Matthew 4 (BOYCB)

1 Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. 2 Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. 3 Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.” 4 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ” 5 Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 6 Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé,“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹwọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọnkí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ” 7 Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” 8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.” 10 Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ” 11 Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un. 12 Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 13 Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14 Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé, 15 “Ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftaliọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,Galili ti àwọn kèfèrí. 16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùntí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikúni ìmọ́lẹ̀ tan fún.” 17 Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” 18 Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20 Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 21 Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22 Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 23 Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

In Other Versions

Matthew 4 in the ANGEFD

Matthew 4 in the ANTPNG2D

Matthew 4 in the AS21

Matthew 4 in the BAGH

Matthew 4 in the BBPNG

Matthew 4 in the BBT1E

Matthew 4 in the BDS

Matthew 4 in the BEV

Matthew 4 in the BHAD

Matthew 4 in the BIB

Matthew 4 in the BLPT

Matthew 4 in the BNT

Matthew 4 in the BNTABOOT

Matthew 4 in the BNTLV

Matthew 4 in the BOATCB

Matthew 4 in the BOATCB2

Matthew 4 in the BOBCV

Matthew 4 in the BOCNT

Matthew 4 in the BOECS

Matthew 4 in the BOGWICC

Matthew 4 in the BOHCB

Matthew 4 in the BOHCV

Matthew 4 in the BOHLNT

Matthew 4 in the BOHNTLTAL

Matthew 4 in the BOICB

Matthew 4 in the BOILNTAP

Matthew 4 in the BOITCV

Matthew 4 in the BOKCV

Matthew 4 in the BOKCV2

Matthew 4 in the BOKHWOG

Matthew 4 in the BOKSSV

Matthew 4 in the BOLCB

Matthew 4 in the BOLCB2

Matthew 4 in the BOMCV

Matthew 4 in the BONAV

Matthew 4 in the BONCB

Matthew 4 in the BONLT

Matthew 4 in the BONUT2

Matthew 4 in the BOPLNT

Matthew 4 in the BOSCB

Matthew 4 in the BOSNC

Matthew 4 in the BOTLNT

Matthew 4 in the BOVCB

Matthew 4 in the BPBB

Matthew 4 in the BPH

Matthew 4 in the BSB

Matthew 4 in the CCB

Matthew 4 in the CUV

Matthew 4 in the CUVS

Matthew 4 in the DBT

Matthew 4 in the DGDNT

Matthew 4 in the DHNT

Matthew 4 in the DNT

Matthew 4 in the ELBE

Matthew 4 in the EMTV

Matthew 4 in the ESV

Matthew 4 in the FBV

Matthew 4 in the FEB

Matthew 4 in the GGMNT

Matthew 4 in the GNT

Matthew 4 in the HARY

Matthew 4 in the HNT

Matthew 4 in the IRVA

Matthew 4 in the IRVB

Matthew 4 in the IRVG

Matthew 4 in the IRVH

Matthew 4 in the IRVK

Matthew 4 in the IRVM

Matthew 4 in the IRVM2

Matthew 4 in the IRVO

Matthew 4 in the IRVP

Matthew 4 in the IRVT

Matthew 4 in the IRVT2

Matthew 4 in the IRVU

Matthew 4 in the ISVN

Matthew 4 in the JSNT

Matthew 4 in the KAPI

Matthew 4 in the KBT1ETNIK

Matthew 4 in the KBV

Matthew 4 in the KJV

Matthew 4 in the KNFD

Matthew 4 in the LBA

Matthew 4 in the LBLA

Matthew 4 in the LNT

Matthew 4 in the LSV

Matthew 4 in the MAAL

Matthew 4 in the MBV

Matthew 4 in the MBV2

Matthew 4 in the MHNT

Matthew 4 in the MKNFD

Matthew 4 in the MNG

Matthew 4 in the MNT

Matthew 4 in the MNT2

Matthew 4 in the MRS1T

Matthew 4 in the NAA

Matthew 4 in the NASB

Matthew 4 in the NBLA

Matthew 4 in the NBS

Matthew 4 in the NBVTP

Matthew 4 in the NET2

Matthew 4 in the NIV11

Matthew 4 in the NNT

Matthew 4 in the NNT2

Matthew 4 in the NNT3

Matthew 4 in the PDDPT

Matthew 4 in the PFNT

Matthew 4 in the RMNT

Matthew 4 in the SBIAS

Matthew 4 in the SBIBS

Matthew 4 in the SBIBS2

Matthew 4 in the SBICS

Matthew 4 in the SBIDS

Matthew 4 in the SBIGS

Matthew 4 in the SBIHS

Matthew 4 in the SBIIS

Matthew 4 in the SBIIS2

Matthew 4 in the SBIIS3

Matthew 4 in the SBIKS

Matthew 4 in the SBIKS2

Matthew 4 in the SBIMS

Matthew 4 in the SBIOS

Matthew 4 in the SBIPS

Matthew 4 in the SBISS

Matthew 4 in the SBITS

Matthew 4 in the SBITS2

Matthew 4 in the SBITS3

Matthew 4 in the SBITS4

Matthew 4 in the SBIUS

Matthew 4 in the SBIVS

Matthew 4 in the SBT

Matthew 4 in the SBT1E

Matthew 4 in the SCHL

Matthew 4 in the SNT

Matthew 4 in the SUSU

Matthew 4 in the SUSU2

Matthew 4 in the SYNO

Matthew 4 in the TBIAOTANT

Matthew 4 in the TBT1E

Matthew 4 in the TBT1E2

Matthew 4 in the TFTIP

Matthew 4 in the TFTU

Matthew 4 in the TGNTATF3T

Matthew 4 in the THAI

Matthew 4 in the TNFD

Matthew 4 in the TNT

Matthew 4 in the TNTIK

Matthew 4 in the TNTIL

Matthew 4 in the TNTIN

Matthew 4 in the TNTIP

Matthew 4 in the TNTIZ

Matthew 4 in the TOMA

Matthew 4 in the TTENT

Matthew 4 in the UBG

Matthew 4 in the UGV

Matthew 4 in the UGV2

Matthew 4 in the UGV3

Matthew 4 in the VBL

Matthew 4 in the VDCC

Matthew 4 in the YALU

Matthew 4 in the YAPE

Matthew 4 in the YBVTP

Matthew 4 in the ZBP