Psalms 111 (BOYCB)
1 Ẹ máa yin OLÚWA. Èmi yóò máa yin OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn. 2 Iṣẹ́ OLÚWA tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀. 3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé. 4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: OLÚWA ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú. 5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀. 6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní. 7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú. 8 Wọ́n dúró láé àti láé,ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n. 9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé,mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀. 10 Ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,ìyìn rẹ̀ dúró láé.