Numbers 9 (BOYCB)
1 OLÚWA sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé, 2 “Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. 3 Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.” 4 Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. 5 Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mose. 6 Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. 7 Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún OLÚWA pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.” 8 Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí OLÚWA yóò pàṣẹ nípa yín.” 9 Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mose pé, 10 “Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ ìrékọjá OLÚWA mọ́. 11 Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. 12 Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ ìrékọjá. 13 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ OLÚWA wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 14 “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe àjọ ìrékọjá OLÚWA, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ” 15 Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀. 16 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná. 17 Nígbàkígbà tí ìkùùkuu yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkùùkuu náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò pa ibùdó wọn sí. 18 Nípa àṣẹ OLÚWA ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ OLÚWA náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó. 19 Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ OLÚWA wọn kò sì ní gbéra láti lọ. 20 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ OLÚWA, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra. 21 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22 Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23 Nípa àṣẹ OLÚWA ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ OLÚWA náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ OLÚWA ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ OLÚWA láti ẹnu Mose.
In Other Versions
Numbers 9 in the ANGEFD
Numbers 9 in the ANTPNG2D
Numbers 9 in the AS21
Numbers 9 in the BAGH
Numbers 9 in the BBPNG
Numbers 9 in the BBT1E
Numbers 9 in the BDS
Numbers 9 in the BEV
Numbers 9 in the BHAD
Numbers 9 in the BIB
Numbers 9 in the BLPT
Numbers 9 in the BNT
Numbers 9 in the BNTABOOT
Numbers 9 in the BNTLV
Numbers 9 in the BOATCB
Numbers 9 in the BOATCB2
Numbers 9 in the BOBCV
Numbers 9 in the BOCNT
Numbers 9 in the BOECS
Numbers 9 in the BOGWICC
Numbers 9 in the BOHCB
Numbers 9 in the BOHCV
Numbers 9 in the BOHLNT
Numbers 9 in the BOHNTLTAL
Numbers 9 in the BOICB
Numbers 9 in the BOILNTAP
Numbers 9 in the BOITCV
Numbers 9 in the BOKCV
Numbers 9 in the BOKCV2
Numbers 9 in the BOKHWOG
Numbers 9 in the BOKSSV
Numbers 9 in the BOLCB
Numbers 9 in the BOLCB2
Numbers 9 in the BOMCV
Numbers 9 in the BONAV
Numbers 9 in the BONCB
Numbers 9 in the BONLT
Numbers 9 in the BONUT2
Numbers 9 in the BOPLNT
Numbers 9 in the BOSCB
Numbers 9 in the BOSNC
Numbers 9 in the BOTLNT
Numbers 9 in the BOVCB
Numbers 9 in the BPBB
Numbers 9 in the BPH
Numbers 9 in the BSB
Numbers 9 in the CCB
Numbers 9 in the CUV
Numbers 9 in the CUVS
Numbers 9 in the DBT
Numbers 9 in the DGDNT
Numbers 9 in the DHNT
Numbers 9 in the DNT
Numbers 9 in the ELBE
Numbers 9 in the EMTV
Numbers 9 in the ESV
Numbers 9 in the FBV
Numbers 9 in the FEB
Numbers 9 in the GGMNT
Numbers 9 in the GNT
Numbers 9 in the HARY
Numbers 9 in the HNT
Numbers 9 in the IRVA
Numbers 9 in the IRVB
Numbers 9 in the IRVG
Numbers 9 in the IRVH
Numbers 9 in the IRVK
Numbers 9 in the IRVM
Numbers 9 in the IRVM2
Numbers 9 in the IRVO
Numbers 9 in the IRVP
Numbers 9 in the IRVT
Numbers 9 in the IRVT2
Numbers 9 in the IRVU
Numbers 9 in the ISVN
Numbers 9 in the JSNT
Numbers 9 in the KAPI
Numbers 9 in the KBT1ETNIK
Numbers 9 in the KBV
Numbers 9 in the KJV
Numbers 9 in the KNFD
Numbers 9 in the LBA
Numbers 9 in the LBLA
Numbers 9 in the LNT
Numbers 9 in the LSV
Numbers 9 in the MAAL
Numbers 9 in the MBV
Numbers 9 in the MBV2
Numbers 9 in the MHNT
Numbers 9 in the MKNFD
Numbers 9 in the MNG
Numbers 9 in the MNT
Numbers 9 in the MNT2
Numbers 9 in the MRS1T
Numbers 9 in the NAA
Numbers 9 in the NASB
Numbers 9 in the NBLA
Numbers 9 in the NBS
Numbers 9 in the NBVTP
Numbers 9 in the NET2
Numbers 9 in the NIV11
Numbers 9 in the NNT
Numbers 9 in the NNT2
Numbers 9 in the NNT3
Numbers 9 in the PDDPT
Numbers 9 in the PFNT
Numbers 9 in the RMNT
Numbers 9 in the SBIAS
Numbers 9 in the SBIBS
Numbers 9 in the SBIBS2
Numbers 9 in the SBICS
Numbers 9 in the SBIDS
Numbers 9 in the SBIGS
Numbers 9 in the SBIHS
Numbers 9 in the SBIIS
Numbers 9 in the SBIIS2
Numbers 9 in the SBIIS3
Numbers 9 in the SBIKS
Numbers 9 in the SBIKS2
Numbers 9 in the SBIMS
Numbers 9 in the SBIOS
Numbers 9 in the SBIPS
Numbers 9 in the SBISS
Numbers 9 in the SBITS
Numbers 9 in the SBITS2
Numbers 9 in the SBITS3
Numbers 9 in the SBITS4
Numbers 9 in the SBIUS
Numbers 9 in the SBIVS
Numbers 9 in the SBT
Numbers 9 in the SBT1E
Numbers 9 in the SCHL
Numbers 9 in the SNT
Numbers 9 in the SUSU
Numbers 9 in the SUSU2
Numbers 9 in the SYNO
Numbers 9 in the TBIAOTANT
Numbers 9 in the TBT1E
Numbers 9 in the TBT1E2
Numbers 9 in the TFTIP
Numbers 9 in the TFTU
Numbers 9 in the TGNTATF3T
Numbers 9 in the THAI
Numbers 9 in the TNFD
Numbers 9 in the TNT
Numbers 9 in the TNTIK
Numbers 9 in the TNTIL
Numbers 9 in the TNTIN
Numbers 9 in the TNTIP
Numbers 9 in the TNTIZ
Numbers 9 in the TOMA
Numbers 9 in the TTENT
Numbers 9 in the UBG
Numbers 9 in the UGV
Numbers 9 in the UGV2
Numbers 9 in the UGV3
Numbers 9 in the VBL
Numbers 9 in the VDCC
Numbers 9 in the YALU
Numbers 9 in the YAPE
Numbers 9 in the YBVTP
Numbers 9 in the ZBP