Nehemiah 4 (BOYCB)
1 Nígbà tí Sanballati gbọ́ pé àwa ń tún odi náà mọ, ó bínú, ó sì bínú púpọ̀. Ó fi àwọn ará Júù ṣe ẹlẹ́yà, 2 ó sọ níwájú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti níwájú àwọn ọmọ-ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn aláìlera Júù wọ̀nyí ń ṣe yìí? Ṣé wọn yóò mú odi wọn padà ni? Ṣé wọn yóò rú ẹbọ ni? Ṣé wọn yóò parí i rẹ̀ lóòjọ́ ni bí? Ṣé wọ́n lè mú òkúta tí a ti sun láti inú òkìtì padà bọ̀ sípò tí ó jóná bí wọ́n ṣe wà?” 3 Tobiah ará Ammoni, ẹni tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wí pé, “Ohun tí wọ́n ń mọ—bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ lásán bá gùn ún sókè, yóò fọ́ odi òkúta wọn lulẹ̀!” 4 Gbọ́ ti wa, Ọlọ́run wa, nítorí àwa di ẹni ẹ̀gàn. Dá ẹ̀gàn wọn padà sórí ara wọn. Kí o sì fi wọ́n fún ìkógun ní ilẹ̀ ìgbèkùn. 5 Má ṣe bo ẹ̀bi wọn tàbí wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kúrò níwájú rẹ, nítorí wọ́n mú ọ bínú níwájú àwọn ọ̀mọ̀lé. 6 Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajì gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn. 7 Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati, Tobiah, àwọn ará Arabia, ará Ammoni, àti àwọn ènìyàn Aṣdodu gbọ́ pé àtúnṣe odi Jerusalẹmu ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi. 8 Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jerusalẹmu jà àti láti dìde wàhálà sí í. 9 Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí. 10 Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Juda wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.” 11 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀tá wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárín wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.” 12 Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọlù wá.” 13 Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn. 14 Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn. Ẹ rántí OLÚWA, ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilé yín.” 15 Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ pé àwa ti mọ èrò wọn àti wí pé Ọlọ́run ti bà á jẹ́, gbogbo wa padà sí ibi odi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sí ibi iṣẹ́ tirẹ̀. 16 Láti ọjọ́ náà lọ, ìdajì àwọn ènìyàn ń ṣe iṣẹ́ náà, nígbà tí àwọn ìdajì tókù múra pẹ̀lú ọ̀kọ̀, asà, ọrun àti ìhámọ́ra. Àwọn ìjòyè sì pín ara wọn sẹ́yìn gbogbo ènìyàn Juda. 17 Àwọn ẹni tí ó ń mọ odi. Àwọn tí ń ru àwọn ohun èlò ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú ọwọ́ kan, wọ́n sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà mú, 18 olúkúlùkù àwọn ọ̀mọ̀lé fi idà wọn sí ẹ̀gbẹ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ń fọn ìpè dúró pẹ̀lú mi. 19 Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Iṣẹ́ náà fẹ̀ ó sì pọ̀, a sì ti jìnnà sí ara wa púpọ̀ lórí odi. 20 Níbikíbi tí ẹ bá ti gbọ́ ohùn ìpè, ẹ da ara pọ̀ mọ́ wa níbẹ̀. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa!” 21 Bẹ́ẹ̀ ni àwa ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ìdajì ènìyàn tí ó di ọ̀kọ̀ mú, láti òwúrọ̀ kùtùkùtù títí di ìgbà tí ìràwọ̀ yóò fi yọ. 22 Ní ìgbà náà mo tún sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ dúró ní Jerusalẹmu ní òru, nítorí kí wọn le jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún wa ní òru, kí wọn sì le ṣe iṣẹ́ ní ọ̀sán.” 23 Bẹ́ẹ̀ ni èmi àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ènìyàn mi àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó wà pẹ̀lú mi kò bọ́ aṣọ wa, olúkúlùkù wa ní ohun ìjà tirẹ̀, kódà nígbà tí wọ́n bá ń lọ pọn omi.
In Other Versions
Nehemiah 4 in the ANGEFD
Nehemiah 4 in the ANTPNG2D
Nehemiah 4 in the AS21
Nehemiah 4 in the BAGH
Nehemiah 4 in the BBPNG
Nehemiah 4 in the BBT1E
Nehemiah 4 in the BDS
Nehemiah 4 in the BEV
Nehemiah 4 in the BHAD
Nehemiah 4 in the BIB
Nehemiah 4 in the BLPT
Nehemiah 4 in the BNT
Nehemiah 4 in the BNTABOOT
Nehemiah 4 in the BNTLV
Nehemiah 4 in the BOATCB
Nehemiah 4 in the BOATCB2
Nehemiah 4 in the BOBCV
Nehemiah 4 in the BOCNT
Nehemiah 4 in the BOECS
Nehemiah 4 in the BOGWICC
Nehemiah 4 in the BOHCB
Nehemiah 4 in the BOHCV
Nehemiah 4 in the BOHLNT
Nehemiah 4 in the BOHNTLTAL
Nehemiah 4 in the BOICB
Nehemiah 4 in the BOILNTAP
Nehemiah 4 in the BOITCV
Nehemiah 4 in the BOKCV
Nehemiah 4 in the BOKCV2
Nehemiah 4 in the BOKHWOG
Nehemiah 4 in the BOKSSV
Nehemiah 4 in the BOLCB
Nehemiah 4 in the BOLCB2
Nehemiah 4 in the BOMCV
Nehemiah 4 in the BONAV
Nehemiah 4 in the BONCB
Nehemiah 4 in the BONLT
Nehemiah 4 in the BONUT2
Nehemiah 4 in the BOPLNT
Nehemiah 4 in the BOSCB
Nehemiah 4 in the BOSNC
Nehemiah 4 in the BOTLNT
Nehemiah 4 in the BOVCB
Nehemiah 4 in the BPBB
Nehemiah 4 in the BPH
Nehemiah 4 in the BSB
Nehemiah 4 in the CCB
Nehemiah 4 in the CUV
Nehemiah 4 in the CUVS
Nehemiah 4 in the DBT
Nehemiah 4 in the DGDNT
Nehemiah 4 in the DHNT
Nehemiah 4 in the DNT
Nehemiah 4 in the ELBE
Nehemiah 4 in the EMTV
Nehemiah 4 in the ESV
Nehemiah 4 in the FBV
Nehemiah 4 in the FEB
Nehemiah 4 in the GGMNT
Nehemiah 4 in the GNT
Nehemiah 4 in the HARY
Nehemiah 4 in the HNT
Nehemiah 4 in the IRVA
Nehemiah 4 in the IRVB
Nehemiah 4 in the IRVG
Nehemiah 4 in the IRVH
Nehemiah 4 in the IRVK
Nehemiah 4 in the IRVM
Nehemiah 4 in the IRVM2
Nehemiah 4 in the IRVO
Nehemiah 4 in the IRVP
Nehemiah 4 in the IRVT
Nehemiah 4 in the IRVT2
Nehemiah 4 in the IRVU
Nehemiah 4 in the ISVN
Nehemiah 4 in the JSNT
Nehemiah 4 in the KAPI
Nehemiah 4 in the KBT1ETNIK
Nehemiah 4 in the KBV
Nehemiah 4 in the KJV
Nehemiah 4 in the KNFD
Nehemiah 4 in the LBA
Nehemiah 4 in the LBLA
Nehemiah 4 in the LNT
Nehemiah 4 in the LSV
Nehemiah 4 in the MAAL
Nehemiah 4 in the MBV
Nehemiah 4 in the MBV2
Nehemiah 4 in the MHNT
Nehemiah 4 in the MKNFD
Nehemiah 4 in the MNG
Nehemiah 4 in the MNT
Nehemiah 4 in the MNT2
Nehemiah 4 in the MRS1T
Nehemiah 4 in the NAA
Nehemiah 4 in the NASB
Nehemiah 4 in the NBLA
Nehemiah 4 in the NBS
Nehemiah 4 in the NBVTP
Nehemiah 4 in the NET2
Nehemiah 4 in the NIV11
Nehemiah 4 in the NNT
Nehemiah 4 in the NNT2
Nehemiah 4 in the NNT3
Nehemiah 4 in the PDDPT
Nehemiah 4 in the PFNT
Nehemiah 4 in the RMNT
Nehemiah 4 in the SBIAS
Nehemiah 4 in the SBIBS
Nehemiah 4 in the SBIBS2
Nehemiah 4 in the SBICS
Nehemiah 4 in the SBIDS
Nehemiah 4 in the SBIGS
Nehemiah 4 in the SBIHS
Nehemiah 4 in the SBIIS
Nehemiah 4 in the SBIIS2
Nehemiah 4 in the SBIIS3
Nehemiah 4 in the SBIKS
Nehemiah 4 in the SBIKS2
Nehemiah 4 in the SBIMS
Nehemiah 4 in the SBIOS
Nehemiah 4 in the SBIPS
Nehemiah 4 in the SBISS
Nehemiah 4 in the SBITS
Nehemiah 4 in the SBITS2
Nehemiah 4 in the SBITS3
Nehemiah 4 in the SBITS4
Nehemiah 4 in the SBIUS
Nehemiah 4 in the SBIVS
Nehemiah 4 in the SBT
Nehemiah 4 in the SBT1E
Nehemiah 4 in the SCHL
Nehemiah 4 in the SNT
Nehemiah 4 in the SUSU
Nehemiah 4 in the SUSU2
Nehemiah 4 in the SYNO
Nehemiah 4 in the TBIAOTANT
Nehemiah 4 in the TBT1E
Nehemiah 4 in the TBT1E2
Nehemiah 4 in the TFTIP
Nehemiah 4 in the TFTU
Nehemiah 4 in the TGNTATF3T
Nehemiah 4 in the THAI
Nehemiah 4 in the TNFD
Nehemiah 4 in the TNT
Nehemiah 4 in the TNTIK
Nehemiah 4 in the TNTIL
Nehemiah 4 in the TNTIN
Nehemiah 4 in the TNTIP
Nehemiah 4 in the TNTIZ
Nehemiah 4 in the TOMA
Nehemiah 4 in the TTENT
Nehemiah 4 in the UBG
Nehemiah 4 in the UGV
Nehemiah 4 in the UGV2
Nehemiah 4 in the UGV3
Nehemiah 4 in the VBL
Nehemiah 4 in the VDCC
Nehemiah 4 in the YALU
Nehemiah 4 in the YAPE
Nehemiah 4 in the YBVTP
Nehemiah 4 in the ZBP