Psalms 100 (BOYCB)
undefined Saamu. Fún ọpẹ́. 1 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLÚWA, gbogbo ayé. 2 Ẹ fi ayọ̀ sin OLÚWA,ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn 3 OLÚWA Ọlọ́run ni ó dá wa,kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pétirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀àti àgùntàn pápá rẹ̀. 4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀. 5 Nítorí tí OLÚWA pọ̀ ní ooreìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.