1 Chronicles 19 (BOYCB)

1 Ní àkókò yí, Nahaṣi ọba àwọn ará Ammoni sì kú, ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 2 Dafidi rò wí pé èmi yóò fi inú rere hàn sí Hanuni ọmọ Nahaṣi, nítorí baba a rẹ̀ fi inú rere hàn sí mi. Bẹ́ẹ̀ ni, Dafidi rán àwọn aṣojú lọ láti lọ fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí Hanuni ní ti baba a rẹ̀.Nígbà tí àwọn ọkùnrin Dafidi wá sí ọ̀dọ̀ Hanuni ní ilẹ̀ àwọn ará Ammoni láti fi ìbá kẹ́dùn rẹ̀ hàn sí i. 3 Àwọn ọkùnrin ọlọ́lá ti Ammoni sọ fún Hanuni pé, “Ṣé ìwọ rò pé Dafidi ń bu ọlá fún baba rẹ nípa rírán àwọn olùtùnú sí ọ? Ṣé àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti rìn wò àti láti bì í ṣubú, àti láti ṣe ayọ́lẹ̀wò ilẹ̀ náà.” 4 Bẹ́ẹ̀ ni Hanuni fi ipá mú àwọn ọkùnrin Dafidi, fá irun wọn, wọ́n gé ẹ̀wù wọn kúrò ní àárín ìdí rẹ̀, ó sì rán wọn lọ. 5 Nígbà tí ẹnìkan wá, tí ó sì sọ fún Dafidi nípa àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó rán àwọn ìránṣẹ́ láti lọ bá wọn, nítorí wọ́n ti di rírẹ̀ sílẹ̀ gidigidi. Ọba wí pe, “Dúró ní Jeriko títí tí irùngbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ẹ padà wá”. 6 Nígbà tí àwọn ará Ammoni sì ri pé wọ́n ti di ẹ̀ṣẹ̀ ní ihò imú Dafidi, Hanuni àti àwọn ará Ammoni rán ẹgbẹ̀rún (1,000) tálẹ́ǹtì fàdákà láti gba iṣẹ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn agun-kẹ̀kẹ́ láti Aramu-Naharaimu, Siria Maaka àti Soba. 7 Wọ́n gba iṣẹ́ ẹgbẹ̀rin méjìlélọ́gbọ̀n (32,000) kẹ̀kẹ́ àti agun-kẹ̀kẹ́ àti ọba Maaka pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ tí ó wá pàgọ́ ní ẹ̀bá Medeba, nígbà tí àwọn ará Ammoni kójọpọ̀ láti ìlú wọn, tí wọ́n sì jáde lọ fún ogun. 8 Ní gbígbọ́ eléyìí, Dafidi rán Joabu jáde pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun ọkùnrin tí ó le jà. 9 Àwọn ọmọ Ammoni sì jáde wá, wọ́n sì tẹ́ ogun ní ẹnu odi ìlú ńlá wọn, nígbà tí àwọn ọba tí ó wá, fún rara wọn wà ni orílẹ̀-èdè tí ó ṣí sílẹ̀. 10 Joabu ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun, bẹ́ẹ̀ ni o mu àwọn ọmọ-ogun tí ó dára ní Israẹli, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Siria. 11 Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Abiṣai arákùnrin rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ammoni. 12 Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́. 13 Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. OLÚWA yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀. 14 Nígbà náà Joabu àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Siria. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀. 15 Nígbà ti àwọn ará Ammoni ri pé àwọn ará Siria ń sálọ, àwọn náà sálọ kúrò níwájú arákùnrin rẹ̀ Abiṣai. Wọ́n sì wọ inú ìlú ńlá lọ. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu padà lọ sí Jerusalẹmu. 16 Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ará Siria rí wí pé àwọn Israẹli ti lé wọn, wọ́n rán ìránṣẹ́. A sì mú àwọn ará Siria rékọjá odò Eufurate wá, pẹ̀lú Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun Hadadeseri, tí ó ń darí wọn. 17 Nígbà tí a sọ fún Dafidi nípa èyí, ó pe gbogbo Israẹli jọ wọ́n sì rékọjá Jordani; Ó lọ síwájú wọn, ó sì fa ìlà ogun dojúkọ wọ́n. Dafidi fa ìlà rẹ̀ láti bá àwọn ará Siria jagun wọ́n sì dojú ìjà kọ ọ́. 18 Ṣùgbọ́n àwọn ará Siria sálọ kúrò níwájú Israẹli, Dafidi sì pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ wọn àti ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó pa Ṣofaki alákòóso ọmọ-ogun wọn pẹ̀lú. 19 Nígbà tí àwọn ẹrú Hadadeseri rí i wí pé Israẹli ti borí wọn, wọ́n ṣe àlàáfíà pẹ̀lú Dafidi, wọ́n sì ń sìn ní abẹ́ ẹ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Siria kò ní ìfẹ́ sí ríran àwọn ará Ammoni lọ́wọ́ mọ́.

In Other Versions

1 Chronicles 19 in the ANGEFD

1 Chronicles 19 in the ANTPNG2D

1 Chronicles 19 in the AS21

1 Chronicles 19 in the BAGH

1 Chronicles 19 in the BBPNG

1 Chronicles 19 in the BBT1E

1 Chronicles 19 in the BDS

1 Chronicles 19 in the BEV

1 Chronicles 19 in the BHAD

1 Chronicles 19 in the BIB

1 Chronicles 19 in the BLPT

1 Chronicles 19 in the BNT

1 Chronicles 19 in the BNTABOOT

1 Chronicles 19 in the BNTLV

1 Chronicles 19 in the BOATCB

1 Chronicles 19 in the BOATCB2

1 Chronicles 19 in the BOBCV

1 Chronicles 19 in the BOCNT

1 Chronicles 19 in the BOECS

1 Chronicles 19 in the BOGWICC

1 Chronicles 19 in the BOHCB

1 Chronicles 19 in the BOHCV

1 Chronicles 19 in the BOHLNT

1 Chronicles 19 in the BOHNTLTAL

1 Chronicles 19 in the BOICB

1 Chronicles 19 in the BOILNTAP

1 Chronicles 19 in the BOITCV

1 Chronicles 19 in the BOKCV

1 Chronicles 19 in the BOKCV2

1 Chronicles 19 in the BOKHWOG

1 Chronicles 19 in the BOKSSV

1 Chronicles 19 in the BOLCB

1 Chronicles 19 in the BOLCB2

1 Chronicles 19 in the BOMCV

1 Chronicles 19 in the BONAV

1 Chronicles 19 in the BONCB

1 Chronicles 19 in the BONLT

1 Chronicles 19 in the BONUT2

1 Chronicles 19 in the BOPLNT

1 Chronicles 19 in the BOSCB

1 Chronicles 19 in the BOSNC

1 Chronicles 19 in the BOTLNT

1 Chronicles 19 in the BOVCB

1 Chronicles 19 in the BPBB

1 Chronicles 19 in the BPH

1 Chronicles 19 in the BSB

1 Chronicles 19 in the CCB

1 Chronicles 19 in the CUV

1 Chronicles 19 in the CUVS

1 Chronicles 19 in the DBT

1 Chronicles 19 in the DGDNT

1 Chronicles 19 in the DHNT

1 Chronicles 19 in the DNT

1 Chronicles 19 in the ELBE

1 Chronicles 19 in the EMTV

1 Chronicles 19 in the ESV

1 Chronicles 19 in the FBV

1 Chronicles 19 in the FEB

1 Chronicles 19 in the GGMNT

1 Chronicles 19 in the GNT

1 Chronicles 19 in the HARY

1 Chronicles 19 in the HNT

1 Chronicles 19 in the IRVA

1 Chronicles 19 in the IRVB

1 Chronicles 19 in the IRVG

1 Chronicles 19 in the IRVH

1 Chronicles 19 in the IRVK

1 Chronicles 19 in the IRVM

1 Chronicles 19 in the IRVM2

1 Chronicles 19 in the IRVO

1 Chronicles 19 in the IRVP

1 Chronicles 19 in the IRVT

1 Chronicles 19 in the IRVT2

1 Chronicles 19 in the IRVU

1 Chronicles 19 in the ISVN

1 Chronicles 19 in the JSNT

1 Chronicles 19 in the KAPI

1 Chronicles 19 in the KBT1ETNIK

1 Chronicles 19 in the KBV

1 Chronicles 19 in the KJV

1 Chronicles 19 in the KNFD

1 Chronicles 19 in the LBA

1 Chronicles 19 in the LBLA

1 Chronicles 19 in the LNT

1 Chronicles 19 in the LSV

1 Chronicles 19 in the MAAL

1 Chronicles 19 in the MBV

1 Chronicles 19 in the MBV2

1 Chronicles 19 in the MHNT

1 Chronicles 19 in the MKNFD

1 Chronicles 19 in the MNG

1 Chronicles 19 in the MNT

1 Chronicles 19 in the MNT2

1 Chronicles 19 in the MRS1T

1 Chronicles 19 in the NAA

1 Chronicles 19 in the NASB

1 Chronicles 19 in the NBLA

1 Chronicles 19 in the NBS

1 Chronicles 19 in the NBVTP

1 Chronicles 19 in the NET2

1 Chronicles 19 in the NIV11

1 Chronicles 19 in the NNT

1 Chronicles 19 in the NNT2

1 Chronicles 19 in the NNT3

1 Chronicles 19 in the PDDPT

1 Chronicles 19 in the PFNT

1 Chronicles 19 in the RMNT

1 Chronicles 19 in the SBIAS

1 Chronicles 19 in the SBIBS

1 Chronicles 19 in the SBIBS2

1 Chronicles 19 in the SBICS

1 Chronicles 19 in the SBIDS

1 Chronicles 19 in the SBIGS

1 Chronicles 19 in the SBIHS

1 Chronicles 19 in the SBIIS

1 Chronicles 19 in the SBIIS2

1 Chronicles 19 in the SBIIS3

1 Chronicles 19 in the SBIKS

1 Chronicles 19 in the SBIKS2

1 Chronicles 19 in the SBIMS

1 Chronicles 19 in the SBIOS

1 Chronicles 19 in the SBIPS

1 Chronicles 19 in the SBISS

1 Chronicles 19 in the SBITS

1 Chronicles 19 in the SBITS2

1 Chronicles 19 in the SBITS3

1 Chronicles 19 in the SBITS4

1 Chronicles 19 in the SBIUS

1 Chronicles 19 in the SBIVS

1 Chronicles 19 in the SBT

1 Chronicles 19 in the SBT1E

1 Chronicles 19 in the SCHL

1 Chronicles 19 in the SNT

1 Chronicles 19 in the SUSU

1 Chronicles 19 in the SUSU2

1 Chronicles 19 in the SYNO

1 Chronicles 19 in the TBIAOTANT

1 Chronicles 19 in the TBT1E

1 Chronicles 19 in the TBT1E2

1 Chronicles 19 in the TFTIP

1 Chronicles 19 in the TFTU

1 Chronicles 19 in the TGNTATF3T

1 Chronicles 19 in the THAI

1 Chronicles 19 in the TNFD

1 Chronicles 19 in the TNT

1 Chronicles 19 in the TNTIK

1 Chronicles 19 in the TNTIL

1 Chronicles 19 in the TNTIN

1 Chronicles 19 in the TNTIP

1 Chronicles 19 in the TNTIZ

1 Chronicles 19 in the TOMA

1 Chronicles 19 in the TTENT

1 Chronicles 19 in the UBG

1 Chronicles 19 in the UGV

1 Chronicles 19 in the UGV2

1 Chronicles 19 in the UGV3

1 Chronicles 19 in the VBL

1 Chronicles 19 in the VDCC

1 Chronicles 19 in the YALU

1 Chronicles 19 in the YAPE

1 Chronicles 19 in the YBVTP

1 Chronicles 19 in the ZBP