Micah 5 (BOYCB)

1 Nísinsin yìí, kó àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ jọ,ìwọ ìlú ti o ni ọmọ-ogun,nítorí ó ti fi gbógun dó tì wá.Wọn yóò fi ọ̀pá lu àwọn alákòóso Israẹli ní ẹ̀rẹ̀kẹ́. 2 “Ṣùgbọ́n ìwọ, Bẹtilẹhẹmu Efrata,bí ìwọ ti jẹ́ kékeré láàrín àwọn ẹ̀yà Juda,nínú rẹ ni ẹni tí yóò jẹ́ olórí ní Israẹliyóò ti jáde tọ̀ mí wá,ìjáde lọ rẹ̀ sì jẹ́ láti ìgbà àtijọ́,láti ìgbà láéláé.” 3 Nítorí náà Israẹli yóò di kíkọ̀sílẹ̀ pátápátátítí di àkókò tí ẹni tí ń rọbí yóò fi bí,àti àwọn ìyókù arákùnrin rẹ̀ yóò fi padàláti darapọ̀ mọ́ àwọn Israẹli. 4 Òun yóò sì dúró,yóò sì máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo ẹran rẹ̀ ní agbára OLÚWA,ní ọláńlá orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀.Wọn yóò sì wà láìléwu,nítorí nísinsin yìí ni títóbi rẹyóò sì dé òpin ayé. 5 Òun yóò sì jẹ́ àlàáfíà wọn.Nígbà tí àwọn Asiria bá gbógun sí ilẹ̀ watí wọ́n sì ń yan lórí odi alágbára wa,nígbà náà ni a ó gbé olùṣọ́-àgùntàn méje dìde sí i,àti olórí ènìyàn mẹ́jọ. 6 Wọn yóò sì fi idà pa ilẹ̀ Asiria run,àti ilẹ̀ Nimrodu pẹ̀lú idà tí a fà.Òun yóò sì gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Asirianígbà tí wọn bá gbógun ti ilẹ̀ watí wọ́n sì tún yan wọ ẹnu-bodè wa. 7 Ìyókù Jakọbu yóò sì wàláàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyànbí ìrì láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wa,bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko,tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàntàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn. 8 Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlàní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn,bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó,bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn,èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là. 9 A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀,gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun. 10 “Ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí,“Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹèmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run. 11 Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run,èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya. 12 Èmi yóò gé ìwà àjẹ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,ìwọ kì yóò sì ní aláfọ̀ṣẹ mọ́. 13 Èmi yóò pa àwọn ère fínfín rẹ̀ run,àti ọwọ̀n rẹ̀ kúrò láàrín rẹ̀;ìwọ kì yóò sì le è foríbalẹ̀fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́. 14 Èmi yóò fa ère Aṣerah tu kúrò láàrín rẹ̀,èmi yóò sì pa ìlú ńlá rẹ̀ run. 15 Èmi yóò gbẹ̀san ní ìbínú àti ìrunúlórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti tẹríba fún mi.”

In Other Versions

Micah 5 in the ANGEFD

Micah 5 in the ANTPNG2D

Micah 5 in the AS21

Micah 5 in the BAGH

Micah 5 in the BBPNG

Micah 5 in the BBT1E

Micah 5 in the BDS

Micah 5 in the BEV

Micah 5 in the BHAD

Micah 5 in the BIB

Micah 5 in the BLPT

Micah 5 in the BNT

Micah 5 in the BNTABOOT

Micah 5 in the BNTLV

Micah 5 in the BOATCB

Micah 5 in the BOATCB2

Micah 5 in the BOBCV

Micah 5 in the BOCNT

Micah 5 in the BOECS

Micah 5 in the BOGWICC

Micah 5 in the BOHCB

Micah 5 in the BOHCV

Micah 5 in the BOHLNT

Micah 5 in the BOHNTLTAL

Micah 5 in the BOICB

Micah 5 in the BOILNTAP

Micah 5 in the BOITCV

Micah 5 in the BOKCV

Micah 5 in the BOKCV2

Micah 5 in the BOKHWOG

Micah 5 in the BOKSSV

Micah 5 in the BOLCB

Micah 5 in the BOLCB2

Micah 5 in the BOMCV

Micah 5 in the BONAV

Micah 5 in the BONCB

Micah 5 in the BONLT

Micah 5 in the BONUT2

Micah 5 in the BOPLNT

Micah 5 in the BOSCB

Micah 5 in the BOSNC

Micah 5 in the BOTLNT

Micah 5 in the BOVCB

Micah 5 in the BPBB

Micah 5 in the BPH

Micah 5 in the BSB

Micah 5 in the CCB

Micah 5 in the CUV

Micah 5 in the CUVS

Micah 5 in the DBT

Micah 5 in the DGDNT

Micah 5 in the DHNT

Micah 5 in the DNT

Micah 5 in the ELBE

Micah 5 in the EMTV

Micah 5 in the ESV

Micah 5 in the FBV

Micah 5 in the FEB

Micah 5 in the GGMNT

Micah 5 in the GNT

Micah 5 in the HARY

Micah 5 in the HNT

Micah 5 in the IRVA

Micah 5 in the IRVB

Micah 5 in the IRVG

Micah 5 in the IRVH

Micah 5 in the IRVK

Micah 5 in the IRVM

Micah 5 in the IRVM2

Micah 5 in the IRVO

Micah 5 in the IRVP

Micah 5 in the IRVT

Micah 5 in the IRVT2

Micah 5 in the IRVU

Micah 5 in the ISVN

Micah 5 in the JSNT

Micah 5 in the KAPI

Micah 5 in the KBT1ETNIK

Micah 5 in the KBV

Micah 5 in the KJV

Micah 5 in the KNFD

Micah 5 in the LBA

Micah 5 in the LBLA

Micah 5 in the LNT

Micah 5 in the LSV

Micah 5 in the MAAL

Micah 5 in the MBV

Micah 5 in the MBV2

Micah 5 in the MHNT

Micah 5 in the MKNFD

Micah 5 in the MNG

Micah 5 in the MNT

Micah 5 in the MNT2

Micah 5 in the MRS1T

Micah 5 in the NAA

Micah 5 in the NASB

Micah 5 in the NBLA

Micah 5 in the NBS

Micah 5 in the NBVTP

Micah 5 in the NET2

Micah 5 in the NIV11

Micah 5 in the NNT

Micah 5 in the NNT2

Micah 5 in the NNT3

Micah 5 in the PDDPT

Micah 5 in the PFNT

Micah 5 in the RMNT

Micah 5 in the SBIAS

Micah 5 in the SBIBS

Micah 5 in the SBIBS2

Micah 5 in the SBICS

Micah 5 in the SBIDS

Micah 5 in the SBIGS

Micah 5 in the SBIHS

Micah 5 in the SBIIS

Micah 5 in the SBIIS2

Micah 5 in the SBIIS3

Micah 5 in the SBIKS

Micah 5 in the SBIKS2

Micah 5 in the SBIMS

Micah 5 in the SBIOS

Micah 5 in the SBIPS

Micah 5 in the SBISS

Micah 5 in the SBITS

Micah 5 in the SBITS2

Micah 5 in the SBITS3

Micah 5 in the SBITS4

Micah 5 in the SBIUS

Micah 5 in the SBIVS

Micah 5 in the SBT

Micah 5 in the SBT1E

Micah 5 in the SCHL

Micah 5 in the SNT

Micah 5 in the SUSU

Micah 5 in the SUSU2

Micah 5 in the SYNO

Micah 5 in the TBIAOTANT

Micah 5 in the TBT1E

Micah 5 in the TBT1E2

Micah 5 in the TFTIP

Micah 5 in the TFTU

Micah 5 in the TGNTATF3T

Micah 5 in the THAI

Micah 5 in the TNFD

Micah 5 in the TNT

Micah 5 in the TNTIK

Micah 5 in the TNTIL

Micah 5 in the TNTIN

Micah 5 in the TNTIP

Micah 5 in the TNTIZ

Micah 5 in the TOMA

Micah 5 in the TTENT

Micah 5 in the UBG

Micah 5 in the UGV

Micah 5 in the UGV2

Micah 5 in the UGV3

Micah 5 in the VBL

Micah 5 in the VDCC

Micah 5 in the YALU

Micah 5 in the YAPE

Micah 5 in the YBVTP

Micah 5 in the ZBP