Proverbs 17 (BOYCB)
1 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sànju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà. 2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ. 3 Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà,ṣùgbọ́n OLÚWA ló ń dán ọkàn wò. 4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi;òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú. 5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà. 6 Ọmọ ọmọ ni adé orí arúgbó,ògo àwọn ọmọ sì ni òbí jẹ. 7 Ọ̀rọ̀ dídùn kò yẹ aṣiwèrè,bẹ́ẹ̀ ni ètè èké kò yẹ ọmọ-aládé! 8 Òkúta iyebíye jẹ́ ẹ̀bùn ní ojú ẹni tí ó ni í,ibikíbi tí ó yí sí, á ṣe rere. 9 Ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i.Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ méjì ní yà. 10 Ọ̀rọ̀ ìbáwí dun olóye ènìyànju ọgọ́rùn-ún pàṣán lọ lẹ́yìn òmùgọ̀. 11 Orí kunkun ni ènìyàn ìkà máa ń ṣe,ìjòyè aláìláàánú ni a ó rán sí i. 12 Ó sàn kí ènìyàn pàdé beari tí a ti kó lọ́mọjù aláìgbọ́n nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. 13 Bí ènìyàn kan bá fi ibi san ìre,ibi kì yóò kúrò nílé rẹ̀ láéláé. 14 Bíbẹ̀rẹ̀ ìjà dàbí ẹni tí ó dá ojú fún adágún omi;nítorí náà mẹ́nu kúrò nínú ọ̀rọ̀ kí ó tó di ìjà. 15 Gbígbé ẹ̀bi fún aláre àti dídá ẹni jàre lẹ́bi, OLÚWA kórìíra méjèèjì. 16 Kí ni ìwúlò owó lọ́wọ́ aṣiwèrè,níwọ̀n bí kò ti ní èròǹgbà láti rí ọgbọ́n? 17 Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo,arákùnrin sì wà fún ìgbà ìpọ́njú. 18 Ènìyàn aláìgbọ́n ṣe ìbúra,ó sì ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ̀. 19 Ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà fẹ́ràn ẹ̀ṣẹ̀;ẹni tí ó kọ́ ibodè gígàn ń wá ìparun. 20 Ènìyàn aláyídáyidà ọkàn kì í gbèrú,ẹni tí ó ní ahọ́n ẹ̀tàn bọ́ sínú ìyọnu. 21 Láti bí aláìgbọ́n lọ́mọ a máa fa ìbànújẹ́ ọkàn,kò sí ayọ̀ fún baba ọmọ tí kò gbọ́n. 22 Ọkàn tí ó túká jẹ́ oògùn gidi,ṣùgbọ́n ọkàn tí ó bàjẹ́ a máa mú kí egungun gbẹ. 23 Ènìyàn búburú a gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀láti yí ìdájọ́ po. 24 Olóye ènìyàn gbójú wo ọgbọ́n níwájú,ṣùgbọ́n ojú aláìgbọ́n ń wò káàkiri ilẹ̀ ayé. 25 Aṣiwèrè ọmọ mú ìbànújẹ́ bá baba rẹ̀àti ìkorò fún ẹni tí ó bí i lọ́mọ. 26 Kò dára láti fìyà jẹ ènìyàn tí kò ṣẹ̀,tàbí láti na ìjòyè lórí òtítọ́ inú wọn. 27 Ènìyàn tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ,ènìyàn olóye sì máa ń ní sùúrù. 28 Kódà aláìgbọ́n máa ń dàbí ọlọ́gbọ́n bí ó bá dákẹ́,àti bí olóye bí ó bá fètèmétè.
In Other Versions
Proverbs 17 in the ANGEFD
Proverbs 17 in the ANTPNG2D
Proverbs 17 in the AS21
Proverbs 17 in the BAGH
Proverbs 17 in the BBPNG
Proverbs 17 in the BBT1E
Proverbs 17 in the BDS
Proverbs 17 in the BEV
Proverbs 17 in the BHAD
Proverbs 17 in the BIB
Proverbs 17 in the BLPT
Proverbs 17 in the BNT
Proverbs 17 in the BNTABOOT
Proverbs 17 in the BNTLV
Proverbs 17 in the BOATCB
Proverbs 17 in the BOATCB2
Proverbs 17 in the BOBCV
Proverbs 17 in the BOCNT
Proverbs 17 in the BOECS
Proverbs 17 in the BOGWICC
Proverbs 17 in the BOHCB
Proverbs 17 in the BOHCV
Proverbs 17 in the BOHLNT
Proverbs 17 in the BOHNTLTAL
Proverbs 17 in the BOICB
Proverbs 17 in the BOILNTAP
Proverbs 17 in the BOITCV
Proverbs 17 in the BOKCV
Proverbs 17 in the BOKCV2
Proverbs 17 in the BOKHWOG
Proverbs 17 in the BOKSSV
Proverbs 17 in the BOLCB
Proverbs 17 in the BOLCB2
Proverbs 17 in the BOMCV
Proverbs 17 in the BONAV
Proverbs 17 in the BONCB
Proverbs 17 in the BONLT
Proverbs 17 in the BONUT2
Proverbs 17 in the BOPLNT
Proverbs 17 in the BOSCB
Proverbs 17 in the BOSNC
Proverbs 17 in the BOTLNT
Proverbs 17 in the BOVCB
Proverbs 17 in the BPBB
Proverbs 17 in the BPH
Proverbs 17 in the BSB
Proverbs 17 in the CCB
Proverbs 17 in the CUV
Proverbs 17 in the CUVS
Proverbs 17 in the DBT
Proverbs 17 in the DGDNT
Proverbs 17 in the DHNT
Proverbs 17 in the DNT
Proverbs 17 in the ELBE
Proverbs 17 in the EMTV
Proverbs 17 in the ESV
Proverbs 17 in the FBV
Proverbs 17 in the FEB
Proverbs 17 in the GGMNT
Proverbs 17 in the GNT
Proverbs 17 in the HARY
Proverbs 17 in the HNT
Proverbs 17 in the IRVA
Proverbs 17 in the IRVB
Proverbs 17 in the IRVG
Proverbs 17 in the IRVH
Proverbs 17 in the IRVK
Proverbs 17 in the IRVM
Proverbs 17 in the IRVM2
Proverbs 17 in the IRVO
Proverbs 17 in the IRVP
Proverbs 17 in the IRVT
Proverbs 17 in the IRVT2
Proverbs 17 in the IRVU
Proverbs 17 in the ISVN
Proverbs 17 in the JSNT
Proverbs 17 in the KAPI
Proverbs 17 in the KBT1ETNIK
Proverbs 17 in the KBV
Proverbs 17 in the KJV
Proverbs 17 in the KNFD
Proverbs 17 in the LBA
Proverbs 17 in the LBLA
Proverbs 17 in the LNT
Proverbs 17 in the LSV
Proverbs 17 in the MAAL
Proverbs 17 in the MBV
Proverbs 17 in the MBV2
Proverbs 17 in the MHNT
Proverbs 17 in the MKNFD
Proverbs 17 in the MNG
Proverbs 17 in the MNT
Proverbs 17 in the MNT2
Proverbs 17 in the MRS1T
Proverbs 17 in the NAA
Proverbs 17 in the NASB
Proverbs 17 in the NBLA
Proverbs 17 in the NBS
Proverbs 17 in the NBVTP
Proverbs 17 in the NET2
Proverbs 17 in the NIV11
Proverbs 17 in the NNT
Proverbs 17 in the NNT2
Proverbs 17 in the NNT3
Proverbs 17 in the PDDPT
Proverbs 17 in the PFNT
Proverbs 17 in the RMNT
Proverbs 17 in the SBIAS
Proverbs 17 in the SBIBS
Proverbs 17 in the SBIBS2
Proverbs 17 in the SBICS
Proverbs 17 in the SBIDS
Proverbs 17 in the SBIGS
Proverbs 17 in the SBIHS
Proverbs 17 in the SBIIS
Proverbs 17 in the SBIIS2
Proverbs 17 in the SBIIS3
Proverbs 17 in the SBIKS
Proverbs 17 in the SBIKS2
Proverbs 17 in the SBIMS
Proverbs 17 in the SBIOS
Proverbs 17 in the SBIPS
Proverbs 17 in the SBISS
Proverbs 17 in the SBITS
Proverbs 17 in the SBITS2
Proverbs 17 in the SBITS3
Proverbs 17 in the SBITS4
Proverbs 17 in the SBIUS
Proverbs 17 in the SBIVS
Proverbs 17 in the SBT
Proverbs 17 in the SBT1E
Proverbs 17 in the SCHL
Proverbs 17 in the SNT
Proverbs 17 in the SUSU
Proverbs 17 in the SUSU2
Proverbs 17 in the SYNO
Proverbs 17 in the TBIAOTANT
Proverbs 17 in the TBT1E
Proverbs 17 in the TBT1E2
Proverbs 17 in the TFTIP
Proverbs 17 in the TFTU
Proverbs 17 in the TGNTATF3T
Proverbs 17 in the THAI
Proverbs 17 in the TNFD
Proverbs 17 in the TNT
Proverbs 17 in the TNTIK
Proverbs 17 in the TNTIL
Proverbs 17 in the TNTIN
Proverbs 17 in the TNTIP
Proverbs 17 in the TNTIZ
Proverbs 17 in the TOMA
Proverbs 17 in the TTENT
Proverbs 17 in the UBG
Proverbs 17 in the UGV
Proverbs 17 in the UGV2
Proverbs 17 in the UGV3
Proverbs 17 in the VBL
Proverbs 17 in the VDCC
Proverbs 17 in the YALU
Proverbs 17 in the YAPE
Proverbs 17 in the YBVTP
Proverbs 17 in the ZBP