Proverbs 23 (BOYCB)

1 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi. 2 Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn. 3 Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni. 4 Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. 5 Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀,ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. 6 Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́,bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀. 7 Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:“Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ. 8 Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù. 9 Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè;nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ. 10 Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò;má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba. 11 Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;yóò gba ìjà wọn jà sí ọ. 12 Fi àyà sí ẹ̀kọ́,àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀. 13 Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé,nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú. 14 Bí ìwọ fi pàṣán nà án,ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì. 15 Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n,ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú. 16 Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́. 17 Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù OLÚWA,ní ọjọ́ gbogbo. 18 Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́;ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò. 19 Gbọ́, ìwọ ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,kí o sì máa tọ́ àyà rẹ sí ọ̀nà títọ́. 20 Má ṣe wà nínú àwọn ọ̀mùtí;àti àwọn wọ̀bìà alájẹkì ọ̀jẹun; 21 nítorí pé ọ̀mùtí àti ọ̀jẹun ni yóò di tálákà;ìmúni-tòògbé ní sì ń fi àkísà wọ ọkùnrin láṣọ. 22 Fetí sí ti baba rẹ tí ó bí ọ,má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí o bá gbó. 23 Ra òtítọ́, kí o má sì ṣe tà á;ra ọgbọ́n pẹ̀lú àti ẹ̀kọ́ àti òye. 24 Baba olódodo ni yóò yọ̀ gidigidi:ẹni tí ó sì bí ọmọ ọlọ́gbọ́n,yóò ní ayọ̀ nínú rẹ̀. 25 Jẹ́ kí baba rẹ àti ìyá rẹ ó yọ̀,sì jẹ́ kí inú ẹni tí ó bí ọ dùn. 26 Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi,kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ ní inú dídùn sí ọ̀nà mi. 27 Nítorí pé panṣágà obìnrin ọ̀gbun jíjìn ni;àti àjèjì obìnrin kànga híhá ni. 28 Òun á sì ba ní bùba bí olè,a sì sọ àwọn olùrékọjá di púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn. 29 Ta ni ó ni òsì? Ta ni ó ni ìbànújẹ́?Ta ni ó ni ìjà? Ta ni ó ni asọ̀? Ta ni ó ni ọgbẹ́ láìnídìí? 30 Àwọn tí ó dúró pẹ́ níbi ọtí wáìnì;àwọn tí ń lọ láti dán ọtí wáìnì àdàlú wò. 31 Ìwọ má ṣe wò ọtí wáìnì nígbà tí ó pọ́n,nígbà tí ó bá ń fi àwọ̀ rẹ̀ hàn nínú ago,tí a gbé e mì, tí ó ń dùn. 32 Níkẹyìn òun á bu ni ṣán bí ejò,a sì bunijẹ bí i paramọ́lẹ̀. 33 Ojú rẹ yóò wò àwọn àjèjì obìnrin,àyà rẹ yóò sì sọ̀rọ̀ àyídáyidà. 34 Nítòótọ́, ìwọ ó dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ ní àárín Òkun,tàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lókè-ọkọ̀. 35 Ìwọ ó sì wí pé, “Wọ́n lù mí; kò dùn mí;wọ́n lù mí, èmi kò sì mọ̀:nígbà wo ni èmi ó jí?Èmi ó tún máa wá òmíràn láti mu.”

In Other Versions

Proverbs 23 in the ANGEFD

Proverbs 23 in the ANTPNG2D

Proverbs 23 in the AS21

Proverbs 23 in the BAGH

Proverbs 23 in the BBPNG

Proverbs 23 in the BBT1E

Proverbs 23 in the BDS

Proverbs 23 in the BEV

Proverbs 23 in the BHAD

Proverbs 23 in the BIB

Proverbs 23 in the BLPT

Proverbs 23 in the BNT

Proverbs 23 in the BNTABOOT

Proverbs 23 in the BNTLV

Proverbs 23 in the BOATCB

Proverbs 23 in the BOATCB2

Proverbs 23 in the BOBCV

Proverbs 23 in the BOCNT

Proverbs 23 in the BOECS

Proverbs 23 in the BOGWICC

Proverbs 23 in the BOHCB

Proverbs 23 in the BOHCV

Proverbs 23 in the BOHLNT

Proverbs 23 in the BOHNTLTAL

Proverbs 23 in the BOICB

Proverbs 23 in the BOILNTAP

Proverbs 23 in the BOITCV

Proverbs 23 in the BOKCV

Proverbs 23 in the BOKCV2

Proverbs 23 in the BOKHWOG

Proverbs 23 in the BOKSSV

Proverbs 23 in the BOLCB

Proverbs 23 in the BOLCB2

Proverbs 23 in the BOMCV

Proverbs 23 in the BONAV

Proverbs 23 in the BONCB

Proverbs 23 in the BONLT

Proverbs 23 in the BONUT2

Proverbs 23 in the BOPLNT

Proverbs 23 in the BOSCB

Proverbs 23 in the BOSNC

Proverbs 23 in the BOTLNT

Proverbs 23 in the BOVCB

Proverbs 23 in the BPBB

Proverbs 23 in the BPH

Proverbs 23 in the BSB

Proverbs 23 in the CCB

Proverbs 23 in the CUV

Proverbs 23 in the CUVS

Proverbs 23 in the DBT

Proverbs 23 in the DGDNT

Proverbs 23 in the DHNT

Proverbs 23 in the DNT

Proverbs 23 in the ELBE

Proverbs 23 in the EMTV

Proverbs 23 in the ESV

Proverbs 23 in the FBV

Proverbs 23 in the FEB

Proverbs 23 in the GGMNT

Proverbs 23 in the GNT

Proverbs 23 in the HARY

Proverbs 23 in the HNT

Proverbs 23 in the IRVA

Proverbs 23 in the IRVB

Proverbs 23 in the IRVG

Proverbs 23 in the IRVH

Proverbs 23 in the IRVK

Proverbs 23 in the IRVM

Proverbs 23 in the IRVM2

Proverbs 23 in the IRVO

Proverbs 23 in the IRVP

Proverbs 23 in the IRVT

Proverbs 23 in the IRVT2

Proverbs 23 in the IRVU

Proverbs 23 in the ISVN

Proverbs 23 in the JSNT

Proverbs 23 in the KAPI

Proverbs 23 in the KBT1ETNIK

Proverbs 23 in the KBV

Proverbs 23 in the KJV

Proverbs 23 in the KNFD

Proverbs 23 in the LBA

Proverbs 23 in the LBLA

Proverbs 23 in the LNT

Proverbs 23 in the LSV

Proverbs 23 in the MAAL

Proverbs 23 in the MBV

Proverbs 23 in the MBV2

Proverbs 23 in the MHNT

Proverbs 23 in the MKNFD

Proverbs 23 in the MNG

Proverbs 23 in the MNT

Proverbs 23 in the MNT2

Proverbs 23 in the MRS1T

Proverbs 23 in the NAA

Proverbs 23 in the NASB

Proverbs 23 in the NBLA

Proverbs 23 in the NBS

Proverbs 23 in the NBVTP

Proverbs 23 in the NET2

Proverbs 23 in the NIV11

Proverbs 23 in the NNT

Proverbs 23 in the NNT2

Proverbs 23 in the NNT3

Proverbs 23 in the PDDPT

Proverbs 23 in the PFNT

Proverbs 23 in the RMNT

Proverbs 23 in the SBIAS

Proverbs 23 in the SBIBS

Proverbs 23 in the SBIBS2

Proverbs 23 in the SBICS

Proverbs 23 in the SBIDS

Proverbs 23 in the SBIGS

Proverbs 23 in the SBIHS

Proverbs 23 in the SBIIS

Proverbs 23 in the SBIIS2

Proverbs 23 in the SBIIS3

Proverbs 23 in the SBIKS

Proverbs 23 in the SBIKS2

Proverbs 23 in the SBIMS

Proverbs 23 in the SBIOS

Proverbs 23 in the SBIPS

Proverbs 23 in the SBISS

Proverbs 23 in the SBITS

Proverbs 23 in the SBITS2

Proverbs 23 in the SBITS3

Proverbs 23 in the SBITS4

Proverbs 23 in the SBIUS

Proverbs 23 in the SBIVS

Proverbs 23 in the SBT

Proverbs 23 in the SBT1E

Proverbs 23 in the SCHL

Proverbs 23 in the SNT

Proverbs 23 in the SUSU

Proverbs 23 in the SUSU2

Proverbs 23 in the SYNO

Proverbs 23 in the TBIAOTANT

Proverbs 23 in the TBT1E

Proverbs 23 in the TBT1E2

Proverbs 23 in the TFTIP

Proverbs 23 in the TFTU

Proverbs 23 in the TGNTATF3T

Proverbs 23 in the THAI

Proverbs 23 in the TNFD

Proverbs 23 in the TNT

Proverbs 23 in the TNTIK

Proverbs 23 in the TNTIL

Proverbs 23 in the TNTIN

Proverbs 23 in the TNTIP

Proverbs 23 in the TNTIZ

Proverbs 23 in the TOMA

Proverbs 23 in the TTENT

Proverbs 23 in the UBG

Proverbs 23 in the UGV

Proverbs 23 in the UGV2

Proverbs 23 in the UGV3

Proverbs 23 in the VBL

Proverbs 23 in the VDCC

Proverbs 23 in the YALU

Proverbs 23 in the YAPE

Proverbs 23 in the YBVTP

Proverbs 23 in the ZBP