Joshua 3 (BOYCB)
1 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sí kúrò ní Ṣittimu, wọ́n sì lọ sí etí odò Jordani, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá. 2 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta àwọn olórí la àárín ibùdó já. 3 Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí OLÚWA Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e. 4 Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárín yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́.” 5 Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, OLÚWA yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.” 6 Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn. 7 OLÚWA sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose. 8 Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jordani, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ” 9 Joṣua sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ súnmọ́ ibí kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. 10 Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín. 11 Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń gòkè lọ sí Jordani ṣáájú u yín. 12 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ọkùnrin méjìlá nínú àwọn ẹ̀yà Israẹli, ẹnìkan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. 13 Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí OLÚWA, Olúwa gbogbo ayé bá ti ẹsẹ̀ bọ odò Jordani, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbá jọ bí òkìtì kan.” 14 Nígbà tí àwọn ènìyàn gbéra láti ibùdó láti kọjá nínú odò Jordani, àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà ń lọ níwájú wọn. 15 Odò Jordani sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jordani tí ẹsẹ̀ wọn sì kan etí omi, 16 omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbá jọ bí òkìtì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Adamu, tí ó wà ní tòsí Saretani; nígbà tí omi tí ń sàn lọ sínú Òkun aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátápátá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdìkejì ní ìdojúkọ Jeriko. 17 Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárín Jordani, nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi rékọjá nínú odò Jordani lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
In Other Versions
Joshua 3 in the ANGEFD
Joshua 3 in the ANTPNG2D
Joshua 3 in the AS21
Joshua 3 in the BAGH
Joshua 3 in the BBPNG
Joshua 3 in the BBT1E
Joshua 3 in the BDS
Joshua 3 in the BEV
Joshua 3 in the BHAD
Joshua 3 in the BIB
Joshua 3 in the BLPT
Joshua 3 in the BNT
Joshua 3 in the BNTABOOT
Joshua 3 in the BNTLV
Joshua 3 in the BOATCB
Joshua 3 in the BOATCB2
Joshua 3 in the BOBCV
Joshua 3 in the BOCNT
Joshua 3 in the BOECS
Joshua 3 in the BOGWICC
Joshua 3 in the BOHCB
Joshua 3 in the BOHCV
Joshua 3 in the BOHLNT
Joshua 3 in the BOHNTLTAL
Joshua 3 in the BOICB
Joshua 3 in the BOILNTAP
Joshua 3 in the BOITCV
Joshua 3 in the BOKCV
Joshua 3 in the BOKCV2
Joshua 3 in the BOKHWOG
Joshua 3 in the BOKSSV
Joshua 3 in the BOLCB
Joshua 3 in the BOLCB2
Joshua 3 in the BOMCV
Joshua 3 in the BONAV
Joshua 3 in the BONCB
Joshua 3 in the BONLT
Joshua 3 in the BONUT2
Joshua 3 in the BOPLNT
Joshua 3 in the BOSCB
Joshua 3 in the BOSNC
Joshua 3 in the BOTLNT
Joshua 3 in the BOVCB
Joshua 3 in the BPBB
Joshua 3 in the BPH
Joshua 3 in the BSB
Joshua 3 in the CCB
Joshua 3 in the CUV
Joshua 3 in the CUVS
Joshua 3 in the DBT
Joshua 3 in the DGDNT
Joshua 3 in the DHNT
Joshua 3 in the DNT
Joshua 3 in the ELBE
Joshua 3 in the EMTV
Joshua 3 in the ESV
Joshua 3 in the FBV
Joshua 3 in the FEB
Joshua 3 in the GGMNT
Joshua 3 in the GNT
Joshua 3 in the HARY
Joshua 3 in the HNT
Joshua 3 in the IRVA
Joshua 3 in the IRVB
Joshua 3 in the IRVG
Joshua 3 in the IRVH
Joshua 3 in the IRVK
Joshua 3 in the IRVM
Joshua 3 in the IRVM2
Joshua 3 in the IRVO
Joshua 3 in the IRVP
Joshua 3 in the IRVT
Joshua 3 in the IRVT2
Joshua 3 in the IRVU
Joshua 3 in the ISVN
Joshua 3 in the JSNT
Joshua 3 in the KAPI
Joshua 3 in the KBT1ETNIK
Joshua 3 in the KBV
Joshua 3 in the KJV
Joshua 3 in the KNFD
Joshua 3 in the LBA
Joshua 3 in the LBLA
Joshua 3 in the LNT
Joshua 3 in the LSV
Joshua 3 in the MAAL
Joshua 3 in the MBV
Joshua 3 in the MBV2
Joshua 3 in the MHNT
Joshua 3 in the MKNFD
Joshua 3 in the MNG
Joshua 3 in the MNT
Joshua 3 in the MNT2
Joshua 3 in the MRS1T
Joshua 3 in the NAA
Joshua 3 in the NASB
Joshua 3 in the NBLA
Joshua 3 in the NBS
Joshua 3 in the NBVTP
Joshua 3 in the NET2
Joshua 3 in the NIV11
Joshua 3 in the NNT
Joshua 3 in the NNT2
Joshua 3 in the NNT3
Joshua 3 in the PDDPT
Joshua 3 in the PFNT
Joshua 3 in the RMNT
Joshua 3 in the SBIAS
Joshua 3 in the SBIBS
Joshua 3 in the SBIBS2
Joshua 3 in the SBICS
Joshua 3 in the SBIDS
Joshua 3 in the SBIGS
Joshua 3 in the SBIHS
Joshua 3 in the SBIIS
Joshua 3 in the SBIIS2
Joshua 3 in the SBIIS3
Joshua 3 in the SBIKS
Joshua 3 in the SBIKS2
Joshua 3 in the SBIMS
Joshua 3 in the SBIOS
Joshua 3 in the SBIPS
Joshua 3 in the SBISS
Joshua 3 in the SBITS
Joshua 3 in the SBITS2
Joshua 3 in the SBITS3
Joshua 3 in the SBITS4
Joshua 3 in the SBIUS
Joshua 3 in the SBIVS
Joshua 3 in the SBT
Joshua 3 in the SBT1E
Joshua 3 in the SCHL
Joshua 3 in the SNT
Joshua 3 in the SUSU
Joshua 3 in the SUSU2
Joshua 3 in the SYNO
Joshua 3 in the TBIAOTANT
Joshua 3 in the TBT1E
Joshua 3 in the TBT1E2
Joshua 3 in the TFTIP
Joshua 3 in the TFTU
Joshua 3 in the TGNTATF3T
Joshua 3 in the THAI
Joshua 3 in the TNFD
Joshua 3 in the TNT
Joshua 3 in the TNTIK
Joshua 3 in the TNTIL
Joshua 3 in the TNTIN
Joshua 3 in the TNTIP
Joshua 3 in the TNTIZ
Joshua 3 in the TOMA
Joshua 3 in the TTENT
Joshua 3 in the UBG
Joshua 3 in the UGV
Joshua 3 in the UGV2
Joshua 3 in the UGV3
Joshua 3 in the VBL
Joshua 3 in the VDCC
Joshua 3 in the YALU
Joshua 3 in the YAPE
Joshua 3 in the YBVTP
Joshua 3 in the ZBP