Nehemiah 2 (BOYCB)
1 Ní oṣù Nisani, ní ogún ọdún ìjọba ọba Artasasta, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún un, mo gbé wáìnì náà, mo fi fún ọba, ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájú rẹ̀. 2 Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn.”Ẹ̀rù bà mí gidigidi, 3 ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Èéṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?” 4 Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, 5 mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Juda níbi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.” 6 Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan. 7 Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu. 8 Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi. 9 Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi. 10 Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi. 11 Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 12 Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn. 13 Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun. 14 Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá; 15 bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì. 16 Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà. 17 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. 18 Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi.Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí. 19 Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?” 20 Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”
In Other Versions
Nehemiah 2 in the ANGEFD
Nehemiah 2 in the ANTPNG2D
Nehemiah 2 in the AS21
Nehemiah 2 in the BAGH
Nehemiah 2 in the BBPNG
Nehemiah 2 in the BBT1E
Nehemiah 2 in the BDS
Nehemiah 2 in the BEV
Nehemiah 2 in the BHAD
Nehemiah 2 in the BIB
Nehemiah 2 in the BLPT
Nehemiah 2 in the BNT
Nehemiah 2 in the BNTABOOT
Nehemiah 2 in the BNTLV
Nehemiah 2 in the BOATCB
Nehemiah 2 in the BOATCB2
Nehemiah 2 in the BOBCV
Nehemiah 2 in the BOCNT
Nehemiah 2 in the BOECS
Nehemiah 2 in the BOGWICC
Nehemiah 2 in the BOHCB
Nehemiah 2 in the BOHCV
Nehemiah 2 in the BOHLNT
Nehemiah 2 in the BOHNTLTAL
Nehemiah 2 in the BOICB
Nehemiah 2 in the BOILNTAP
Nehemiah 2 in the BOITCV
Nehemiah 2 in the BOKCV
Nehemiah 2 in the BOKCV2
Nehemiah 2 in the BOKHWOG
Nehemiah 2 in the BOKSSV
Nehemiah 2 in the BOLCB
Nehemiah 2 in the BOLCB2
Nehemiah 2 in the BOMCV
Nehemiah 2 in the BONAV
Nehemiah 2 in the BONCB
Nehemiah 2 in the BONLT
Nehemiah 2 in the BONUT2
Nehemiah 2 in the BOPLNT
Nehemiah 2 in the BOSCB
Nehemiah 2 in the BOSNC
Nehemiah 2 in the BOTLNT
Nehemiah 2 in the BOVCB
Nehemiah 2 in the BPBB
Nehemiah 2 in the BPH
Nehemiah 2 in the BSB
Nehemiah 2 in the CCB
Nehemiah 2 in the CUV
Nehemiah 2 in the CUVS
Nehemiah 2 in the DBT
Nehemiah 2 in the DGDNT
Nehemiah 2 in the DHNT
Nehemiah 2 in the DNT
Nehemiah 2 in the ELBE
Nehemiah 2 in the EMTV
Nehemiah 2 in the ESV
Nehemiah 2 in the FBV
Nehemiah 2 in the FEB
Nehemiah 2 in the GGMNT
Nehemiah 2 in the GNT
Nehemiah 2 in the HARY
Nehemiah 2 in the HNT
Nehemiah 2 in the IRVA
Nehemiah 2 in the IRVB
Nehemiah 2 in the IRVG
Nehemiah 2 in the IRVH
Nehemiah 2 in the IRVK
Nehemiah 2 in the IRVM
Nehemiah 2 in the IRVM2
Nehemiah 2 in the IRVO
Nehemiah 2 in the IRVP
Nehemiah 2 in the IRVT
Nehemiah 2 in the IRVT2
Nehemiah 2 in the IRVU
Nehemiah 2 in the ISVN
Nehemiah 2 in the JSNT
Nehemiah 2 in the KAPI
Nehemiah 2 in the KBT1ETNIK
Nehemiah 2 in the KBV
Nehemiah 2 in the KJV
Nehemiah 2 in the KNFD
Nehemiah 2 in the LBA
Nehemiah 2 in the LBLA
Nehemiah 2 in the LNT
Nehemiah 2 in the LSV
Nehemiah 2 in the MAAL
Nehemiah 2 in the MBV
Nehemiah 2 in the MBV2
Nehemiah 2 in the MHNT
Nehemiah 2 in the MKNFD
Nehemiah 2 in the MNG
Nehemiah 2 in the MNT
Nehemiah 2 in the MNT2
Nehemiah 2 in the MRS1T
Nehemiah 2 in the NAA
Nehemiah 2 in the NASB
Nehemiah 2 in the NBLA
Nehemiah 2 in the NBS
Nehemiah 2 in the NBVTP
Nehemiah 2 in the NET2
Nehemiah 2 in the NIV11
Nehemiah 2 in the NNT
Nehemiah 2 in the NNT2
Nehemiah 2 in the NNT3
Nehemiah 2 in the PDDPT
Nehemiah 2 in the PFNT
Nehemiah 2 in the RMNT
Nehemiah 2 in the SBIAS
Nehemiah 2 in the SBIBS
Nehemiah 2 in the SBIBS2
Nehemiah 2 in the SBICS
Nehemiah 2 in the SBIDS
Nehemiah 2 in the SBIGS
Nehemiah 2 in the SBIHS
Nehemiah 2 in the SBIIS
Nehemiah 2 in the SBIIS2
Nehemiah 2 in the SBIIS3
Nehemiah 2 in the SBIKS
Nehemiah 2 in the SBIKS2
Nehemiah 2 in the SBIMS
Nehemiah 2 in the SBIOS
Nehemiah 2 in the SBIPS
Nehemiah 2 in the SBISS
Nehemiah 2 in the SBITS
Nehemiah 2 in the SBITS2
Nehemiah 2 in the SBITS3
Nehemiah 2 in the SBITS4
Nehemiah 2 in the SBIUS
Nehemiah 2 in the SBIVS
Nehemiah 2 in the SBT
Nehemiah 2 in the SBT1E
Nehemiah 2 in the SCHL
Nehemiah 2 in the SNT
Nehemiah 2 in the SUSU
Nehemiah 2 in the SUSU2
Nehemiah 2 in the SYNO
Nehemiah 2 in the TBIAOTANT
Nehemiah 2 in the TBT1E
Nehemiah 2 in the TBT1E2
Nehemiah 2 in the TFTIP
Nehemiah 2 in the TFTU
Nehemiah 2 in the TGNTATF3T
Nehemiah 2 in the THAI
Nehemiah 2 in the TNFD
Nehemiah 2 in the TNT
Nehemiah 2 in the TNTIK
Nehemiah 2 in the TNTIL
Nehemiah 2 in the TNTIN
Nehemiah 2 in the TNTIP
Nehemiah 2 in the TNTIZ
Nehemiah 2 in the TOMA
Nehemiah 2 in the TTENT
Nehemiah 2 in the UBG
Nehemiah 2 in the UGV
Nehemiah 2 in the UGV2
Nehemiah 2 in the UGV3
Nehemiah 2 in the VBL
Nehemiah 2 in the VDCC
Nehemiah 2 in the YALU
Nehemiah 2 in the YAPE
Nehemiah 2 in the YBVTP
Nehemiah 2 in the ZBP