Psalms 119 (BOYCB)

1 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLÚWA. 2 Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. 3 Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀. 4 Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi. 5 Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣinláti máa pa òfin rẹ̀ mọ́! 6 Nígbà náà, ojú kò ní tì mínígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo. 7 Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣinbí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀. 8 Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀,má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá. 9 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ. 10 Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mimá ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ. 11 Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mikí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ. 12 Ìyìn ni fún OLÚWA;kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. 13 Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírògbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ. 14 Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá. 15 Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹèmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ. 16 Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ. 17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ. 18 La ojú mi kí èmi lè ríran ríohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ. 19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé,má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi. 20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nànítorí òfin rẹ nígbà gbogbo. 21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn úntí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ. 22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́. 23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀,wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ. 24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi. 25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. 26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. 27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ. 28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. 29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tànfún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ. 30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ. 31 Èmi yára di òfin rẹ mú. OLÚWAmá ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí. 32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀. 33 Kọ́ mi, OLÚWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin. 34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi. 35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn. 36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹkí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. 37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. 38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,nítorí òfin rẹ dára. 39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rùnítorí tí ìdájọ́ rẹ dára. 40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ. 41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLÚWA,ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. 42 Nígbà náà ni èmi yóò dáẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. 43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu minítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ. 44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogboláé àti láéláé. 45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde. 46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọbaojú kì yóò sì tì mí, 47 nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹnítorí èmi ní ìfẹ́ wọn. 48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀. 49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí. 50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́. 51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ. 52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLÚWA,èmi sì rí ìtùnú nínú wọn. 53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀. 54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin miníbikíbi tí èmi ń gbé. 55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLÚWA,èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ 56 nítorí tí mogba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́. 57 Ìwọ ni ìpín mi, OLÚWA:èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ. 58 Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. 59 Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mièmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ. 60 Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́raláti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. 61 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. 62 Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọnítorí òfin òdodo rẹ. 63 Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ. 64 Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ, OLÚWA,kọ́ mi ní òfin rẹ. 65 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹgẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLÚWA. 66 Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere,nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ. 67 Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà,ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ. 68 Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni;kọ́ mi ní ìlànà rẹ. 69 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí,èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. 70 Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú,ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ. 71 Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójúnítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ. 72 Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ. 73 Ọwọ́ rẹ ni ó dá mi tí ó sì mọ mí;fún mi ní òye láti kọ́ àṣẹ rẹ. 74 Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ máa yọ̀ nígbà tí wọ́n bá rí mi,nítorí èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. 75 Èmi mọ, OLÚWA, nítorí òfin rẹ òdodo ni,àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú. 76 Kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà jẹ́ ìtùnú mi,gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ. 77 Jẹ́ kí àánú rẹ kí ó tọ̀ mí wá, kí èmi kí ó lè yè,nítorí òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi. 78 Kí ojú kí ó ti àwọn agbéraganítorí wọn pa mí lára láìnídìíṣùgbọ́n èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. 79 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ yí padà sí mi,àwọn tí ó ní òye òfin rẹ. 80 Jẹ́ kí ọkàn mi wà láìlẹ́bi sí òfin rẹ,kí ojú kí ó má ṣe tì mí. 81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. 82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?” 83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ. 84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọntí ń ṣe inúnibíni sí mi wí? 85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,tí ó lòdì sí òfin rẹ. 86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé;ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí. 87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ. 88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́. 89 Ọ̀rọ̀ rẹ, OLÚWA, títí láé ni;ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run. 90 Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran;ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin. 91 Òfin rẹ dúró di ònínítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́. 92 Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi,èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi. 93 Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé,nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́. 94 Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹèmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ. 95 Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run,ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ. 96 Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin;ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni. 97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá. 98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé. 99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ. 100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ. 101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibinítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ. 102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ ni ó kọ́ mi. 103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi! 104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́. 105 Ọ̀rọ̀ rẹ ni fìtílà sí ẹsẹ̀ miàti ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà mi. 106 Èmi ti ṣe ìbúra èmi sì ti tẹnumọ́ ọnwí pé èmi yóò máa tẹ̀lé òfin òdodo rẹ. 107 A pọ́n mi lójú gidigidi; OLÚWA, sọ mi di ààyè, gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ rẹ 108 OLÚWA, gba ìyìn àtinúwá ẹnu mi,kí o sì kọ́ mi ní òfin rẹ̀. 109 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé mi wà ni ọwọ́ mi nígbà gbogbo,èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. 110 Àwọn ẹni búburú ti dẹ okùn sílẹ̀ fún mi,ṣùgbọ́n èmi kò ṣìnà kúrò nínú ẹ̀kọ́ rẹ. 111 Òfin rẹ ni ogún mi láéláé;àwọn ni ayọ̀ ọkàn mi. 112 Ọkàn mi ti lé pípa òfin rẹ mọ́láé dé òpin. 113 Èmi kórìíra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin rẹ. 114 Ìwọ ni ààbò mi àti asà mi;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. 115 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́! 116 Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí. 117 Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin rẹ. 118 Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó ṣìnà kúrò nínú òfin rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni. 119 Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọ yọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin rẹ̀. 120 Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin rẹ. 121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára. 122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára. 123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ. 124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹkí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. 125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òyekí èmi lè ní òye òfin rẹ 126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, OLÚWA;nítorí òfin rẹ ti fọ́. 127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ, 128 nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú. 129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́. 130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;ó fi òye fún àwọn òpè. 131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ. 132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọntí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ. 133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi. 134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. 135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lárakí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ. 136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́. 137 Olódodo ni ìwọ OLÚWAìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin. 138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé. 139 Ìtara mi ti pa mí run,nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá. 140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátáìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n. 141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gànèmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ. 142 Òdodo rẹ wà títí láéòtítọ́ ni òfin rẹ̀. 143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi. 144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;fún mi ní òye kí èmi lè yè. 145 Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:dá mi lóhùn OLÚWA,èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. 146 Èmi kígbe pè ọ́; gbà míèmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́. 147 Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. 148 Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru,nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ. 149 Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ:pa ayé mi mọ́, OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. 150 Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí,ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ. 151 Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, OLÚWA,àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́. 152 Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹtí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé. 153 Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí,nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ. 154 Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. 155 Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburúnítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ. 156 Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, OLÚWA;pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. 157 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi,ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ. 158 Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. 159 Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ;pa ayé mi mọ́, OLÚWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ. 160 Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ;gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni. 161 Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí,ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ. 162 Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹbí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀. 163 Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣeṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ. 164 Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́nítorí òfin òdodo rẹ. 165 Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ,kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. 166 Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, OLÚWA,èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ. 167 Èmi gba òfin rẹ gbọ́,nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀. 168 Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ,nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi. 169 Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, OLÚWA;fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. 170 Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ;gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. 171 Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde,nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ. 172 Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ,nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo. 173 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ. 174 Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLÚWA,àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi. 175 Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́,kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró. 176 Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù.Wá ìránṣẹ́ rẹ,nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

In Other Versions

Psalms 119 in the ANGEFD

Psalms 119 in the ANTPNG2D

Psalms 119 in the AS21

Psalms 119 in the BAGH

Psalms 119 in the BBPNG

Psalms 119 in the BBT1E

Psalms 119 in the BDS

Psalms 119 in the BEV

Psalms 119 in the BHAD

Psalms 119 in the BIB

Psalms 119 in the BLPT

Psalms 119 in the BNT

Psalms 119 in the BNTABOOT

Psalms 119 in the BNTLV

Psalms 119 in the BOATCB

Psalms 119 in the BOATCB2

Psalms 119 in the BOBCV

Psalms 119 in the BOCNT

Psalms 119 in the BOECS

Psalms 119 in the BOGWICC

Psalms 119 in the BOHCB

Psalms 119 in the BOHCV

Psalms 119 in the BOHLNT

Psalms 119 in the BOHNTLTAL

Psalms 119 in the BOICB

Psalms 119 in the BOILNTAP

Psalms 119 in the BOITCV

Psalms 119 in the BOKCV

Psalms 119 in the BOKCV2

Psalms 119 in the BOKHWOG

Psalms 119 in the BOKSSV

Psalms 119 in the BOLCB

Psalms 119 in the BOLCB2

Psalms 119 in the BOMCV

Psalms 119 in the BONAV

Psalms 119 in the BONCB

Psalms 119 in the BONLT

Psalms 119 in the BONUT2

Psalms 119 in the BOPLNT

Psalms 119 in the BOSCB

Psalms 119 in the BOSNC

Psalms 119 in the BOTLNT

Psalms 119 in the BOVCB

Psalms 119 in the BPBB

Psalms 119 in the BPH

Psalms 119 in the BSB

Psalms 119 in the CCB

Psalms 119 in the CUV

Psalms 119 in the CUVS

Psalms 119 in the DBT

Psalms 119 in the DGDNT

Psalms 119 in the DHNT

Psalms 119 in the DNT

Psalms 119 in the ELBE

Psalms 119 in the EMTV

Psalms 119 in the ESV

Psalms 119 in the FBV

Psalms 119 in the FEB

Psalms 119 in the GGMNT

Psalms 119 in the GNT

Psalms 119 in the HARY

Psalms 119 in the HNT

Psalms 119 in the IRVA

Psalms 119 in the IRVB

Psalms 119 in the IRVG

Psalms 119 in the IRVH

Psalms 119 in the IRVK

Psalms 119 in the IRVM

Psalms 119 in the IRVM2

Psalms 119 in the IRVO

Psalms 119 in the IRVP

Psalms 119 in the IRVT

Psalms 119 in the IRVT2

Psalms 119 in the IRVU

Psalms 119 in the ISVN

Psalms 119 in the JSNT

Psalms 119 in the KAPI

Psalms 119 in the KBT1ETNIK

Psalms 119 in the KBV

Psalms 119 in the KJV

Psalms 119 in the KNFD

Psalms 119 in the LBA

Psalms 119 in the LBLA

Psalms 119 in the LNT

Psalms 119 in the LSV

Psalms 119 in the MAAL

Psalms 119 in the MBV

Psalms 119 in the MBV2

Psalms 119 in the MHNT

Psalms 119 in the MKNFD

Psalms 119 in the MNG

Psalms 119 in the MNT

Psalms 119 in the MNT2

Psalms 119 in the MRS1T

Psalms 119 in the NAA

Psalms 119 in the NASB

Psalms 119 in the NBLA

Psalms 119 in the NBS

Psalms 119 in the NBVTP

Psalms 119 in the NET2

Psalms 119 in the NIV11

Psalms 119 in the NNT

Psalms 119 in the NNT2

Psalms 119 in the NNT3

Psalms 119 in the PDDPT

Psalms 119 in the PFNT

Psalms 119 in the RMNT

Psalms 119 in the SBIAS

Psalms 119 in the SBIBS

Psalms 119 in the SBIBS2

Psalms 119 in the SBICS

Psalms 119 in the SBIDS

Psalms 119 in the SBIGS

Psalms 119 in the SBIHS

Psalms 119 in the SBIIS

Psalms 119 in the SBIIS2

Psalms 119 in the SBIIS3

Psalms 119 in the SBIKS

Psalms 119 in the SBIKS2

Psalms 119 in the SBIMS

Psalms 119 in the SBIOS

Psalms 119 in the SBIPS

Psalms 119 in the SBISS

Psalms 119 in the SBITS

Psalms 119 in the SBITS2

Psalms 119 in the SBITS3

Psalms 119 in the SBITS4

Psalms 119 in the SBIUS

Psalms 119 in the SBIVS

Psalms 119 in the SBT

Psalms 119 in the SBT1E

Psalms 119 in the SCHL

Psalms 119 in the SNT

Psalms 119 in the SUSU

Psalms 119 in the SUSU2

Psalms 119 in the SYNO

Psalms 119 in the TBIAOTANT

Psalms 119 in the TBT1E

Psalms 119 in the TBT1E2

Psalms 119 in the TFTIP

Psalms 119 in the TFTU

Psalms 119 in the TGNTATF3T

Psalms 119 in the THAI

Psalms 119 in the TNFD

Psalms 119 in the TNT

Psalms 119 in the TNTIK

Psalms 119 in the TNTIL

Psalms 119 in the TNTIN

Psalms 119 in the TNTIP

Psalms 119 in the TNTIZ

Psalms 119 in the TOMA

Psalms 119 in the TTENT

Psalms 119 in the UBG

Psalms 119 in the UGV

Psalms 119 in the UGV2

Psalms 119 in the UGV3

Psalms 119 in the VBL

Psalms 119 in the VDCC

Psalms 119 in the YALU

Psalms 119 in the YAPE

Psalms 119 in the YBVTP

Psalms 119 in the ZBP