Luke 14 (BOYCB)

1 Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ. 2 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí ó ní ara wíwú níwájú rẹ̀. 3 Jesu sì dáhùn ó wí fún àwọn amòfin àti àwọn Farisi pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, tàbí kò tọ́?” 4 Wọ́n sì dákẹ́. Ó sì mú un, ó mú un láradá, ó sì jẹ́ kí ó lọ. 5 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù rẹ̀ yóò bọ́ sínú ihò, tí kì yóò sì fà á sókè lójúkan náà ní ọjọ́ ìsinmi?” 6 Wọn kò sì lè dá a lóhùn mọ́ sí nǹkan wọ̀nyí. 7 Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé, 8 “Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. 9 Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn. 10 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ. 11 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.” 12 Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ, ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.” 15 Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jókòó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó wí fún Jesu pé, “Alábùkún ni fún ẹni tí yóò jẹ oúnjẹ àsè ní ìjọba Ọlọ́run!” 16 Jesu dá a lóhùn pé, “Ọkùnrin kan ṣe àsè alẹ́ ńlá, ó sì pe ènìyàn púpọ̀. 17 Ó sì rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní wákàtí àsè alẹ́ náà láti sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Ẹ wá; nítorí ohun gbogbo ṣetán!’ 18 “Gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí ohun kan. ‘Èkínní wí fún un pé, mo ra ilẹ̀ kan, mo sì fẹ́ lọ wò ó wò, mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ 19 “Èkejì sì wí pé, ‘Mo ra àjàgà màlúù márùn-ún, mo sì ń lọ wò wọ́n wò: mo bẹ̀ ọ́ ṣe gáfárà fún mi.’ 20 “Ẹ̀kẹta sì wí pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, nítorí náà ni èmi kò fi lè wá.’ 21 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì padà dé, ó sọ nǹkan wọ̀nyí fún olúwa rẹ̀. Nígbà náà ni baálé ilé bínú, ó wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Jáde lọ sí ìgboro, àti sí òpópó ọ̀nà, kí o sì mú àwọn tálákà, àti àwọn amúnkùn ún, àti àwọn arọ, àti àwọn afọ́jú wá sí ìhín yìí.’ 22 “Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wí pé, ‘Olúwa a ti ṣe bí o ti pàṣẹ, ààyè sì ń bẹ síbẹ̀.’ 23 “Olúwa náà sì wí fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà pé, ‘Jáde lọ sí òpópó, àti sí ọ̀nà ọgbà, kí o sì rọ̀ wọ́n láti wọlé wá, kí ilé mi lè kún. 24 Nítorí mo wí fún yín, ẹnikẹ́ni nínú àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí a ti pè, kì yóò tọ́wò nínú àsè ńlá mi!’ ” 25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, 26 “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 27 Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 28 “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29 Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30 Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’ 31 “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) pàdé ẹni tí ń mú ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bọ̀ wá ko òun lójú? 32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà. 33 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 34 “Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kín ni a ó fi mú un dùn? 35 Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”

In Other Versions

Luke 14 in the ANGEFD

Luke 14 in the ANTPNG2D

Luke 14 in the AS21

Luke 14 in the BAGH

Luke 14 in the BBPNG

Luke 14 in the BBT1E

Luke 14 in the BDS

Luke 14 in the BEV

Luke 14 in the BHAD

Luke 14 in the BIB

Luke 14 in the BLPT

Luke 14 in the BNT

Luke 14 in the BNTABOOT

Luke 14 in the BNTLV

Luke 14 in the BOATCB

Luke 14 in the BOATCB2

Luke 14 in the BOBCV

Luke 14 in the BOCNT

Luke 14 in the BOECS

Luke 14 in the BOGWICC

Luke 14 in the BOHCB

Luke 14 in the BOHCV

Luke 14 in the BOHLNT

Luke 14 in the BOHNTLTAL

Luke 14 in the BOICB

Luke 14 in the BOILNTAP

Luke 14 in the BOITCV

Luke 14 in the BOKCV

Luke 14 in the BOKCV2

Luke 14 in the BOKHWOG

Luke 14 in the BOKSSV

Luke 14 in the BOLCB

Luke 14 in the BOLCB2

Luke 14 in the BOMCV

Luke 14 in the BONAV

Luke 14 in the BONCB

Luke 14 in the BONLT

Luke 14 in the BONUT2

Luke 14 in the BOPLNT

Luke 14 in the BOSCB

Luke 14 in the BOSNC

Luke 14 in the BOTLNT

Luke 14 in the BOVCB

Luke 14 in the BPBB

Luke 14 in the BPH

Luke 14 in the BSB

Luke 14 in the CCB

Luke 14 in the CUV

Luke 14 in the CUVS

Luke 14 in the DBT

Luke 14 in the DGDNT

Luke 14 in the DHNT

Luke 14 in the DNT

Luke 14 in the ELBE

Luke 14 in the EMTV

Luke 14 in the ESV

Luke 14 in the FBV

Luke 14 in the FEB

Luke 14 in the GGMNT

Luke 14 in the GNT

Luke 14 in the HARY

Luke 14 in the HNT

Luke 14 in the IRVA

Luke 14 in the IRVB

Luke 14 in the IRVG

Luke 14 in the IRVH

Luke 14 in the IRVK

Luke 14 in the IRVM

Luke 14 in the IRVM2

Luke 14 in the IRVO

Luke 14 in the IRVP

Luke 14 in the IRVT

Luke 14 in the IRVT2

Luke 14 in the IRVU

Luke 14 in the ISVN

Luke 14 in the JSNT

Luke 14 in the KAPI

Luke 14 in the KBT1ETNIK

Luke 14 in the KBV

Luke 14 in the KJV

Luke 14 in the KNFD

Luke 14 in the LBA

Luke 14 in the LBLA

Luke 14 in the LNT

Luke 14 in the LSV

Luke 14 in the MAAL

Luke 14 in the MBV

Luke 14 in the MBV2

Luke 14 in the MHNT

Luke 14 in the MKNFD

Luke 14 in the MNG

Luke 14 in the MNT

Luke 14 in the MNT2

Luke 14 in the MRS1T

Luke 14 in the NAA

Luke 14 in the NASB

Luke 14 in the NBLA

Luke 14 in the NBS

Luke 14 in the NBVTP

Luke 14 in the NET2

Luke 14 in the NIV11

Luke 14 in the NNT

Luke 14 in the NNT2

Luke 14 in the NNT3

Luke 14 in the PDDPT

Luke 14 in the PFNT

Luke 14 in the RMNT

Luke 14 in the SBIAS

Luke 14 in the SBIBS

Luke 14 in the SBIBS2

Luke 14 in the SBICS

Luke 14 in the SBIDS

Luke 14 in the SBIGS

Luke 14 in the SBIHS

Luke 14 in the SBIIS

Luke 14 in the SBIIS2

Luke 14 in the SBIIS3

Luke 14 in the SBIKS

Luke 14 in the SBIKS2

Luke 14 in the SBIMS

Luke 14 in the SBIOS

Luke 14 in the SBIPS

Luke 14 in the SBISS

Luke 14 in the SBITS

Luke 14 in the SBITS2

Luke 14 in the SBITS3

Luke 14 in the SBITS4

Luke 14 in the SBIUS

Luke 14 in the SBIVS

Luke 14 in the SBT

Luke 14 in the SBT1E

Luke 14 in the SCHL

Luke 14 in the SNT

Luke 14 in the SUSU

Luke 14 in the SUSU2

Luke 14 in the SYNO

Luke 14 in the TBIAOTANT

Luke 14 in the TBT1E

Luke 14 in the TBT1E2

Luke 14 in the TFTIP

Luke 14 in the TFTU

Luke 14 in the TGNTATF3T

Luke 14 in the THAI

Luke 14 in the TNFD

Luke 14 in the TNT

Luke 14 in the TNTIK

Luke 14 in the TNTIL

Luke 14 in the TNTIN

Luke 14 in the TNTIP

Luke 14 in the TNTIZ

Luke 14 in the TOMA

Luke 14 in the TTENT

Luke 14 in the UBG

Luke 14 in the UGV

Luke 14 in the UGV2

Luke 14 in the UGV3

Luke 14 in the VBL

Luke 14 in the VDCC

Luke 14 in the YALU

Luke 14 in the YAPE

Luke 14 in the YBVTP

Luke 14 in the ZBP