Philemon 1 (BOYCB)

1 Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìyìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa, Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, 2 sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ: 3 Oore-ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi. 4 Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, 5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. 6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. 7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára. 8 Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, 9 síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. 10 Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. 11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá. 12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13 Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìyìnrere 14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15 Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé. 16 Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa. 17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ. 20 Èmi ń fẹ́ arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi. 21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ. 22 Ó ku ohun kan, ṣe ìtọ́jú iyàrá àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín. 23 Epafira, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kristi Jesu kí ọ. 24 Marku kí ọ pẹ̀lú Aristarku, Dema àti Luku, àwọn alábáṣiṣẹ́ mi. 25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

In Other Versions

Philemon 1 in the ANGEFD

Philemon 1 in the ANTPNG2D

Philemon 1 in the AS21

Philemon 1 in the BAGH

Philemon 1 in the BBPNG

Philemon 1 in the BBT1E

Philemon 1 in the BDS

Philemon 1 in the BEV

Philemon 1 in the BHAD

Philemon 1 in the BIB

Philemon 1 in the BLPT

Philemon 1 in the BNT

Philemon 1 in the BNTABOOT

Philemon 1 in the BNTLV

Philemon 1 in the BOATCB

Philemon 1 in the BOATCB2

Philemon 1 in the BOBCV

Philemon 1 in the BOCNT

Philemon 1 in the BOECS

Philemon 1 in the BOGWICC

Philemon 1 in the BOHCB

Philemon 1 in the BOHCV

Philemon 1 in the BOHLNT

Philemon 1 in the BOHNTLTAL

Philemon 1 in the BOICB

Philemon 1 in the BOILNTAP

Philemon 1 in the BOITCV

Philemon 1 in the BOKCV

Philemon 1 in the BOKCV2

Philemon 1 in the BOKHWOG

Philemon 1 in the BOKSSV

Philemon 1 in the BOLCB

Philemon 1 in the BOLCB2

Philemon 1 in the BOMCV

Philemon 1 in the BONAV

Philemon 1 in the BONCB

Philemon 1 in the BONLT

Philemon 1 in the BONUT2

Philemon 1 in the BOPLNT

Philemon 1 in the BOSCB

Philemon 1 in the BOSNC

Philemon 1 in the BOTLNT

Philemon 1 in the BOVCB

Philemon 1 in the BPBB

Philemon 1 in the BPH

Philemon 1 in the BSB

Philemon 1 in the CCB

Philemon 1 in the CUV

Philemon 1 in the CUVS

Philemon 1 in the DBT

Philemon 1 in the DGDNT

Philemon 1 in the DHNT

Philemon 1 in the DNT

Philemon 1 in the ELBE

Philemon 1 in the EMTV

Philemon 1 in the ESV

Philemon 1 in the FBV

Philemon 1 in the FEB

Philemon 1 in the GGMNT

Philemon 1 in the GNT

Philemon 1 in the HARY

Philemon 1 in the HNT

Philemon 1 in the IRVA

Philemon 1 in the IRVB

Philemon 1 in the IRVG

Philemon 1 in the IRVH

Philemon 1 in the IRVK

Philemon 1 in the IRVM

Philemon 1 in the IRVM2

Philemon 1 in the IRVO

Philemon 1 in the IRVP

Philemon 1 in the IRVT

Philemon 1 in the IRVT2

Philemon 1 in the IRVU

Philemon 1 in the ISVN

Philemon 1 in the JSNT

Philemon 1 in the KAPI

Philemon 1 in the KBT1ETNIK

Philemon 1 in the KBV

Philemon 1 in the KJV

Philemon 1 in the KNFD

Philemon 1 in the LBA

Philemon 1 in the LBLA

Philemon 1 in the LNT

Philemon 1 in the LSV

Philemon 1 in the MAAL

Philemon 1 in the MBV

Philemon 1 in the MBV2

Philemon 1 in the MHNT

Philemon 1 in the MKNFD

Philemon 1 in the MNG

Philemon 1 in the MNT

Philemon 1 in the MNT2

Philemon 1 in the MRS1T

Philemon 1 in the NAA

Philemon 1 in the NASB

Philemon 1 in the NBLA

Philemon 1 in the NBS

Philemon 1 in the NBVTP

Philemon 1 in the NET2

Philemon 1 in the NIV11

Philemon 1 in the NNT

Philemon 1 in the NNT2

Philemon 1 in the NNT3

Philemon 1 in the PDDPT

Philemon 1 in the PFNT

Philemon 1 in the RMNT

Philemon 1 in the SBIAS

Philemon 1 in the SBIBS

Philemon 1 in the SBIBS2

Philemon 1 in the SBICS

Philemon 1 in the SBIDS

Philemon 1 in the SBIGS

Philemon 1 in the SBIHS

Philemon 1 in the SBIIS

Philemon 1 in the SBIIS2

Philemon 1 in the SBIIS3

Philemon 1 in the SBIKS

Philemon 1 in the SBIKS2

Philemon 1 in the SBIMS

Philemon 1 in the SBIOS

Philemon 1 in the SBIPS

Philemon 1 in the SBISS

Philemon 1 in the SBITS

Philemon 1 in the SBITS2

Philemon 1 in the SBITS3

Philemon 1 in the SBITS4

Philemon 1 in the SBIUS

Philemon 1 in the SBIVS

Philemon 1 in the SBT

Philemon 1 in the SBT1E

Philemon 1 in the SCHL

Philemon 1 in the SNT

Philemon 1 in the SUSU

Philemon 1 in the SUSU2

Philemon 1 in the SYNO

Philemon 1 in the TBIAOTANT

Philemon 1 in the TBT1E

Philemon 1 in the TBT1E2

Philemon 1 in the TFTIP

Philemon 1 in the TFTU

Philemon 1 in the TGNTATF3T

Philemon 1 in the THAI

Philemon 1 in the TNFD

Philemon 1 in the TNT

Philemon 1 in the TNTIK

Philemon 1 in the TNTIL

Philemon 1 in the TNTIN

Philemon 1 in the TNTIP

Philemon 1 in the TNTIZ

Philemon 1 in the TOMA

Philemon 1 in the TTENT

Philemon 1 in the UBG

Philemon 1 in the UGV

Philemon 1 in the UGV2

Philemon 1 in the UGV3

Philemon 1 in the VBL

Philemon 1 in the VDCC

Philemon 1 in the YALU

Philemon 1 in the YAPE

Philemon 1 in the YBVTP

Philemon 1 in the ZBP