Leviticus 9 (BOYCB)
1 Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Israẹli. 2 Ó sọ fún Aaroni pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú OLÚWA. 3 Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun, 4 àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú OLÚWA. Nítorí pé OLÚWA yóò farahàn yín ní òní.’ ” 5 Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú OLÚWA. 6 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo OLÚWA bá à lè farahàn yín.” 7 Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ.” 8 Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. 9 Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 10 Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mose. 11 Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó. 12 Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 13 Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 14 Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ. 15 Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́. 16 Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀. 17 Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀. 18 Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 19 Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀: 20 gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ. 21 Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ. 22 Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀. 23 Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo OLÚWA sì farahàn sí gbogbo ènìyàn. 24 Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.
In Other Versions
Leviticus 9 in the ANGEFD
Leviticus 9 in the ANTPNG2D
Leviticus 9 in the AS21
Leviticus 9 in the BAGH
Leviticus 9 in the BBPNG
Leviticus 9 in the BBT1E
Leviticus 9 in the BDS
Leviticus 9 in the BEV
Leviticus 9 in the BHAD
Leviticus 9 in the BIB
Leviticus 9 in the BLPT
Leviticus 9 in the BNT
Leviticus 9 in the BNTABOOT
Leviticus 9 in the BNTLV
Leviticus 9 in the BOATCB
Leviticus 9 in the BOATCB2
Leviticus 9 in the BOBCV
Leviticus 9 in the BOCNT
Leviticus 9 in the BOECS
Leviticus 9 in the BOGWICC
Leviticus 9 in the BOHCB
Leviticus 9 in the BOHCV
Leviticus 9 in the BOHLNT
Leviticus 9 in the BOHNTLTAL
Leviticus 9 in the BOICB
Leviticus 9 in the BOILNTAP
Leviticus 9 in the BOITCV
Leviticus 9 in the BOKCV
Leviticus 9 in the BOKCV2
Leviticus 9 in the BOKHWOG
Leviticus 9 in the BOKSSV
Leviticus 9 in the BOLCB
Leviticus 9 in the BOLCB2
Leviticus 9 in the BOMCV
Leviticus 9 in the BONAV
Leviticus 9 in the BONCB
Leviticus 9 in the BONLT
Leviticus 9 in the BONUT2
Leviticus 9 in the BOPLNT
Leviticus 9 in the BOSCB
Leviticus 9 in the BOSNC
Leviticus 9 in the BOTLNT
Leviticus 9 in the BOVCB
Leviticus 9 in the BPBB
Leviticus 9 in the BPH
Leviticus 9 in the BSB
Leviticus 9 in the CCB
Leviticus 9 in the CUV
Leviticus 9 in the CUVS
Leviticus 9 in the DBT
Leviticus 9 in the DGDNT
Leviticus 9 in the DHNT
Leviticus 9 in the DNT
Leviticus 9 in the ELBE
Leviticus 9 in the EMTV
Leviticus 9 in the ESV
Leviticus 9 in the FBV
Leviticus 9 in the FEB
Leviticus 9 in the GGMNT
Leviticus 9 in the GNT
Leviticus 9 in the HARY
Leviticus 9 in the HNT
Leviticus 9 in the IRVA
Leviticus 9 in the IRVB
Leviticus 9 in the IRVG
Leviticus 9 in the IRVH
Leviticus 9 in the IRVK
Leviticus 9 in the IRVM
Leviticus 9 in the IRVM2
Leviticus 9 in the IRVO
Leviticus 9 in the IRVP
Leviticus 9 in the IRVT
Leviticus 9 in the IRVT2
Leviticus 9 in the IRVU
Leviticus 9 in the ISVN
Leviticus 9 in the JSNT
Leviticus 9 in the KAPI
Leviticus 9 in the KBT1ETNIK
Leviticus 9 in the KBV
Leviticus 9 in the KJV
Leviticus 9 in the KNFD
Leviticus 9 in the LBA
Leviticus 9 in the LBLA
Leviticus 9 in the LNT
Leviticus 9 in the LSV
Leviticus 9 in the MAAL
Leviticus 9 in the MBV
Leviticus 9 in the MBV2
Leviticus 9 in the MHNT
Leviticus 9 in the MKNFD
Leviticus 9 in the MNG
Leviticus 9 in the MNT
Leviticus 9 in the MNT2
Leviticus 9 in the MRS1T
Leviticus 9 in the NAA
Leviticus 9 in the NASB
Leviticus 9 in the NBLA
Leviticus 9 in the NBS
Leviticus 9 in the NBVTP
Leviticus 9 in the NET2
Leviticus 9 in the NIV11
Leviticus 9 in the NNT
Leviticus 9 in the NNT2
Leviticus 9 in the NNT3
Leviticus 9 in the PDDPT
Leviticus 9 in the PFNT
Leviticus 9 in the RMNT
Leviticus 9 in the SBIAS
Leviticus 9 in the SBIBS
Leviticus 9 in the SBIBS2
Leviticus 9 in the SBICS
Leviticus 9 in the SBIDS
Leviticus 9 in the SBIGS
Leviticus 9 in the SBIHS
Leviticus 9 in the SBIIS
Leviticus 9 in the SBIIS2
Leviticus 9 in the SBIIS3
Leviticus 9 in the SBIKS
Leviticus 9 in the SBIKS2
Leviticus 9 in the SBIMS
Leviticus 9 in the SBIOS
Leviticus 9 in the SBIPS
Leviticus 9 in the SBISS
Leviticus 9 in the SBITS
Leviticus 9 in the SBITS2
Leviticus 9 in the SBITS3
Leviticus 9 in the SBITS4
Leviticus 9 in the SBIUS
Leviticus 9 in the SBIVS
Leviticus 9 in the SBT
Leviticus 9 in the SBT1E
Leviticus 9 in the SCHL
Leviticus 9 in the SNT
Leviticus 9 in the SUSU
Leviticus 9 in the SUSU2
Leviticus 9 in the SYNO
Leviticus 9 in the TBIAOTANT
Leviticus 9 in the TBT1E
Leviticus 9 in the TBT1E2
Leviticus 9 in the TFTIP
Leviticus 9 in the TFTU
Leviticus 9 in the TGNTATF3T
Leviticus 9 in the THAI
Leviticus 9 in the TNFD
Leviticus 9 in the TNT
Leviticus 9 in the TNTIK
Leviticus 9 in the TNTIL
Leviticus 9 in the TNTIN
Leviticus 9 in the TNTIP
Leviticus 9 in the TNTIZ
Leviticus 9 in the TOMA
Leviticus 9 in the TTENT
Leviticus 9 in the UBG
Leviticus 9 in the UGV
Leviticus 9 in the UGV2
Leviticus 9 in the UGV3
Leviticus 9 in the VBL
Leviticus 9 in the VDCC
Leviticus 9 in the YALU
Leviticus 9 in the YAPE
Leviticus 9 in the YBVTP
Leviticus 9 in the ZBP