Leviticus 1 (BOYCB)
1 OLÚWA sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé, 2 “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún OLÚWA, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran. 3 “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLÚWA 4 kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un. 5 Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú OLÚWA, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká. 6 Òun yóò bó awọ ara ẹbọ sísun náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́. 7 Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà. 8 Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9 Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA. 10 “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11 kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú OLÚWA, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká. 12 Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 13 Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA. 14 “ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí OLÚWA, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé. 15 Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16 Kí ó yọ àjẹsí ẹyẹ náà pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, kí ó gbe lọ ṣí apá ìlà-oòrùn pẹpẹ níbi tí eérú wà. 17 Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má ya á tan pátápátá. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí OLÚWA.
In Other Versions
Leviticus 1 in the ANGEFD
Leviticus 1 in the ANTPNG2D
Leviticus 1 in the AS21
Leviticus 1 in the BAGH
Leviticus 1 in the BBPNG
Leviticus 1 in the BBT1E
Leviticus 1 in the BDS
Leviticus 1 in the BEV
Leviticus 1 in the BHAD
Leviticus 1 in the BIB
Leviticus 1 in the BLPT
Leviticus 1 in the BNT
Leviticus 1 in the BNTABOOT
Leviticus 1 in the BNTLV
Leviticus 1 in the BOATCB
Leviticus 1 in the BOATCB2
Leviticus 1 in the BOBCV
Leviticus 1 in the BOCNT
Leviticus 1 in the BOECS
Leviticus 1 in the BOGWICC
Leviticus 1 in the BOHCB
Leviticus 1 in the BOHCV
Leviticus 1 in the BOHLNT
Leviticus 1 in the BOHNTLTAL
Leviticus 1 in the BOICB
Leviticus 1 in the BOILNTAP
Leviticus 1 in the BOITCV
Leviticus 1 in the BOKCV
Leviticus 1 in the BOKCV2
Leviticus 1 in the BOKHWOG
Leviticus 1 in the BOKSSV
Leviticus 1 in the BOLCB
Leviticus 1 in the BOLCB2
Leviticus 1 in the BOMCV
Leviticus 1 in the BONAV
Leviticus 1 in the BONCB
Leviticus 1 in the BONLT
Leviticus 1 in the BONUT2
Leviticus 1 in the BOPLNT
Leviticus 1 in the BOSCB
Leviticus 1 in the BOSNC
Leviticus 1 in the BOTLNT
Leviticus 1 in the BOVCB
Leviticus 1 in the BPBB
Leviticus 1 in the BPH
Leviticus 1 in the BSB
Leviticus 1 in the CCB
Leviticus 1 in the CUV
Leviticus 1 in the CUVS
Leviticus 1 in the DBT
Leviticus 1 in the DGDNT
Leviticus 1 in the DHNT
Leviticus 1 in the DNT
Leviticus 1 in the ELBE
Leviticus 1 in the EMTV
Leviticus 1 in the ESV
Leviticus 1 in the FBV
Leviticus 1 in the FEB
Leviticus 1 in the GGMNT
Leviticus 1 in the GNT
Leviticus 1 in the HARY
Leviticus 1 in the HNT
Leviticus 1 in the IRVA
Leviticus 1 in the IRVB
Leviticus 1 in the IRVG
Leviticus 1 in the IRVH
Leviticus 1 in the IRVK
Leviticus 1 in the IRVM
Leviticus 1 in the IRVM2
Leviticus 1 in the IRVO
Leviticus 1 in the IRVP
Leviticus 1 in the IRVT
Leviticus 1 in the IRVT2
Leviticus 1 in the IRVU
Leviticus 1 in the ISVN
Leviticus 1 in the JSNT
Leviticus 1 in the KAPI
Leviticus 1 in the KBT1ETNIK
Leviticus 1 in the KBV
Leviticus 1 in the KJV
Leviticus 1 in the KNFD
Leviticus 1 in the LBA
Leviticus 1 in the LBLA
Leviticus 1 in the LNT
Leviticus 1 in the LSV
Leviticus 1 in the MAAL
Leviticus 1 in the MBV
Leviticus 1 in the MBV2
Leviticus 1 in the MHNT
Leviticus 1 in the MKNFD
Leviticus 1 in the MNG
Leviticus 1 in the MNT
Leviticus 1 in the MNT2
Leviticus 1 in the MRS1T
Leviticus 1 in the NAA
Leviticus 1 in the NASB
Leviticus 1 in the NBLA
Leviticus 1 in the NBS
Leviticus 1 in the NBVTP
Leviticus 1 in the NET2
Leviticus 1 in the NIV11
Leviticus 1 in the NNT
Leviticus 1 in the NNT2
Leviticus 1 in the NNT3
Leviticus 1 in the PDDPT
Leviticus 1 in the PFNT
Leviticus 1 in the RMNT
Leviticus 1 in the SBIAS
Leviticus 1 in the SBIBS
Leviticus 1 in the SBIBS2
Leviticus 1 in the SBICS
Leviticus 1 in the SBIDS
Leviticus 1 in the SBIGS
Leviticus 1 in the SBIHS
Leviticus 1 in the SBIIS
Leviticus 1 in the SBIIS2
Leviticus 1 in the SBIIS3
Leviticus 1 in the SBIKS
Leviticus 1 in the SBIKS2
Leviticus 1 in the SBIMS
Leviticus 1 in the SBIOS
Leviticus 1 in the SBIPS
Leviticus 1 in the SBISS
Leviticus 1 in the SBITS
Leviticus 1 in the SBITS2
Leviticus 1 in the SBITS3
Leviticus 1 in the SBITS4
Leviticus 1 in the SBIUS
Leviticus 1 in the SBIVS
Leviticus 1 in the SBT
Leviticus 1 in the SBT1E
Leviticus 1 in the SCHL
Leviticus 1 in the SNT
Leviticus 1 in the SUSU
Leviticus 1 in the SUSU2
Leviticus 1 in the SYNO
Leviticus 1 in the TBIAOTANT
Leviticus 1 in the TBT1E
Leviticus 1 in the TBT1E2
Leviticus 1 in the TFTIP
Leviticus 1 in the TFTU
Leviticus 1 in the TGNTATF3T
Leviticus 1 in the THAI
Leviticus 1 in the TNFD
Leviticus 1 in the TNT
Leviticus 1 in the TNTIK
Leviticus 1 in the TNTIL
Leviticus 1 in the TNTIN
Leviticus 1 in the TNTIP
Leviticus 1 in the TNTIZ
Leviticus 1 in the TOMA
Leviticus 1 in the TTENT
Leviticus 1 in the UBG
Leviticus 1 in the UGV
Leviticus 1 in the UGV2
Leviticus 1 in the UGV3
Leviticus 1 in the VBL
Leviticus 1 in the VDCC
Leviticus 1 in the YALU
Leviticus 1 in the YAPE
Leviticus 1 in the YBVTP
Leviticus 1 in the ZBP