Numbers 2 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose àti Aaroni pé, 2 “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.” 3 Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn:ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu. 4 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600). 5 Ẹ̀yà Isakari ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Isakari ni Netaneli ọmọ Suari. 6 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irinwó (54,400). 7 Ẹ̀yà Sebuluni ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni. 8 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (57,400). 9 Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Juda, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàléláàdọ́rùn-ún ó lé irinwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú. 10 Ní ìhà gúúsù:ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 11 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (46,500). 12 Ẹ̀yà Simeoni ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Simoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 13 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje (59,300). 14 Ẹ̀yà Gadi ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli. 15 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́talélẹ́gbẹ̀jọ (45,650). 16 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Reubeni, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́talélégbèje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì. 17 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Lefi àti àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀síwájú láàrín ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láààyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. 18 Ní ìhà ìlà-oòrùn:ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu. 19 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì lé ó lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500). 20 Ẹ̀yà Manase ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Manase ni Gamalieli ọmọ Pedasuri. 21 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba (32,200). 22 Ẹ̀yà Benjamini ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni. 23 Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje (35,400). 24 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Efraimu, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta. 25 Ní ìhà àríwá:ni ìpín Dani yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Dani ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 26 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (62,700). 27 Ẹ̀yà Aṣeri ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okanri. 28 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500). 29 Ẹ̀yà Naftali ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Naftali ni Ahira ọmọ Enani. 30 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé egbèje (53,400). 31 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dani jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rin ó lé ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn. 32 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjìdínlógún dín làádọ́ta (603,550). 33 Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Lefi papọ̀ mọ́ àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mose. 34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí OLÚWA pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.
In Other Versions
Numbers 2 in the ANGEFD
Numbers 2 in the ANTPNG2D
Numbers 2 in the AS21
Numbers 2 in the BAGH
Numbers 2 in the BBPNG
Numbers 2 in the BBT1E
Numbers 2 in the BDS
Numbers 2 in the BEV
Numbers 2 in the BHAD
Numbers 2 in the BIB
Numbers 2 in the BLPT
Numbers 2 in the BNT
Numbers 2 in the BNTABOOT
Numbers 2 in the BNTLV
Numbers 2 in the BOATCB
Numbers 2 in the BOATCB2
Numbers 2 in the BOBCV
Numbers 2 in the BOCNT
Numbers 2 in the BOECS
Numbers 2 in the BOGWICC
Numbers 2 in the BOHCB
Numbers 2 in the BOHCV
Numbers 2 in the BOHLNT
Numbers 2 in the BOHNTLTAL
Numbers 2 in the BOICB
Numbers 2 in the BOILNTAP
Numbers 2 in the BOITCV
Numbers 2 in the BOKCV
Numbers 2 in the BOKCV2
Numbers 2 in the BOKHWOG
Numbers 2 in the BOKSSV
Numbers 2 in the BOLCB
Numbers 2 in the BOLCB2
Numbers 2 in the BOMCV
Numbers 2 in the BONAV
Numbers 2 in the BONCB
Numbers 2 in the BONLT
Numbers 2 in the BONUT2
Numbers 2 in the BOPLNT
Numbers 2 in the BOSCB
Numbers 2 in the BOSNC
Numbers 2 in the BOTLNT
Numbers 2 in the BOVCB
Numbers 2 in the BPBB
Numbers 2 in the BPH
Numbers 2 in the BSB
Numbers 2 in the CCB
Numbers 2 in the CUV
Numbers 2 in the CUVS
Numbers 2 in the DBT
Numbers 2 in the DGDNT
Numbers 2 in the DHNT
Numbers 2 in the DNT
Numbers 2 in the ELBE
Numbers 2 in the EMTV
Numbers 2 in the ESV
Numbers 2 in the FBV
Numbers 2 in the FEB
Numbers 2 in the GGMNT
Numbers 2 in the GNT
Numbers 2 in the HARY
Numbers 2 in the HNT
Numbers 2 in the IRVA
Numbers 2 in the IRVB
Numbers 2 in the IRVG
Numbers 2 in the IRVH
Numbers 2 in the IRVK
Numbers 2 in the IRVM
Numbers 2 in the IRVM2
Numbers 2 in the IRVO
Numbers 2 in the IRVP
Numbers 2 in the IRVT
Numbers 2 in the IRVT2
Numbers 2 in the IRVU
Numbers 2 in the ISVN
Numbers 2 in the JSNT
Numbers 2 in the KAPI
Numbers 2 in the KBT1ETNIK
Numbers 2 in the KBV
Numbers 2 in the KJV
Numbers 2 in the KNFD
Numbers 2 in the LBA
Numbers 2 in the LBLA
Numbers 2 in the LNT
Numbers 2 in the LSV
Numbers 2 in the MAAL
Numbers 2 in the MBV
Numbers 2 in the MBV2
Numbers 2 in the MHNT
Numbers 2 in the MKNFD
Numbers 2 in the MNG
Numbers 2 in the MNT
Numbers 2 in the MNT2
Numbers 2 in the MRS1T
Numbers 2 in the NAA
Numbers 2 in the NASB
Numbers 2 in the NBLA
Numbers 2 in the NBS
Numbers 2 in the NBVTP
Numbers 2 in the NET2
Numbers 2 in the NIV11
Numbers 2 in the NNT
Numbers 2 in the NNT2
Numbers 2 in the NNT3
Numbers 2 in the PDDPT
Numbers 2 in the PFNT
Numbers 2 in the RMNT
Numbers 2 in the SBIAS
Numbers 2 in the SBIBS
Numbers 2 in the SBIBS2
Numbers 2 in the SBICS
Numbers 2 in the SBIDS
Numbers 2 in the SBIGS
Numbers 2 in the SBIHS
Numbers 2 in the SBIIS
Numbers 2 in the SBIIS2
Numbers 2 in the SBIIS3
Numbers 2 in the SBIKS
Numbers 2 in the SBIKS2
Numbers 2 in the SBIMS
Numbers 2 in the SBIOS
Numbers 2 in the SBIPS
Numbers 2 in the SBISS
Numbers 2 in the SBITS
Numbers 2 in the SBITS2
Numbers 2 in the SBITS3
Numbers 2 in the SBITS4
Numbers 2 in the SBIUS
Numbers 2 in the SBIVS
Numbers 2 in the SBT
Numbers 2 in the SBT1E
Numbers 2 in the SCHL
Numbers 2 in the SNT
Numbers 2 in the SUSU
Numbers 2 in the SUSU2
Numbers 2 in the SYNO
Numbers 2 in the TBIAOTANT
Numbers 2 in the TBT1E
Numbers 2 in the TBT1E2
Numbers 2 in the TFTIP
Numbers 2 in the TFTU
Numbers 2 in the TGNTATF3T
Numbers 2 in the THAI
Numbers 2 in the TNFD
Numbers 2 in the TNT
Numbers 2 in the TNTIK
Numbers 2 in the TNTIL
Numbers 2 in the TNTIN
Numbers 2 in the TNTIP
Numbers 2 in the TNTIZ
Numbers 2 in the TOMA
Numbers 2 in the TTENT
Numbers 2 in the UBG
Numbers 2 in the UGV
Numbers 2 in the UGV2
Numbers 2 in the UGV3
Numbers 2 in the VBL
Numbers 2 in the VDCC
Numbers 2 in the YALU
Numbers 2 in the YAPE
Numbers 2 in the YBVTP
Numbers 2 in the ZBP