojúrere, ṣùgbọ́n kí ó lè pa wọ́n, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 21 Ní àkókò náà ni Joṣua lọ tí ó sì run àwọn ará Anaki kúrò ní ilẹ̀ òkè, láti Hebroni, Debiri, àti ní Anabu, àti gbogbo ilẹ̀ Juda, àti kúrò ní gbogbo ilẹ̀ òkè Israẹli. Joṣua sì run gbogbo wọn pátápátá àti ìlú wọn. 22 Kò sí ará Anaki kankan tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Israẹli: bí kò ṣe ní Gasa, Gati àti Aṣdodu. 23 Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua sì gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose, ó sì fi fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nípa ẹ̀yà wọn.Ilẹ̀ náà sì sinmi ogun.
In Other Versions
Joshua 11 in the ANGEFD
Joshua 11 in the ANTPNG2D
Joshua 11 in the AS21
Joshua 11 in the BAGH
Joshua 11 in the BBPNG
Joshua 11 in the BBT1E
Joshua 11 in the BDS
Joshua 11 in the BEV
Joshua 11 in the BHAD
Joshua 11 in the BIB
Joshua 11 in the BLPT
Joshua 11 in the BNT
Joshua 11 in the BNTABOOT
Joshua 11 in the BNTLV
Joshua 11 in the BOATCB
Joshua 11 in the BOATCB2
Joshua 11 in the BOBCV
Joshua 11 in the BOCNT
Joshua 11 in the BOECS
Joshua 11 in the BOGWICC
Joshua 11 in the BOHCB
Joshua 11 in the BOHCV
Joshua 11 in the BOHLNT
Joshua 11 in the BOHNTLTAL
Joshua 11 in the BOICB
Joshua 11 in the BOILNTAP
Joshua 11 in the BOITCV
Joshua 11 in the BOKCV
Joshua 11 in the BOKCV2
Joshua 11 in the BOKHWOG
Joshua 11 in the BOKSSV
Joshua 11 in the BOLCB
Joshua 11 in the BOLCB2
Joshua 11 in the BOMCV
Joshua 11 in the BONAV
Joshua 11 in the BONCB
Joshua 11 in the BONLT
Joshua 11 in the BONUT2
Joshua 11 in the BOPLNT
Joshua 11 in the BOSCB
Joshua 11 in the BOSNC
Joshua 11 in the BOTLNT
Joshua 11 in the BOVCB
Joshua 11 in the BPBB
Joshua 11 in the BPH
Joshua 11 in the BSB
Joshua 11 in the CCB
Joshua 11 in the CUV
Joshua 11 in the CUVS
Joshua 11 in the DBT
Joshua 11 in the DGDNT
Joshua 11 in the DHNT
Joshua 11 in the DNT
Joshua 11 in the ELBE
Joshua 11 in the EMTV
Joshua 11 in the ESV
Joshua 11 in the FBV
Joshua 11 in the FEB
Joshua 11 in the GGMNT
Joshua 11 in the GNT
Joshua 11 in the HARY
Joshua 11 in the HNT
Joshua 11 in the IRVA
Joshua 11 in the IRVB
Joshua 11 in the IRVG
Joshua 11 in the IRVH
Joshua 11 in the IRVK
Joshua 11 in the IRVM
Joshua 11 in the IRVM2
Joshua 11 in the IRVO
Joshua 11 in the IRVP
Joshua 11 in the IRVT
Joshua 11 in the IRVT2
Joshua 11 in the IRVU
Joshua 11 in the ISVN
Joshua 11 in the JSNT
Joshua 11 in the KAPI
Joshua 11 in the KBT1ETNIK
Joshua 11 in the KBV
Joshua 11 in the KJV
Joshua 11 in the KNFD
Joshua 11 in the LBA
Joshua 11 in the LBLA
Joshua 11 in the LNT
Joshua 11 in the LSV
Joshua 11 in the MAAL
Joshua 11 in the MBV
Joshua 11 in the MBV2
Joshua 11 in the MHNT
Joshua 11 in the MKNFD
Joshua 11 in the MNG
Joshua 11 in the MNT
Joshua 11 in the MNT2
Joshua 11 in the MRS1T
Joshua 11 in the NAA
Joshua 11 in the NASB
Joshua 11 in the NBLA
Joshua 11 in the NBS
Joshua 11 in the NBVTP
Joshua 11 in the NET2
Joshua 11 in the NIV11
Joshua 11 in the NNT
Joshua 11 in the NNT2
Joshua 11 in the NNT3
Joshua 11 in the PDDPT
Joshua 11 in the PFNT
Joshua 11 in the RMNT
Joshua 11 in the SBIAS
Joshua 11 in the SBIBS
Joshua 11 in the SBIBS2
Joshua 11 in the SBICS
Joshua 11 in the SBIDS
Joshua 11 in the SBIGS
Joshua 11 in the SBIHS
Joshua 11 in the SBIIS
Joshua 11 in the SBIIS2
Joshua 11 in the SBIIS3
Joshua 11 in the SBIKS
Joshua 11 in the SBIKS2
Joshua 11 in the SBIMS
Joshua 11 in the SBIOS
Joshua 11 in the SBIPS
Joshua 11 in the SBISS
Joshua 11 in the SBITS
Joshua 11 in the SBITS2
Joshua 11 in the SBITS3
Joshua 11 in the SBITS4
Joshua 11 in the SBIUS
Joshua 11 in the SBIVS
Joshua 11 in the SBT
Joshua 11 in the SBT1E
Joshua 11 in the SCHL
Joshua 11 in the SNT
Joshua 11 in the SUSU
Joshua 11 in the SUSU2
Joshua 11 in the SYNO
Joshua 11 in the TBIAOTANT
Joshua 11 in the TBT1E
Joshua 11 in the TBT1E2
Joshua 11 in the TFTIP
Joshua 11 in the TFTU
Joshua 11 in the TGNTATF3T
Joshua 11 in the THAI
Joshua 11 in the TNFD
Joshua 11 in the TNT
Joshua 11 in the TNTIK
Joshua 11 in the TNTIL
Joshua 11 in the TNTIN
Joshua 11 in the TNTIP
Joshua 11 in the TNTIZ
Joshua 11 in the TOMA
Joshua 11 in the TTENT
Joshua 11 in the UBG
Joshua 11 in the UGV
Joshua 11 in the UGV2
Joshua 11 in the UGV3
Joshua 11 in the VBL
Joshua 11 in the VDCC
Joshua 11 in the YALU
Joshua 11 in the YAPE
Joshua 11 in the YBVTP
Joshua 11 in the ZBP