Zechariah 8 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá. 2 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Owú ńlá ńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńlá ńlá ni mo fi jowú fún un.” 3 Báyìí ni OLÚWA wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.” 4 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. 5 Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.” 6 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 7 Báyìí ní OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. 8 Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.” 9 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. 12 “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀, àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13 Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún, ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.” 14 Nítorí báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16 Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni OLÚWA wí. 18 Ọ̀rọ̀ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé. 19 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.” 20 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21 Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere OLÚWA, àti láti wá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere OLÚWA.” 23 Báyìí ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”
In Other Versions
Zechariah 8 in the ANGEFD
Zechariah 8 in the ANTPNG2D
Zechariah 8 in the AS21
Zechariah 8 in the BAGH
Zechariah 8 in the BBPNG
Zechariah 8 in the BBT1E
Zechariah 8 in the BDS
Zechariah 8 in the BEV
Zechariah 8 in the BHAD
Zechariah 8 in the BIB
Zechariah 8 in the BLPT
Zechariah 8 in the BNT
Zechariah 8 in the BNTABOOT
Zechariah 8 in the BNTLV
Zechariah 8 in the BOATCB
Zechariah 8 in the BOATCB2
Zechariah 8 in the BOBCV
Zechariah 8 in the BOCNT
Zechariah 8 in the BOECS
Zechariah 8 in the BOGWICC
Zechariah 8 in the BOHCB
Zechariah 8 in the BOHCV
Zechariah 8 in the BOHLNT
Zechariah 8 in the BOHNTLTAL
Zechariah 8 in the BOICB
Zechariah 8 in the BOILNTAP
Zechariah 8 in the BOITCV
Zechariah 8 in the BOKCV
Zechariah 8 in the BOKCV2
Zechariah 8 in the BOKHWOG
Zechariah 8 in the BOKSSV
Zechariah 8 in the BOLCB
Zechariah 8 in the BOLCB2
Zechariah 8 in the BOMCV
Zechariah 8 in the BONAV
Zechariah 8 in the BONCB
Zechariah 8 in the BONLT
Zechariah 8 in the BONUT2
Zechariah 8 in the BOPLNT
Zechariah 8 in the BOSCB
Zechariah 8 in the BOSNC
Zechariah 8 in the BOTLNT
Zechariah 8 in the BOVCB
Zechariah 8 in the BPBB
Zechariah 8 in the BPH
Zechariah 8 in the BSB
Zechariah 8 in the CCB
Zechariah 8 in the CUV
Zechariah 8 in the CUVS
Zechariah 8 in the DBT
Zechariah 8 in the DGDNT
Zechariah 8 in the DHNT
Zechariah 8 in the DNT
Zechariah 8 in the ELBE
Zechariah 8 in the EMTV
Zechariah 8 in the ESV
Zechariah 8 in the FBV
Zechariah 8 in the FEB
Zechariah 8 in the GGMNT
Zechariah 8 in the GNT
Zechariah 8 in the HARY
Zechariah 8 in the HNT
Zechariah 8 in the IRVA
Zechariah 8 in the IRVB
Zechariah 8 in the IRVG
Zechariah 8 in the IRVH
Zechariah 8 in the IRVK
Zechariah 8 in the IRVM
Zechariah 8 in the IRVM2
Zechariah 8 in the IRVO
Zechariah 8 in the IRVP
Zechariah 8 in the IRVT
Zechariah 8 in the IRVT2
Zechariah 8 in the IRVU
Zechariah 8 in the ISVN
Zechariah 8 in the JSNT
Zechariah 8 in the KAPI
Zechariah 8 in the KBT1ETNIK
Zechariah 8 in the KBV
Zechariah 8 in the KJV
Zechariah 8 in the KNFD
Zechariah 8 in the LBA
Zechariah 8 in the LBLA
Zechariah 8 in the LNT
Zechariah 8 in the LSV
Zechariah 8 in the MAAL
Zechariah 8 in the MBV
Zechariah 8 in the MBV2
Zechariah 8 in the MHNT
Zechariah 8 in the MKNFD
Zechariah 8 in the MNG
Zechariah 8 in the MNT
Zechariah 8 in the MNT2
Zechariah 8 in the MRS1T
Zechariah 8 in the NAA
Zechariah 8 in the NASB
Zechariah 8 in the NBLA
Zechariah 8 in the NBS
Zechariah 8 in the NBVTP
Zechariah 8 in the NET2
Zechariah 8 in the NIV11
Zechariah 8 in the NNT
Zechariah 8 in the NNT2
Zechariah 8 in the NNT3
Zechariah 8 in the PDDPT
Zechariah 8 in the PFNT
Zechariah 8 in the RMNT
Zechariah 8 in the SBIAS
Zechariah 8 in the SBIBS
Zechariah 8 in the SBIBS2
Zechariah 8 in the SBICS
Zechariah 8 in the SBIDS
Zechariah 8 in the SBIGS
Zechariah 8 in the SBIHS
Zechariah 8 in the SBIIS
Zechariah 8 in the SBIIS2
Zechariah 8 in the SBIIS3
Zechariah 8 in the SBIKS
Zechariah 8 in the SBIKS2
Zechariah 8 in the SBIMS
Zechariah 8 in the SBIOS
Zechariah 8 in the SBIPS
Zechariah 8 in the SBISS
Zechariah 8 in the SBITS
Zechariah 8 in the SBITS2
Zechariah 8 in the SBITS3
Zechariah 8 in the SBITS4
Zechariah 8 in the SBIUS
Zechariah 8 in the SBIVS
Zechariah 8 in the SBT
Zechariah 8 in the SBT1E
Zechariah 8 in the SCHL
Zechariah 8 in the SNT
Zechariah 8 in the SUSU
Zechariah 8 in the SUSU2
Zechariah 8 in the SYNO
Zechariah 8 in the TBIAOTANT
Zechariah 8 in the TBT1E
Zechariah 8 in the TBT1E2
Zechariah 8 in the TFTIP
Zechariah 8 in the TFTU
Zechariah 8 in the TGNTATF3T
Zechariah 8 in the THAI
Zechariah 8 in the TNFD
Zechariah 8 in the TNT
Zechariah 8 in the TNTIK
Zechariah 8 in the TNTIL
Zechariah 8 in the TNTIN
Zechariah 8 in the TNTIP
Zechariah 8 in the TNTIZ
Zechariah 8 in the TOMA
Zechariah 8 in the TTENT
Zechariah 8 in the UBG
Zechariah 8 in the UGV
Zechariah 8 in the UGV2
Zechariah 8 in the UGV3
Zechariah 8 in the VBL
Zechariah 8 in the VDCC
Zechariah 8 in the YALU
Zechariah 8 in the YAPE
Zechariah 8 in the YBVTP
Zechariah 8 in the ZBP