Psalms 47 (BOYCB)
undefined Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. 1 Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyànẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀. 2 Báwo ni OLÚWA Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tóọba ńlá lórí gbogbo ayé. 3 Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ waàwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa 4 Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa,ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa. 5 Ọlọ́run tó gòkè lọ tí òun tayọ̀, OLÚWA ti òun ti ariwo ìpè. 6 Ẹ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, ẹ kọrin ìyìn.Ẹ kọrin ìyìn sí ọba wa, ẹ kọrin ìyìn! 7 Nítorí Ọlọ́run ni ọba gbogbo ayé,ẹ kọrin ìyìn pẹ̀lú Saamu! 8 Ọlọ́run jẹ ọba lórí gbogbo kèfèrí;Ọlọ́run jókòó lórí ìtẹ́ ìwà mímọ́ rẹ̀. 9 Àwọn aládé ayé kó ara wọn jọgẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run Abrahamunítorí asà ayé ti Ọlọ́run ni,òun ni ó ga jùlọ.